Owó bẹntiróò gọbọi kò dẹ́kun fàyàwọ́ epo - Ọ̀gá Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè ké gbàjarè

Oríṣun àwòrán, NTA
Lẹyin wakati meloo kan ti awọn alaṣẹ dana sun ọkọ oju omi agbepo rọbi onifayawọ kan, Ọga ileeṣẹ aṣọbode ni Naijiria ti sọ pe owo epo ti wọn ko dẹkun gbigbe epo lọ ta lọna ẹburu.
Ọgbẹni Adewale Adeniyi to jẹ ọga ileeṣẹ aṣọbode lo tu kẹkẹ ọrọ yi lẹyin ipade to ṣe pẹlu aarẹ ni ile ijọba.
O sọ fawọn akọroyin pe yoo ṣe diẹ ki ọrọ fayawọ epo tita to dinku lawọn ibode Naijiria kọọkan.
O fi kun un pe awọn gbọ iroyin pe awọn ẹṣọ aṣọbode ri awọn kan mu to n gbe epo lọ ta nita lootọ.
Adeniyi ṣalaye pe ero awọn tẹlẹ ni pe owo epo ti di gọbọi yi ko ni jẹ iwuri fawọn onifayawọ lati ji epo lọ ta nita ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ.
''Iye epo ti wọn n gbe lọ sita lati ta ti dinku ju ti tẹlẹ lọ ati pe ireti wa ni wi pe ti a ba pari awọn eto wa taa n ṣe yoo dẹkun fayawọ epo patapata''.
Ni idahun si ibeere igba ti ijọba Naijiria yoo ṣi awọn ibode to wa ni titi pa, o ṣalaye pe oun ṣe ipade pẹlu aarẹ lori ọna ti eleyi yoo fi waye.
O ni awọn ṣi n ṣe awọn eto to yẹ lati rii wipe wọn ṣi awọn ibode Naijiria to wa ni titi pa laipẹ yii.
''Ti a ba ṣi awọn ibode yii, ko ni jẹ nkan bonkẹlẹ, gbogbo eeyan naa ni yoo mọ sii.''
O fi kun un pe awọn yoo lo imọ ẹrọ igbalode lati fi daabo bo iṣẹ ati awọn oṣiṣẹ aṣọbode Naijiria.















