"Lóòtọ́ ni mo pa ọ̀rẹ́bìnrin mi àmọ̀ mi ò gé ojú ara rẹ̀ fún oògùn owó"

@KILLABOIGRAM/INSTAGRAM AND @AUSTA_XXO

Oríṣun àwòrán, @KILLABOIGRAM/INSTAGRAM AND @AUSTA_XXO

Ọdọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn to ṣekupa ọrẹbinrin rẹ niluu Eko, Benjamin, ti apẹle rẹ n jẹ Killaboi, ti sọ pe oun ko ge ẹya ara oloogbe naa gẹgẹ bii iroyin to gbode.

Ninu atẹjade kan loju opo ‘Instagram story’ rẹ lo ti ṣalaye bẹẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, aṣiṣe ni oun fi ṣekupa ọdọbinrin naa ati pe oun ko fi oloogbe ọhun ṣoogun owo.

Atẹjade naa ni “ẹ jọọ ẹ dẹkun ati maa sọrọ kobakungbe nipa ololufẹ mi Augusta, ọmọ daadaa ni, ọmọ daadaa si ni emi naa pẹlu, iṣoro kan ṣoṣo to walaarin wa ni ede aiyede to maa n waye ni gbogbo igba.”

“Mi o fi ọrẹbinrin mi ṣoogun owo, mo nifẹ rẹ gidi”

“Oloogbe naa mọ iṣẹ ti mo n ṣe, o si mọ pe ọwọ mi mọ.”

“Owo mi kii ṣe owo ẹjẹ, kii sii ṣe ohun to buru pe awa mejeji yofẹ ara wa.”

Afurasi ọhun tẹsiwaju pe “o ti to ọdun meji ti a ti n fẹ ara wqa bọ, ko si ṣeeṣe fun mi lati fi ololufẹ mi ṣe oogun owo, ẹ dẹkun ati maa sọrọ buruku nipa rẹ.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ija lo waye laarin awọn ṣaaju iṣẹlẹ naa amọ ohun ko le tu iṣu de isalẹ ikoko ọrọ naa lọna ati ma ba orukọ oloogbe naa jẹ.

“Mo ṣetan lati jọwọ ara mi fun ọlọpaa”

Killaboi ṣalaye pe laipẹ laipẹ lai jina oun yo jọwọ ara oun fun awọn ọlọpaa nitori pe oun fẹran oloogbe naa doju iku.

Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ṣetan lati foju wina ofin lori iṣẹlẹ naa, kii ṣe nitori ahesọ awọn eeyan pe oun lo oloogbe naa fun oogun owo.

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, fidi rẹ mulẹ fun BBC pe oju ara oloogbe naa ko si lara rẹ mọ lasiko ti awọn ṣawari oku rẹ.

Àkọlé fídíò, Men who trained on house chores: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú kí ọkùnrin máa ṣiṣẹ́ ilé

Ọlọ́pàá Eko bá òkú ọmọge nínú ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ , ìwádìí bẹ̀rẹ̀

@KILLABOIGRAM/INSTAGRAM AND @AUSTA_XXO

Oríṣun àwòrán, @KILLABOIGRAM/INSTAGRAM AND @AUSTA_XXO

Ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Eko ni oun ti bẹrẹ iwadii iku ọdọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Onuwabuagbe Augusta Osedion, ti ọrẹkunrin rẹ Benjamin, ṣekupa.

Benjamin, ti apẹle rẹ n jẹ ‘Killaboi’ ti jẹwọ loju opo Instagram rẹ pe lootọ oun loun ṣekupa ọdọbinrin naa.

Gẹgẹ bii ohunto lori ‘Instagram story,’ o ni ede aiyede kan lo waye laarin awọn mejeji ti oun si ṣeṣi gun oloogbe naa pa.

Killaboi sọ loju opo naa pe oun yoo jọwọ ara oun fun awọn ọlọpaa lati jẹ iya to tọ labẹ ofin.

O tun ṣafihan loju opo Instagram naa awọn oniruru atẹjiṣẹ to fi ṣọwọ si iya oloogbe ọhun pe oun kọ mọọmọ gbẹmi ọmọ rẹ.

Bi ọlọpaa ṣe ṣawari oku Augusta

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ni ọjọ kọkanla, oṣu Karun un yii ni iya oloogbe naa, Onwabhagbe Cordelia, kọkọ fi to awọn ọlọpaa leti pe oloogbe naa sọ fun oun pe ija wa laarin oun ati ọrẹkunrin oun.

Hundeyin ni iya obinrin ọhun gbiyanju lati pari aawọ awọn ololufẹ naa amọ o ṣoro lati kan si awọn mejeji lori ẹrọ ile wọn ati loju opo ayelujara.

Cordelia ni ọrẹ oloogbe naa kan lo ṣamọna bi oun ṣe wa lọ si ile ti afurasi naa n gbe Oral Estate, ni Okota nibi ti wọn ti ri ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes Benz C30 to jẹ ti oloogbe ọhun amọ wọn ko ri aye lati wọle.

Hundeyin ṣalaye siwaju si pe awọn ọlọpaa to wa ni Ajah lo lọ sile naa ti wọn si ja ilẹkun rẹ nibi ti wọn ti ṣawari oku Augusta.

Ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe wọn ti ge oju ara oloogbe naa lọ amọ wọn ba oku rẹ to ti n jẹra.

Agbẹnusọ ọlọpaa fi kun pe awọn ri ami ipa ati ijakadi lara oloogbe naa, awọn si ti gbe oku rẹ lọ sile igbokusi nile iwosan fun ayẹwo ati iwadii.

O ni wọn tun ri iwe kan ti afurasi naa kọ silẹ lẹba oku ọrẹbinrin rẹ ọhun eyii ti awọn ti mu gẹgẹ bii ẹri.

Ta ni Killboi?

Killaboi

Oríṣun àwòrán, @KILLABOIGRAM/INSTAGRAM

Gẹgẹ bii akọle to wa loju opo Instagram rẹ, iṣẹ “Blockchain Developer and Crypto Purveyor” lo n ṣe.

O sọ nibẹ pe iye owo ti oun ti pa lori tẹtẹ tita laarin ọdun 2022 si 2023 ti le ni ọọdunrun miliọnu naira.

O tun kọ sibẹ pe aye oun ti dojuru latatari pe oun ṣeku pa ọrẹbinri oun.

Ta ni Augusta?

Onuwabuagbe Augusta Osedion

Oríṣun àwòrán, @AUSTA_XXO/INSTAGRAM

Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Onuwabuagbe Augusta Osedion to jẹ akẹkọọ fasiti Lead City to wa niluu Ibadan.

O juwe ara rẹ loju opo Instagram gẹgẹ bii gbajumọ lawujọ.

Nnkan bii ẹgbẹrun mọ́kàndínláàdọ́fà (109,000) eeyan lo n tẹle loju opo Instagram naa.