Àlàyé rèé nípa akẹ́kọ̀ọ́jáde fásitì n‘Ibadan, tí wọn lú pa torí pé ó jí búrẹ́dì

Aworan

Oríṣun àwòrán, FREEBORN EBIMOTIMI

Ọkunrin kan, ẹni ọdun mejilelọgbọn ti awọn eeyan kan lu pa ni Yenagoa nipinlẹ Bayelsa nitori pe o ji burẹdi, ni iwadi fihan pe o ni ọdẹ ori.

Awọn mọlẹbi ati alabagbe oloogbe Ebimotimi Freedom Opuofoni, lo sọrọ yii lẹyin to jade laye.

Ileeṣẹ BBC ṣe iwadi lori ohun to sẹlẹ si ọkùnrin naa, ti a si ri pe kii ṣe burẹdi gan ni oloogbe naa ji gbe, gẹgẹ bí iroyin ṣe gbe .

Sugbọn 'Madiga' to jẹ oúnjẹ miiran ti wọn n fi burẹdi ṣe lo gbe.

'Madiga' jẹ oúnjẹ kan to dabi burẹdi sugbọn o le ju burẹdi lọ, to si jẹ oúnjẹ fun awọn ọmọde ati agbalagba.

"Ironu nipa ọdẹ ori ti Freedom ni lo sekupa baba rẹ laipẹ yii"

Ebimotimi Freeborn lo wa lati Korokosei, agbegbe kan ni apa ijoba ibilẹ guusu Ijaw nipinlẹ Bayelsa.

Ko ti ni iyawo, tori ko nisẹ lọwọ lẹyin to parí ni fasiti Lead City niluu Ibadan nipinlẹ Oyo.

Ọkan lara ọrẹ rẹ, Kenneth Amewuga ni Freeborn parí ẹkọ rẹ ni fasiti , to si wa nipele aseyọri Upper Division' ni fasiti Lead City.

O salaye siwaju pe ọpọ eeyan lo mọ pe oloogbe naa ni ọdẹ ori, to si ma n ja foonu gba lọwọ awọn nigba miiran,.

O ni o le sọ foonu naa sinu igbo tabi ko ba a jẹ sugbọn ko ni ta a rara.

O ni ọrọ yii lo ṣekúpa baba rẹ lẹyin ọpọlọpọ ironu ni ọdun diẹ sẹyin.

Amewuga ni Freeborn lọ fun agunbanirọ sugbọn ai rí isẹ ko ipa lori bi o ṣe ni ọdẹ ori.

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

"Awọn ẹbi Freedom dana sun ileesẹ burẹdi ati awọn ti wọn furasi pe o lu Freedom pa"

Amewuga ti isẹlẹ naa soju rẹ sọ pe ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti oun rí tí wọn pe le Freeborn lori nítorí o mu 'Madiba'.

"Freeborn kuro ni adugbo rẹ nibi tí awọn eeyan mọ nípa ailera rẹ, lọ si ibi ti awọn eeyan ko ti mọ rara.

"Lẹyin to gbe Madiga ọhun, awọn kan ri bí o ṣe n lọ, ti wọn si bẹrẹ si ni ma a lu."

Elomiran to n gbe ni ẹgbẹ ileeṣẹ burẹdi tí iṣẹlẹ naa ti waye ni agbegbe Tombia ni Yenagoa, Barisuka Witor ni oun gbọ to n bẹ awọn eeyan pe ki wọn maa lu oun mọ.

O ni iṣẹlẹ naa waye ni agogo marun-un ku isẹju diẹ, to si jẹ pe lasiko ti oun yoo fi bọ sita, Freeborn tí jade laye.

Witor salaye pe awọn mọlẹbi Freeborn ati agbegbe rẹ pe ara wọn jọ, tí wọn si dana sun ileeṣẹ burẹdi ati ile awọn ti wọn lu Freeborn ku.

"Aburo mi jẹ akẹkọọjade fasiti, airi isẹ se fun ọdun mẹta lo dakun ohun to sẹlẹ si"

Iroyin nípa iku Freeborn lo jẹ ibanujẹ fun awọn mọlẹbi rẹ.

Ọkan lara ẹgbọn rẹ obìnrin, Beauty Edisemi Opuofoni pẹlu omije ba BBC sọrọ, o si ni iṣẹlẹ naa dun oun pupọ nitori oun ko ro iku sì Freeborn rara.

O ni bi aburo oun ṣe jẹ akẹkọọ jade, airi isẹ se fun bí ọdun mẹta lo dakun ohun to sẹlẹ si.

"N ko mọ nnkan ti mo le sọ. Aburo mi ti ku. N ko ti rí oku rẹ nitori o si wa ni ile igbokusi. Ko pẹ ti Baba wa ku, awa nikan lo ku, ko si ẹnikẹni."

Wayi o, Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Bayelsa ti mu afurasi mẹta to lọwọ ninu isekupani Freeborn.

Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Bayelsa, SP Asinim Butswat, ninu atẹjade to fi síta ni, awọn afurasi ti awọn mu, wa lara eeyan to pe Freeborn.

"A mu eeyan mẹta ni agbegbe Tombia lẹyin ti awọn eeyan lu ọkùnrin kan pa nitori o ji burẹdi.

A rọ awọn eeyan lati dẹkun sise idajọ lọwọ ara wọn."