Trinity Guy gba ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Instagram/Cute Abiola
Gbajúmọ̀ adẹ́rìnínpòṣónú, Abdullahi Maruf Adisa tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Trinity Guy ti gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Ẹ ó rántí pé láti ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹfà ọdún 2023 tí Trinity Guy ti fojú bá ilé ẹjọ́ lórí fídíò kan tó ṣe tí ọmọdé wà níbẹ̀.
Nínú fídíò náà ni Trinity Guy ti ń bèèrè àwọn ọ̀rọ̀ àlùfàǹṣá lọ́wọ́ ọmọ náà tí èyí sì fà awuyewuye lórí ayélujára.
Ní ọjọ́ náà ni ilé ẹjọ́ Májísíréètì tó wà ní Iyaganku, Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ní kí wọ́n fi Trinity Guy sí ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di oṣù Kẹjọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Yàtọ̀ sí Trinity Guy, ilé ẹjọ́ tún fi àwọn òbí ọmọ náà sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n pé àwọn náà lọ́wọ́ nínú fídíò tí Trinity Guy ṣe.
Àmọ́ báyìí Trinity Guy tí gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àhámọ́ tó wà.
Gbajúmọ̀ adẹ́rìnínpòṣónú mìíràn, AbdulGafar Abiola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Cute Abiola ló fi ìkéde náà síta.
Cute Abiola lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì ló fi ọ̀rọ̀ náà sórí Instagram rẹ̀ pẹ̀lú àwòrán Trinity Guy pé wọ́n tí gba béèlì rẹ̀.















