Àwọn èèyàn bú mi pé mi ò kàwé mo dẹ̀ fẹ́ ṣe gómìnà ló jẹ́ kí ń kàwé yọrí – Adeleke

Oríṣun àwòrán, @AAdeleke_01
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ti sọ pe ọjọ ori ko yẹ ko di eeyan lọwọ ati kawe.
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade fasiti Adeleke to wa niluu Ede, Adeleke ni lara gbedeke ti wọn fun oun ti oun ba fẹ de ipo gomina ipinlẹ naa ni ki oun kawe yọri.
Lẹyin to lulẹ ninu ibo gomina ọdun 2018, o ni ọpọ igba lawọn eeyan maa n bu oun, eyii to mu ki oun tẹkọ leti lọ soke okun lati lọ pari ẹkọ oun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbesẹ lati pari eto ẹkọ naa ko ṣẹyin imọran ẹgbẹ oun, Deji Adeleke to ni oun gbọdọ kawe naa pari tabi ki oun gbagbe pe oun fẹ di gomina.
“Imọran Tajudeen Adeleke lo mu ki n kawe yọri”

Oríṣun àwòrán, @AAdeleke_01
O ni “Ọmọwe Tajudeen Adeleke lo fun mi ni iwuri lati kawe siwaju.”
“Ki n to lọ silẹ okeere, o pe mi si ipade kan nibi ti a ti sọrọ.”
“O sọ fun mi pe ki n wo bi awọn eeyan ṣe n yẹyẹ mi pe mi o kawe, lẹyin naa lo gba mi ni imọran lati lọ kawe nilẹ Amẹrika.”
“O jẹ ko ye mi pe oun kan ṣoṣo ti mo le ṣe fun awọn eeyan ipinlẹ Osun ti mo ba ṣetan lati di gomina ni ki n kawe, o sọ pe mo gbọdọ kawe yọri, amọ ti mo ba kọ lati pari ẹkọ mi, ki n gbagbe pe mo fẹ ṣe gomina.”
Adeleke tẹsiwaju pe “pẹlu ọjọ ori mi lasiko naa, mo lọ gba fọọmu, mo si kawe yọri.”
“Ohun iwuri lo jẹ fun mi bayii pe mo gbe igbesẹ ọhun, mo si dupẹ lọwọ awọn ẹbi atawọn ọrẹ mi fun atilẹyin wọn.”
“Ẹkọ to wa nibẹ ni pe ki a maṣe jẹ ki ọjọ ori di wa lọwọ iwe kika.”
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ naa, oludasilẹ fasiti ọhun, Ọmọwe Deji Adeleke ni Naijiria yoo dara ti gbogbo mutumuwa ba fọwọsowọpọ lati tun Naijiria ṣe.
Lẹyin naa lo ke si awọn araalu lati ṣe ojusẹ fun ilọsiwaju Naijiria.












