Ojú ọjọ́ tó gbóná jain-jain gbòde ní ilẹ̀ Yuroopu àti Ilẹ̀ Amerika

Aworan

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn onimọ nipa oju ọjọ ti kede oju ọjọ to gbona jain-jain ni agbegbe Guusu Yuroopu, ati ila Guusu-ariwa orilẹede Amẹrika.

Awọn onimọ ni oṣeeṣe ki oju ọjọ naa tun gbọna ju bi o ṣe wa lọ, ti wọn si ni ki awọn eniyan gbaradi lati da abo bo ara wọn lasiko yii.

Ni orilẹede Italy, ileeṣẹ eto ilera ti fi ikede ilu ofararọ sita fun awọn ilu mẹrindinlogun ni orilẹede naa.

Awọn agbegbe bii Acropolis ni Athens ni iwọn oju ojo 40C, nigba ti awọn agbegbe miran si n koju ina to n jo nitori oju ọjọ to gbona jain-jain, paapaa ni agbegb La Palma ni ilẹ Spain.

Ni orilẹede Amẹrika. Awọn agbegbe guusu-ariwa ilẹ naa pẹlu awọn eniyan ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu si n koju oju ọjọ gbigbona.

Ijọba ti fi ikilọ lede pe ki awọn eniyan da aabo bo ara wọn nitori oju ọjọ to gbona jain-jain pẹlu iwọn 53.9C ni agbegbe Death Valley, ni ilu Carlifornia.

Ni ilu London ni awọn eniyan ti ri ojo diẹ pẹlu afẹfẹ to tutu diẹ, amọ awọn agbegbe miran ko ri bẹẹ.

Kini itumọ oju ọjọ gbigbona?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Asiko oju ọjọ to gbona ni igba ti awọn eniyan ba n koju oju ọjọ to gbona jainjain ju igba miran lọ laarin ọdun.

Awọn onimọ ni asiko yii n peleke si nitori iṣoro oju ọjọ to n se segesege.

Wọn fikun un pe eyi tunmọ si pe oju ọjọ gbigbona yii yoo tẹsiwaju si, ti yoo si buru jai.

Ajọ to n siri oju ọjọ ni ilẹ yuroopu, The European Centre for Medium-Range Weather ni kaakiri agbaye, osu kẹfa yii lo gbona julọ.

Wọn si pe orukọ rẹ ni Charon ti wọn ni ohun ni ọkunrin to n gbe awọn eniyan lọ si ọgbun isalẹ ilẹ.

Awọn ami pe ara n gbọna jainjain lasiko oju ọjọ to gbona jainjain;

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

  • Yio ma se eniyan bi ẹni to fẹ daku
  • Lilaagun kọja ala
  • Ki ara maa gbona
  • Eebi abi ki eebi maa gbe eniyan
  • Ki egun maa ro eniyan

Awọn aworan oju ọjọ to gbona jainjain ree...

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images