Charles Agbako rí ẹ̀bùn ₦500,000 gbà, yóò tún gba ₦100,000 lóṣù títí dọjọ́ ikú

Agbako

Oríṣun àwòrán, primateayodele

Agbako yoo maa gba ₦‎100,000 owo oṣu titi ti yoo fi jade laye

Pasitọ agba ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Ayodele ti fun agba oṣere tiata Yoruba, Charles Olumo ‘Agbako’ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrun ọdun rẹ.

Primate Ayodele tun ṣeleri lati maa san owo oṣu fun oṣere naa titi ti yoo fi papoda.

Eyii lo waye nibi ayẹyẹ ọjọ ibi agba oṣere ọhun ti ẹgbẹ awọn oṣere tiata Yoruba, TAMPAN, ṣe fun un niluu Abeokuta.

Nibi ayẹyẹ naa ni wọn ti fun Primate Ayodele nipo baba isalẹ ati baba ninu ẹmi fun ẹgbẹ awọn oṣere naa.

Nigba to n sọrọ lori eredi ti wọn fi fun Ayodele ni ipo naa, Aarẹ TAMPAN nipinlẹ Ogun, Owolabi Ajasa sọ pe ko ṣẹyin bi Ọlọrun ṣe n lo pasitọ naa ni Naijiria ati kaakiri agbaye.

Lẹyin naa ni Ajasa dupe lọwọ pasitọ ọhun fun bo ṣe gba lati jẹ baba isalẹ fun awọn.

Primate Ayodele di Baba Isalẹ TAMPAN, ó fun ẹgbẹ naa ni ₦500,000 mii

Nigba ti Aarẹ gbogbogbo TAMPAN, Mr Latin n sọrọ, o ni o ti le ni ọgbọn ọdun ti oun ti n tẹle Ayodele, ati pe ko si igba ti oun kii tẹti si awọn asọtẹlẹ rẹ ni gbogbo opin ọdun.

Lasiko ti Ayodele funra rẹ n sọrọ, o dupe lọwọ TAMPAN fun ayẹsi ti wọn ṣe fun oun lati fi oun jẹ baba isalẹ wọn.

O ni “Mo mọ riri ẹgbẹ yii fun bi wọn ṣe yẹ mi si... lagbara Ọlọrun, mo maa fun agba oṣere Charles Olumo ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira.”

“Bẹẹ ni maa si maa san owo oṣu ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgunrun naira fun un titi ti yoo fi jade laye.”

“Mo tun maa fun ẹgbẹ yii ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira miran fun bi wọn ṣe gbe ayẹyẹ yii kalẹ.”

Lara awọn to wa nibi ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni Aarẹ TAMPAN, Bolaji Amusan ‘Mr Latin’, Odunlade Adekola, Yemi Solade, Charles Olumo, Owolabi Ajasa atawọn oṣere mii.

Àkọlé fídíò, “Tí FUNAB kò bá fàyè gbà wá láti lo Niqob, a ó lọ sí UI tàbí LASU”

A ti pinu láti ṣe àkójọ orúkọ gbogbo àwọn àgbà láàrín wa, a ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ... - Mr Latin sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Agbako

Awọn Oṣere

Ka wi bẹẹ ka si ba a bẹẹ, iyẹn ni iyi ọmọluabi! Eyi gaan ni apapọ ẹgbẹ awọn oṣere fiimu Yoruba, TAMPAN sọ ti wọn si ṣe bẹẹ nipa agba oṣere ti iroyin gbe e lẹnu ọjọ mẹta yii pe o ti pe ẹni ọgọrun ọdun laye, Charles Olumo ti ọpọ eeyan mọ si “Agbako”.

Lonii Ogunjọ Oṣu Keje gan ni ọjọ ti wọn da ọhun pe. Pẹlu tilu tifọn ni awọn oṣere fiimu Yoruba fi gbaruku ti baba ẹni ọgọrun ọdun naa ti wọn jọ jo wọ inu gbọngan ti wọn ti ṣe ayẹyẹ naa fun Agbako.

