Lóòtọ́ ni mo yí èsì ìdánwò JAMB mi, ẹ dárí jì mí, ọmọdé ló ṣe mí - Mmesoma

Oríṣun àwòrán, @jagabanolu
Mmesoma Ejikeme, akẹkọọ ti wọn fẹsun kan pe o yi esi idanwo JAMB rẹ ti kọ lẹta si ajọ naa pe ko forijin oun.
Ọdọmọde ẹni ọdun mọkandinlogun naa kọkọ sọ pe 362 ni iye maaki ti oun gba ninu idanwo naa bo tilẹ jẹ pe 249 lo gba, gẹgẹ bii ohun ti JAMB sọ.
Ninu fidio kan lo ti kọkọ ṣe afihan esi idanwo ọhun, eyii to sọ pe pe o wa lati ọdọ JAMB funra rẹ.
Amọ JAMB mu ẹri jade pe 249 ni esi ti wọn fi ṣọwọ si akẹkọọ ọhun.
Ẹwẹ, lasiko to yọju siwaju igbimọ to n ṣewadii awuyewuye naa nile igbimọ aṣojuṣofin, Mmesoma ni oun ti gba pe oun ṣe aṣiṣẹ, oun si tọrọ aforiji.
“Ẹ dariji mi, ọmọde lo ṣe mi”
O ni “mo wa sibi pẹlu irẹlẹ lati tọrọ aforiji yin fun aṣiṣẹ ti mo ṣe.”
“Lootọ ni pe ori ẹrọ miran ni mo ti mu esi idanwo JAMB mi jade ti mo si sọrọ kobakungbe si JAMB amọ mo tọ aforiji.”
Akẹkọọ ọhun, ti JAMB ti gbẹsẹle esi idanwo rẹ, ti wọn si tun sọ pe ko ni lanfani lati ṣe idanwo naa mọ fun ọdun mẹta gbako ti jẹwọ pe ẹjẹ ọmọde lo mu oun ṣe ‘aṣiṣe’ naa.
O ni “mi o le ṣsalaye bi ọrọ yi ṣe ri lara mi, igba akọkọ ree ti mo si maa yi iwe bayii.”
“Mo fẹ ki ẹ fi oju aanu wo mi... mo si ṣeleri lati sa gbogbo ipa lati ri pe mi o ni ṣe bẹẹ mọ lọna ti tun orukọ mi ṣe.”
Ẹwẹ, ọga agba ajọ JAMB, Ọjọgbọn Is-haq Oloyede ti sọ pe gbọgan to ti ṣe idanwo naa ni akẹkọọ ọhun ti yi esi idanwo rẹ pada, awọn si ti fofin de gbọgan naa ko ma le kopa ninu idanwo JAMB mọ.
Yatọ si gbọgan naa, o ni JAMB tun ti bẹrẹ iwadii lori gbọgan mẹjọ mii nipinlẹ Anambra lori ẹsun kan naa, ati pe ẹbi ọrọ ọhun ko ti ọwọ JAMB wa, bi ko ṣe awọn araalu to n lo alumọkọrọyi fun esi idanwo.















