Tobi Amusan lọ rọ́ọ́kún nílé ná torí ẹ̀sùn àìṣe àyẹ̀wò lílo òògùn olóró

Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ́ tó ń ṣèwádìí òòtọ́ nípa àwọn eléré ìdárayá ní kí Tobi Amusan lọ rọ́ọ́kún nílé ná torí ẹ̀sùn pé kò ṣe àyẹ̀wò lílo òògùn olóró

Ẹka to n se ọfintoto iwa otitọ laarin awọn elere idaraya, The Athletics Integrity Uniti (AIU) ti kede pe ki gbajumọ asare ori ọdan, Tobi Amusan lọ rọọkun nile na.

Ẹsun ti ẹka AIU fi kan Amusan ni pe o kuna lati se ayẹwo lilo oogun oloro nigba mẹta ọtọọtọ laarin ọdun kan.

Loju opo ayelujara Twitter ajọ AIU naa ni wọn ti kede igbesẹ ọhun, to si ni ẹsun yii le mu ki wọn ni ki Amusan lọ sinmi nile fun ọdun meji gbako lai kopa ninu ere sisa kankan, to ba fi jẹbi ẹsun naa.

Ẹka AIU wa salaye pe igbimọ olugbẹjọ lati huwa ọmọhuwabi labẹ ẹka naa yoo gbọ ẹjọ Amusan saaju idije ere idaraya lagbaye ti yoo bẹrẹ lọjọbọ.

Àkọlé fídíò, Men who trained on house chores: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú kí ọkùnrin máa ṣiṣẹ́ ilé

Tobi Amusan wọ gàù torí kò ṣe àyẹ̀wò lílo òògùn olóró ní ẹ̀ẹ̀mẹta

Tobi Amusan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n gbogun ti egbogi oloro lilo fun awọn elere idaraya, AIU, ti fẹsun kan ọmọ Naijiria to gba ami ẹyẹ obinrin to le sa ere ju lagbaye, Tobi Amusan, lẹyin to kọ lati ṣe ayẹwo oogun oloro.

Amusan lo fi ọrọ naa lede loju opo Facebook rẹ.

O ni “Lonii ni ajọ Athletics Integrity Unit, AIU, fẹsun kan mi pe mo ru ofin sise ayẹwo lilo oogun oloro lẹyin ti mi o ṣe ayẹwo naa lẹẹmẹta laarin ọdun kan sẹyin.”

O ṣeeṣe ki Amusan ma lee kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ‘world championships’ ti yoo waye loṣu to n bọ latari ẹsun yii.

“Mi o lo oogun oloro, ọwọ mi mọ”

Amọ ṣa, Amusan ti fesi si ẹsun naa loju opo Instagram rẹ, nibi to ti sọ pe oun ko lo oogun oloro kankan.

O ni “gbogbo igba ni AIU maa n ṣe ayẹwo fun mi.... ọwọ mi mọ.”

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

“Mo ti ṣetan lati pe ẹsun yii nija, awọn mẹta to jẹ adajọ ere idaraya ni yoo si joko lori ọrọ naa ki a to bẹrẹ idije ife ẹyẹ agbaye loṣu to n bọ.”

Ofin AUI sọ pe ẹnikẹni to ba kọ lati jọwọ ara rẹ fun ayẹwo oogun oloro nigba mẹta ọtọtọ laarin ọdun ko ni lanfani lati kopa ninu ere idaraya naa fun ọdun kan tabi ọdun meji.

Ọjọ Aiku to kọja yii ni Amusan ṣẹṣẹ gba ami ẹyẹ ‘Diamond League’ ni Silesia, eyii to n waye lẹyin aṣeyọri rẹ ni Stockholm.

Ẹwẹ, aarin ọjọ kọkandinlogun si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ni idije ‘World Athletics Championships’ yoo waye ni olu ilu Hungaria, nibi ti ireti wa pe Amusan yoo ti kopa.