Ẹ̀lẹ́rìí sọ nílé ẹjọ́ pé Olubadan ń déte láti gba oyè Otun lọ́wọ́ Ladoja

Rashidi Ladoja

Oríṣun àwòrán, Rashidi Ladoja

Igbẹjọ ti waye lọjọ Aje nipa ẹjọ ti gomina ana nipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Rashidi Ladoja pe lori bi awọn agba oye nilẹ Ibadan se di ọba alade.

Bẹẹ ba gbagbe, a ti mu iroyin wa fun yin pe Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ti gbe ade le awọn agba oye kan lori lawọn ijọba ibilẹ mọkanla to wa nilẹ Ibadan.

Ọjọ Ẹti, ọjọ Keje osu Keje ọdun 2023 ni ayẹyẹ igbade naa waye nibi ti gomina ipinlẹ Oyo, Ẹ nginbia Seyi Makinde peju si.

Nibẹ si ni Makinde ti sọ fun eyikeyi oloye ti igbesẹ naa ko ba dun mọ ninu lati gba ile ẹjọ lọ.

Amọ Sẹnatọ Rashidi Ladoja, tii se Ọtun Olubadan tako igbesẹ gbigbe ade lori awọn agba oye naa, ti ko si yọju sibi ayẹyẹ igbade naa.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ladoja sọ pe ade Olubadan nikan ni oun n puhungbẹ rẹ, kii se ‘ade paali’ tawọn agba oye naa n de.

Eyi si lo mu ko gba ile ẹjọ lọ lati tako igbesẹ naa.

Àkọlé fídíò, Gomina ipinlẹ Oyọ tẹlẹ, Rashidi Ladoja sọrọ lori awuyewuye nipa awọn oloye ati ade dide.

Olubadan n dete lati gba oye Otun Olubadan lọwọ Ladoja tori atako to se – Lateef Popoola

Nibi igbẹjọ to waye lọjọ Aje oni, alagba Lateef Popoola tii se ọkan lara ẹlẹri ti Sẹnetọ Rashidi Ladoja pe wa sile ẹjọ bura pe Olubadan tilẹ Ibadan, Sẹnatọ Lekan Balogun ti n dete lati yẹ aga oye tun mọ Ladoja nidi ni

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n bura niwaju ile ẹjọ si ọrọ naa, Popoola ni Olubadan n dete naa lẹyin ti Ladoja tako igbesẹ rẹ lati gbe ade le awọn agba oye nilẹ Ibadan lori.

Ninu ọrọ rẹ, ẹlẹri naa ni “Olubadan nikan ni ọba ti gbogbo aye mọ to n jẹ nilẹ Ibadan, oun nikan si lo yẹ ko maa de ade.

Ilẹkẹ nikan lo yẹ ki awọn oloye maa lo sọrun nitori pe ọmọ igbimọ Olubadan lasan ni wọn jẹ.

Bakan naa si ni Ladoja ti fi to Olubadan leti pe igbesẹ gbigbe ade le awọn agba oye nilẹ Ibadan lori ko ba asa ilana oye jijẹ mu ni kete to ti n gbọ nipa igbesẹ naa lori ayelujara.

Lati igba naa si ni Olubadan, tii se olujẹjọ akọkọ ninu ẹjọ ti Ladoja pe naa, ti n dete pe oun yoo gba ilẹkẹ Ọtun Olubadan kuro lọrun Ladoja, to ba kọ lati gba ade sori bii awọn agba oye yoku.

Bakan naa ni Olubadan tun n leri leka pe Ladoja ko ni gori itẹ awọn baba rẹ lasiko to ba kan an lati di Olubadan nitori pe o kọ lati gba ade.”

Popoola wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe igbesẹ lati gbe ade le awọn agba ijoye lori nilẹ Ibadan wa lati da iyapa ati aigbọraẹniye silẹ ni.

Iha wo ni igbimọ Olubadan kọ si ẹsun yii?

Nibayii, igbimọ olugbaninimọran fun Olubadan tilẹ Ibadan, ninu eyi ti awọn agba oye nilẹ Ibadan wa, ti sọrọ lori ẹsun ti Ladoja fi kan wọn naa.

Igbimọ naa ni gbogbo ẹsun ti Ladoja fi kan Olubadan atawọn ọmọ igbimọ rẹ lo jẹ ahesọ ti ko fidi mulẹ ati awawi lasan ti ko ni gbongbo.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Olubadan, Oladele Ogunsola fisita nilu Ibadan sisọ loju rẹ pe igbimọ naa ti jiroro lori awọn ẹsun ti Ladoja fi kan wọn.