Torii bi ọjọ ori rẹ ṣe to, agba oṣere naa ti yoo jẹ ọkan lara awọn to dagba ju to ṣi wa looke eepẹ ko lee fi gbogbo agbara rin daadaa amọ lẹẹkọọkan, ṣe ni ti igba ewe n bọ si baba lara ti yoo si tun ki ijo mọlẹ.

Ayẹyẹ ọjọ ibi Agbako

Lara awọn gbajumọ oṣere to wa nibẹ ni pupọ lara wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, ẹka ti ipinlẹ Ogun bẹẹ si ni awọn miran wa lati ipinlẹ mii.

Yatọ fun aarẹ ẹgbẹ naa, Bolaji Amusan ti ọpọ mọ si Mr Latin, agba oṣere akọtan, Tunde Kelani, gbajugbaja oṣere to maa n ko ipa Ọga Ọlọpaa ninu fiimu, Owolabi Ajasa, Odunlade Adekola, Adebayo Oladunni(Immalian Boy), Tunbosun Adeniyi, Baba Ojogẹ ati ọpọlọpọ oṣere mii ti a ko le darukọ wọn tan.

Nigba ti Aarẹ wọn, Mr Latin n sọrọ, o dupẹ lọwọ awọn to maa n na ọwọ iranwọ si awọn oṣere to si ni awọn mọ riri wọn. Ninu ọrọ naa lo ti sọ pe niwaju Ọlọrun ati gbogbo eeyan to wa nibẹ, awọn ko fi awọn to jẹ agba laarin awọn silẹ.

Ayẹyẹ ọjọ ibi Agbako

Oríṣun àwòrán, Emiralty Africa

“A o ni ọkan lati fi awọn to jẹ agba laarin wa silẹ lai tọju wọn”

Bolaji Amusan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere fiimu Yoruba (TAMPAN), Ọga Latin ki ẹnu bọ ọrọ niwaju ọkan lara awọn ẹlẹyinju aanu to jade lati maa ran awọn agba oṣere lọwọ lati sọrọ tako erongba awọn eeyan pe awọn oṣere maa n kọ awọn agba laarin wọn silẹ to ba ti di ọjọ ogbo.

“Niwaju Ọlọrun ati gbogbo eniyan to wa nibi, a ko fi awọn to jẹ agba laarin wa silẹ o, awọn to jẹ ọmọde laarin wa, a ko fi wọn silẹ, a pọ, ṣugbọn a o le ṣe e tan lẹẹkan naa”.

Latin ni awọn nilo awọn eeyan to si jẹ awọn eeyan daadaa lati pawọpọ pẹlu awọn, awọn yoo si tẹsiwaju lati maa dupẹ lọwọ wọn.

“Ọfiisi wa lapapọ ti gbe eto jade lati pese orukọ gbogbo awọn agba aarin wa lagbo oṣere Tiata ti a o si tẹsiwaju lati maa bẹ wọn wo, lati maa ṣe iwọnba ti a ba le ṣe a o si bẹrẹ pẹlu ilera wọn.”

Mr Latin ni bi nnkan ba si ṣe n lọ ni awọn yoo maa ṣafihan rẹ.

“A ti n ṣe e tẹlẹ amọ o ko ki n fihan faraye”

Ayẹyẹ ọjọ ibi Agbako

Ọgbẹni Bolaji Amusan jẹ ko di mimọ pe awọn ti maa n nawọ iranwọ si awọn agba laarin awọn tẹlẹ amọ o ṣe ni laanu pe awọn kii gbe e sori ayelujara.

“Amọ a o bẹrẹ bayii lati maa jẹ ki gbogbo eeyan mọ nnkan ti a n ṣe e ati ọna ti a n gbe e gba.”

Lati lee jẹ ki awọn eeyan mọ wipe awọn oṣere naa mọ awọn to n nawọ iranwọ si wọn ati pe awọn mọ riri wọn, nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ti wọn ṣe fun Agbako ni wọn ti fi ami ẹyẹ da Olori ijọ kan lọla ti wọn ni awọn mọ riri iṣẹ ati iranlọwọ to n ṣe fun awọn.

Ayẹyẹ ọjọ ibi Agbako