‘A ò tíì gbúròó Tinubu, ohun táa fẹ́ lọ́dọ́ rẹ̀ rèé bí àwa aráàlú ṣe ń jẹ pálí ìyà toríi subsidy’

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Kii ṣe ohun to farasin mọ wipe ilu le koko lasiko yii lorilẹede Naijiria, koda, ariwo ko sowo, ko sepo, owo epo ati ọkọ di gọbọi lo gba gbogbo orilẹede Naijiria kan.

Eyi ti mu ki awọn ọmọ Naijiria jẹ ko di mimọ lori ayelujara pe bi awọn o ba tilẹ le lọ si Aso Rock, ọrọ nipa imọran ti awọn ni fun ijọba yoo ṣaa ṣee fi sita lori ayelujara boya lọna kan tabi omiran yoo kan ijọba leti.

Bi awọn kan ṣe fi oko rọ ranṣẹ si ijọba atawọn adari lawọn mii n sọ ọna abayọ ati igbesẹ to yẹ ki ijọba gbe to lee maye dẹrun fun awọn araalu.

Loju opo BBC Yoruba, oniruuru imọran lawọn araalu ti fi sita ti wọn fẹ ki ijọba Bola Ahmed Tinubu gbe yẹwo lati mu ki ilu rọ.

'Eṣu lo n dari awọn ijọba wa'

Ọrọ araalu si ijọba

Bi awọn kan ṣe n sọ ọrọ ti o le ran ijọba lọwọ ni awọn mii ko le fi ibinu ati irunu wọn pamọ si bi awọn to wa ni ipo adari ṣe n ṣe ijọba.

Ọkan lara awọn to sọrọ ni kii ṣe ẹmi Ọlọrun lo n dari awọn to wa ni ipo ijọba.

"Eṣu lo n dari awọn ijọba wa, ẹmi Ọlọrun ko si ni ara wọn rara, oun to wa lọkan wọn ni wọn maa n ṣe..."

Bakan naa ni ẹlomiran, Mathew Adebamiji Ogunyinka ṣe alakalẹ awọn nnkan to lero pe o yẹ ki ijọba gbe yẹwo lẹyin to kan sara si pe igbesẹ to dara ni bi ijọba ṣe yọ owo iranwọ epo bẹntiroo kuro.

"Ki ijọba ṣi gbogbo ibode to wọ Naijiria silẹ amọ ki wọn maa moju to wọn. Ki wọn sọ ọrọ aje di eyi to buyari sii; Eto ọgbin, okoowo ati iṣẹ agbẹ to yanranti to fi mọ idagbasoke eto ilera to dara ṣe pataki."

Bakan naa lo fi kun un pe o yẹ ki ijọba jẹ ki eto oṣelu dabii ohun to rọrun fun ẹnikẹni lati ri ṣe.

Ọrọ araalu si ijọba

'Kí ìjọba dín owó oṣù àwọn olóṣelù pàápàá, aṣòfin tì'

Ọrọ awọn araalu si ijọba

Bi Arabinrin Morounkeji Adunni-Ade ṣe ko ọrọ to ro o pẹlu alaye lọlọkan o jọkan ni awọn eeyan to ku n kan sara sii pe o ri gbogbo ọrọ rẹ sọ.

O mẹnu ba pe ki ijọba da Gomina ile ifowopamọ to ga julọ, Godwin Emefiele duro, idi eyi ni wipe inira ti awọn ọmọ Naijiria la kọja lati asiko ti wọn ṣe ayipada owo Naira atijọ si tuntun latari bi awọn eeyan ko ṣe ri owo na ko tii gbẹ lara awọn araalu tori naa, wọn ṣi n woye pe o yẹ ki ijọba fi iya jẹ adari Banki naa.

Lafikun, ẹlomiran ti orukọ rẹ n jẹ SonofMercy Marvel Ajifowobaje ni oun ro pe ki ijọba gbiyanju lati mu owo epo bẹnriroo to ga gọbọi yii walẹ diẹ na nitori wipe kii ṣe gbogbo araalu lo n gba owo oṣu latọdọ ijọba.

O ni idi eyi ni wipe ebi wa lode awọn eniyan ko si ni lee farada ebi tori ebi kii wọinu ki ọrọ mii wọ ọ.

Ọrọ araalu si ijọba
Ọrọ araalu si ijọba
Ọrọ araalu si Tinubu