Ọkọ, ìyàwó, ọmọ méjì àti èèyàn méjì míì kú lẹ́yìn tí wọ́n kó sílé tuntun

THEOPHILUS OKO/FACEBOOK

Oríṣun àwòrán, THEOPHILUS OKO/FACEBOOK

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ni oun ti bẹrẹ iwadii iku to pa odidi mọlẹbi kan niluu Onisha.

Ifeanyi Theophilus Okoh, iyawo rẹ, awọn ọmọ meji, mọlẹbi iyawo rẹ ati ọmọkunrin kekere kan lo ku lẹyin ti wọn ko wọ inu ile tuntunn kan to wa ni Nkwelle GRA, niluu Onisha.

Ọkan larsa awọn alabagbe wọn ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede ṣalaye fun BBC pe apapọ awọn to ku ninu ile naa jẹ mẹfa.

O ni “a gbọ pe iyawo rẹ bimọ lọjọru, o lọ sile iwosan lọjọ Aiku, lẹyin ti iyawo rẹ bimọ tan ni wọn ṣe ayẹyẹ iṣile.”

“Lẹyin naa la gbọ pe gbogbo wọn ti jade laye amọ ọmọ kekere jojolo ti wọn ṣẹṣẹ bi ṣi wa laaye.”

Iroyin ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2023 yii ni wọn ṣe isọmọlorukọ, ti wọn si ko sinu ile wọn tuntun amọ oku wọn ni wọn gbe jade nibẹ.

Gẹgẹ ohun ti a gbọ, alẹ ọjọ Isinmi lawọn alejo wọn kuro ninu ile naa, ti awọn naa si sun.

Ṣugbọn nigba ti awọn eeyan yoo fi bẹ wọn wo lọjọ keji, oku wọn ni wọn ba.

Bo tilẹ jẹ pe wọn gbiyannu lati ko awọn eeyan ọhun lọ sile iwosan fun itọju, o ti bọ sori.

Ẹwẹ, ọlọpaa ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ laabi naa.

Agbẹnusọ ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Anambra, Tochukwu Ikenga ṣo fun BBC pe awọn ti ṣawari ile ti isẹlẹ naa ti waye.

O ni “a tun ti n wadii lori ile iwosan ti wọn ko wọn lọ.”