N kò tọrọ ìrànlọ́wọ́ Tope Alabi àti pé ìjà ìfẹ́ ló wà láàrín wa - Yemi My Lover

Oríṣun àwòrán, Others
Agba oṣere Yemi Ayebo ti ọpọ eeyan mọ si Yemi My Lover ti ni irọ ni iroyin kan to gba ori ayelujara pe oun binu si Olorin Ẹmi, Tope Alabi nitori o kọ lati wa si bi ayẹyẹ ti oun pe e si.
Yemi My Lover, ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara ṣalaye pe ija ifẹ lo wa laarin oun ati Tope Alabi ati pe awọn oniroyin lo lọ fẹ ọrọ naa loju.
"Mo gbọ iroyin to n lọ ní ìgboro nipa emi ati Tope Alabi, oni kọ ni awọn oniroyin ma n fi ọrọ wa wa lẹnu wo lori iṣẹ wa ti a dẹ maa n ba wọn sọrọ ṣugbọn nigba miiran awọn oniroyin ma n fi tiwọn kun un ko le pọ sii.
"Kayefi lo jẹ fun mi nigba ti mo bẹrẹ si ni maa ka iroyin pe mo ni Tope Alabi ko gbe ipe mi, ko fun mi lowo, ko tọju mi, gbogbo ọrọ yii lo ya mi lẹnu.
"Ẹ jọọ ṣe emi ni mo da ileeṣẹ silẹ fun Tope Alabi ti maa wa duro le e lori, bawo ni temi ṣe jẹ ti maa wa ni ko gbe ipe mi. Ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Ọlọrun ti mo sin ko fi iya jẹ mi
Yemi My Lover tẹsiwaju pe Ọlọrun ti oun sin ko jẹ ki iya ya sọdọ oun, ti inu oun si dun si gbogbo ohun ti oun ni ati ti Ọlọrun ṣe fun oun.
"Emi ko gb'ara le Tope Alabi, ti ẹ ba rii ti a n sọrọ nigba mii, mo fẹ ki ẹ mọ pe ija ifẹ ni a maa n ja, ìyẹn ko ni pe mo wa gun le e lọrun pe ti ko ba ṣe fun mi n ko ni jẹun.
"Emi pẹlu Tope Alabi, a ko le ja, mọlẹbi ni wa, ti a si jẹ mọlẹbi titi Jesu yoo fi de."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"Eeyan buruku ni ko ni fẹ ki ọmọ abẹ oun maa ni lari"
Yemi My Lover fi idi rẹ mulẹ pe ko si nnkan to jọ mọ pe oun binu si Tope Alabi nitori pe o ni lari.
"Ko ṣeeṣe, were eeyan ni ko ni fẹ ki ọmọ abẹ oun ni lari.
"Pupọ ija laarin wa lo jẹ ija ifẹ, ko ju bẹẹ lọ. N ko tọrọ jẹ lọwọ Tope, Ọlọrun ko ni jẹ ki n wo oju Tope kí n to jẹun. Ko si eeyan ti Ọlọrun ko ṣe fun afi ẹni to ba ni toun ko to."
"Inu mi dun fun ore ti Ọlọrun ṣe fun Tope, ẹ ma da sija ilẹ laarin wa."















