"Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe jí Alága APC l‘Ekiti gbé àti bó ṣe gba ìdáǹdè"

Àkọlé fídíò, Kidnapped Ekiti APC Chairman: Àbúrò alága APC sọ bí agbébọn ṣe tú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sílẹ̀
"Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe jí Alága APC l‘Ekiti gbé àti bó ṣe gba ìdáǹdè"
Alaga ti wọn ji gbe ati agbebọn

Laipẹ yiini iroyin kan gba igboro pe awọn gende agbebọn ti ji alaga fẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ekiti, Paul Omotoso gbe lọ.

Isẹlẹ naa lo waye ni ọjọ kẹjọ osu keje ọdun 2023 yii.

Se ni ọgbagba iroyin naa gba ilẹ kan, eyi to mu ki BBC Yoruba gbera lati lọ se iwadi bii isẹlẹ naa se waye.

Amọ nigba ta fi pari iwadi wa lori bi wọn se ji alaga naa gbe lọ, ni iroyin miran tun lu sita pe awọn agbebọn ti fun Omotoso ni idande, to si ti pada sile.

Ọjọbọ, ọjọ kẹtala osu Keje naa si ni wọn fi alaga APC naa silẹ ni akata awn ajinigbe.

Eyi tumọ si pe ọsẹ kan gbako ni agba oselu naa lo ni ahamọ awọn agbebọn ọhun.

Idi ree ta se saayan lati ba alaga naa sọrọ tabi awọn mọlẹbi rẹ to mọ hulẹhulẹ nipa bi isẹlẹ ijinigbe naa se waye ati ọna ti Omotoso gba ri idande gba lọwọ awọn agbebọn naa.

Oko ti Alaga APC ti n sin adiẹ (Poultry) ni Omotoso ti n bọ, ko to bọ sọwọ awọn agbebọn - Aburo rẹ

Gbogbo iyanju BBC Yoruba lati ba alaga ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ekiti, Paul Omotoso, tawọn agbebọn ji gbe sọrọ, lo ja si pabo.

Amọ aburo rẹ,Adeyemi Adeoye David, to se agbatẹru bi alaga naa se ri idande, ba wa sọrọ lori bi isẹlẹ naa se waye ati ọna ti idande alaga naa gba sẹlẹ.

Adeyemi ni "Oko ọsin adiẹ ti alaga ni nilu Imesi lo ti n bọ, nigba to ko sọwọ awọn agbebọn to ji gbe naa.

Emi ti gbọ saaju pe wọn n jibọn loju ọna naa, ti mo si n pe aago ẹgbọn mi pe ko mase kọja lasiko naa wa sile.

Amọ ko gbe aago mi, bi mo si se n pe e, ni ipe naa n ja, lai mọ pe o ti bọ sọwọ agbebọn ni."

Adeyemi ni lati igba naa ni ara oun ko ti lelẹ mọ, ti jinijini si bo oun lori oun to le sẹlẹ si

"N20m ni awọn agbebọn pe ka mu wa amọ wọn tu alaga silẹ lẹyin o rẹyin"

Adeyemi Adeoye Davidi tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe awọn agbebọn naa gba pe ki ẹgbọn oun pe ile lati fi to wa leti pe oun ti ha sọwọ agbebọn.

"Emi ni Omotoso pe lati sọ pe wọn ti ji oun gbe, ti awọn agbebọn naa si sọ fun mi pe ogun miliọnu naira ni awọn yoo gba, ki awọn to tu silẹ́.

Mo si n taraporo pe nibo la ti fẹ ri ogun miliọnu lasiko yii.

Amọ sa, wọn tu silẹ lẹyin o rẹyin, to si pada wa sile."

Sugbọn ninu ifọrọwerọ naa, Adeyemi ko salaye boya wn sanwo idande lori Omotoso, ki awọn agbebọn naa to tu silẹ tabi bẹẹ kọ.

Bakan naa ni ko fi ye wa iye ti wọn san ninu ogun miliọnu naira naa abi gbogbo owo naa, ki alaga ẹgbẹ oselu APC naa to gba idande lọwọ awọn ajinigbe yii.