Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Anthrax to ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Federal Government
Ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè agbègbè tí ìjọba àpapọ̀ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àrùn Anthrax ti wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí ilé iṣẹ́ náà fi léde lọ́jọ́ Ajé ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ikọ̀ tó ń mójútó àrùn ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ náà ń fura pé ó ṣeéṣe kí àrùn anthrax ti wà nínú oko kan tí wọ́n ti ń sin àgbò, ewúrẹ́ àti àwọn adìẹ ní ìpínlẹ̀ Niger.
Àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera àti ìgbìmọ̀ ìjọba àpapọ̀ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì wọ inú ọgbà oko náà láti ṣàyẹ̀wò bóyá àrùn náà.
Ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ọdún 2023 ni ilé iṣẹ́ náà gba ìròyìn pé àrùn Anthrax ti wọ ìpínlẹ̀ Niger, èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní Nàìjíríà.
Èyí ń wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí àrùn yìí ti wọ orílẹ̀ èdè Ghana àtàwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ní ẹkùn iwọ̀ oòrùn Áfríkà.
Nígbà náà ni ilé iṣẹ́ yìí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti mọ ewu tó wà nínú tí àrùn yìí bá wọ Nàìjíríà.
Ní báyìí, àrùn yìí ti pa ènìyàn kan àti ẹranko tó tó ọgbọ̀n ní Ghana, tí ìròyìn sì ní o ṣeéṣe kí àwọn ènìyàn mẹ́tàlá mìíràn tún ti kó àrùn ọ̀hún.
Kí ni Anthrax?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí àmójútó àjàkálẹ̀ àrùn ṣe sọ, Anthrax jẹ́ àrùn kan tó lágbára tí kòkòrò àìfojúrí Bacillus anthracis máa ń fà.
Nínú ilẹ̀ ni àrùn yìí máa ń wà tó sì máa ń mú àwọn ẹranko káàkiri àgbáyé.
Ènìyàn le kó àrùn yìí tó bá fara kan ẹranko tó ní àrùn náà.
Anthrax lè fà àìsàn tó lágbára fún ènìyàn àti ẹranko.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oríṣi Anthrax mélòó ló wà?
Oríṣi Anthrax mẹ́rin ló wà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní àmì àti àpẹẹrẹ tó yàtọ̀.
Cutaneous anthrax: Tí irú Anthrax yìí bá mú ènìyàn, ó máa ń dàbí tí ẹ̀fọn bá jẹ ènìyàn tí ojú ibẹ̀ yóò sì máa yún ènìyàn. Ó le fa ara gbígbóná àti orí fífọ́, tí ojú rẹ̀ yóò sì padà di egbò.
Gastrointestinal anthrax: Tí ènìyàn bá jẹ ẹran ẹranko tó ní àrùn tí wọn kò sì sè é dada. Ó máa ń èébì, inú rírun, ara gbígbóná, ìgbẹ́ gbuuru tí ẹ̀jẹ̀ wà nínú rẹ̀, ọ̀nà ọ̀fun dúndùn àti kí ọrùn wú.
Inhalation anthrax: Irú anthrax máa ń wáyé tí ènìyàn tàbí ẹranko bá fa kòkòrò tó ń fa àrùn náà símú. Ohun ni oríṣi Anthrax tó burú jùlọ pẹ̀lú àwọn àmì àpẹẹrẹ bí i àyà dídùn, kí ènìyàn tàbí ẹranko má le mí dáadáa, ara gbígbóná, gìrì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Injection anthrax: Ní ẹkùn Yúróòpù ni wọ́n ti ṣe àwárí irú Anthrax yìí, láti ara abẹ́rẹ́ sì ni wọ́n ti lè ko. Àwọn àmì àpẹẹrẹ rẹ̀ ni kí ojú abẹ́rẹ́ ibẹ̀ wú, gìrì, yírùnyírùn, kí àwọn ẹ̀yà ara má ṣiṣẹ́ mọ́.

Oríṣun àwòrán, Thinkstock
Ìjọba àpapọ̀ ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ṣe ìdádúró ìtànkálẹ̀ àrùn náà.
Ní báyìí, wọ́n ti ya oko tí wọ́n ti ṣe àwárí àrùn náà sọ́tọ̀.
Bákan náà ni wọ́n tún ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn àgbẹ̀, tí wọ́n sì ti ẹranko tó wà ní oko náà ní abẹ́rẹ́ àjẹsára tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta.












