‘Àwọn nọ́ọ̀sì wa ti jápa lọ sí UK tán, àwọn aláàrẹ̀ kò rí ìwòsàn tó péye mọ́’

Ise ti awọn orilẹede to ni owo lọwọ ni agbaye ṣe n gba awọn nọọsi si iṣẹ lagbaye ti da wahala silẹ lorilẹede Ghana.
Adari ajọ awọn nọọsi lagbaye ni bi Ilẹ Gẹẹsi ṣe n ko awọn nọọsi lati Ilẹ Ghana si iṣẹ ti fa ki o ma si iwosan to peye fun awọn araalu mọ.
Eyi n waye lasiko ti iwadii ileeṣẹ BBC fihan pe eto iwosan ti fidi janlẹ ni Ghana nitori aisi eto iwosan to peye.
Awọn onimọ nipa eto iwosan to jẹ nọọsi ni awọn nọọsi naa n kuro ni orilẹede wọn lati wa iṣẹ ti yoo san owo daadaa ni oke okun.
Ni ọdun 2022, o le ni awọn nọọsi 1,200 to fi iṣẹ silẹ lati lọ si Ilẹ okeere.
Bi o tiḷẹ jẹ ijọba Ilẹ Gẹẹsi ti ni wọn ko gbọdọ gba osisẹ eto iwosan lati ilẹ Ghana mọ, amọ lori ẹrọ ayelujara ni awọn eniyan ti n ri ipolongo iṣẹ ti wọn a si gbiyanju lati gba iṣẹ naa.
Gbogbo awọn nọọsi to kunjuwọn ti lọ tan’

Adari awọn nọọsi ni ajọ International Council of Nurses ni ọrọ naa kọ oun lominu nitori iye awọn eniyan to n kuro ni Ghana lọ si UK.
Bakan naa ni adari awọn nọọsi ni ileewosan Greater AccraRegional Hospital, Gifty Aryee ni nọọsi ogun lo kuro ni ẹka pajawiri laarin osu mẹfa lọ si UK ati US.
O ni eleyii n fa inira fun awọn to nilo iwosan nitori ko si olutọju to peye mọ fun awọn araalu, ti ko si si eto iwosan pajawiri fun awọn araalu.
Bakan naa ni ọrọ ri ni ileewosan Cape Coast Municipal Hospital lori aisi nọọsi to peye.
Igbakeji olori awọn nọọsi nibẹ, Caroline Agbodza ni o kere tan nọọsi mejilelogun lo ti kuro nibẹ lọ si Ilẹ Gẹẹsi laarin ọdun kan.
Bakan naa ni awọn ileewosan kekeke naa n fi ara gba ninu iṣẹlẹ naa nitori awọn oṣiṣẹ wọn naa n kuro ni ọgọọrọ ni.
Ninu alaye wọn, wọn ni ipenija naa kọja keremi ti wọn ko si le salaye ohun ti oju awọn to nilo iwosan n ri nitori ko si nọọsi tabi dokita.