Oladele sọ pe nibi ipade naa, ni mẹjọ ninu awọn ọba to sẹsẹ gba ade pẹlu Olubadan ti koro oju si igbesẹ Otun Olubadan naa.

Igbimọ naa ni ko si ẹni to le jẹ Olubadan lai jẹ pe awọn ọmọ igbimọ Olubadan, tii wọn jẹ igbimọ afọbajẹ nilẹ Ibadan, fontẹ lu u.

Bakan naa, ninu ifọrọwerọ wọn pẹlu BBC Yoruba, diẹ lara awọn ọmọ igbimọ Olubadan naa ni ko seese ki eeyan kan soso tako eeyan mẹwa ninu igbimọ naa, ko si bori.

Awọn agba oye nilẹ Ibadan naa wa gba agba oye Rashidi Ladoja nimọran lati fi ẹṣọ se, ko si yẹ ara rẹ wo.

Àkọlé fídíò, Awọn ọmọ tó ń ta ilẹ̀ ní ìtàkutà rugi oyin nilẹ̀ Ibadan bí àwọn olóyè Olubadan ṣe gba adé

Ladoja wọ́ Makinde, Olubadan lọ Ilé ẹjọ́ lórí dídé adé fáwọn olóyè Ibadan

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Gomina tẹlẹri nipinlẹ Oyo, ẹni to tun jẹ Ọtun Olubadan ti ilẹ Ibadan, Rasidi Ladoja ti pe Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun at'awọn oloye agba mẹwaa ti wọn gba ade laipẹ lẹjọ .

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo to wa ni Ring road niluu Ibadan ni Oloye Ladọja gba lọ.

Ti a ko ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni awọn oloye agba mẹwaa gba Ade Oba lọwọ Olubadan lẹyin ti Gomina buwọle agbega wọn si Oba.

Oloye Ladọja, ẹni to wa lara awọn agba oye ilu Ibadan to yẹ ko gbade lọjọ naa kọ lati yọju sibi ayẹyẹ igbade naa.

Asẹyinwa asẹyinbọ rẹ lo fi gba ile ẹjọ lọ.

Ki lo wa ninu iwe ẹjọ ti Ladọja pe?

Ninu iwe ẹjọ ti oloye Ladoja fi pe ẹjọ naa, eyi to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ, Oloye Ladoja ni igbesẹ naa ko ba asa ile ibadan mu.

O tẹsiwaju ninu iwe ẹsun naa pe Olubadan n dunkoko mọ oun pe ti oun ba kọ lati gba Ade i awọn agba oye naa de, oun yoo rọ oun loye ni.

Bakan naa lo ni Olubadan n sọ pe ko ni si anfani fun oun pẹlu lati jẹ Olubadan nigba ti asiko ba to fun oun.

Aworan iwe ipẹjọ ati oloye Ladoja

"Gbogbo Ibadan wa labẹ isakoso Olubadan ti ilẹ Ibadan, agbega yii ni o sese ko pin ibadan, ko si tun da wahala si lẹ .

"Igbesẹ yii lodi si idajo to waye lori ẹjọ M/317/2017 to waye laarin Agba oye Rasidi Ladoja ati Gomina ipinlẹ Oyo ati ANOR, lọjọ kọkandinlogun oṣu kọkanla ọdun 2019."

O wa kesi ile ẹjọ lati se gbogbo ohun to yẹ lati dabobo asa ilẹ Ibadan, ki o si yi igbesẹ naa pada.

Ade Olubadan nikan ni mọ fẹ de - Ladoja

Saaju ni Oloye Rashidi Ladoja ni ade Olubadan nikan ni oun fẹ jẹ, oun ko ni de Ade paali.

Ladoja lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni lootọ ni oun gbọ awuyewuye nipa awọn oloye ti wọn fẹ maa de ade amọ oun ko ni nkan se nipa rẹ.

O ni ade ẹyọkan ṣoṣo to wu oun de lati igba pipẹ wa ni ade olubadan, ati pe oun ko nifẹ si ade miran.

Bakan naa lo fikun un pe ki ijọba gba awọn to nifẹ lati de ade gẹgẹ bi oloye ni aaye lati de ade wọn, kii ṣe ade ti ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo fun wọn.