Èló ni iye owó tó lè parí ilé oníyàrá méjì lásìkò yìí ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Elo ni eeyan lilo lati fi kole lonii lorilẹede Naijiria?
Eyi ni ibeere tí awọn eeyan n bere lẹyin ti akọle kan kede lori ayelujara pe oun le fi milọnu marun-un naira ko ile oni yara meji.
Abraham MacHills gbe ọrọ yii sori ayelujara Twitter rẹ lọjọ Aiku to kọja, ọjọ kẹsan an oṣu keje
O ni "Pẹlu 5m, ma kọ ile oni yara meji fun yín, ti o ba ti ni ilẹ."
Atẹjade yii lo fa ọpọlọpọ awuyewuye lori ayelujara laarin awọn onkọle, awọn to mọ nípa eroja ile kíkọ ati awọn to ti kọ ile tabi ti wọn gbinyanju lati kọ ile.
Bí àwọn kan ṣe n sọ pe o sese ni awọn miran ni yoo nira lati fi 5m kọ ile lode oni ni Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter
Elo ni owo to le kọ ile loni ni Naijiria?

Oríṣun àwòrán, others
Lati mọ nípa elo ti yoo gba lati kọ ile lorilẹede Naijiria pẹlu bí nnkan ṣe wa pẹlu ọrọ aje wá, BBC News ba awọn onimọ nípa ile kíkọ sọrọ.
Akọwe fun ẹgbẹ Nigeria Institute of Building, Adelaja Adekanmi ni ko sẹsẹ fi milọnu marun-un ko ile oni yara meji pẹlu bi nnkan ṣe wọn lasiko yii.
Ṣugbọn o ni o sese kanipe eeyan fẹ kọ ile naa lọpọlọpọ nitori wọn yoo ro gbogbo ohun ile lati kọ ile naa papọ.
"N5m ko le kọ ile, kí eeyan lọ sọja lati mọ bí nnkan ṣe wọn si. Apo simẹnti naa wọn, ayafi ti eeyan naa ba fẹ kọ ile fun ẹranko sugbọn to ba jẹ pe eeyan lo fẹ gbe ibẹ, owo naa kere."
"Fun ile gidi to jẹ fun eeyan, N5m ko le kọ."
Onimọ mìíran, Muhammad Saad ni ile kíkọ da lori eroja tí eeyan fẹ lo, ilana ti eeyan fẹ lo ati iru ile ti eeyan fẹ kọ.
O fikun pe kikọ oni yara meji igbalode pẹlu milọnu pẹlu bi ọrọ aje ṣe ri ni oun ko le sọ boya o sese ayafi ti akọle ba lo awọn eroja tí gbe owo lori fun ile naa.
"To ba jẹ awọn biriki tí ko ki n se igbalode ni, o sese nítorí onkọle ko ni na owo lori ọda ati kikun ile naa ati pe owo diẹ ni yoo fi fana ati omi wọ ile ọhun."
Kíkọ ile fun milọnu marun-un sese - Abraham Mac-Hill

Oríṣun àwòrán, others
Bi ọrọ naa se n fa ọpọlọpọ awuyewuye lori ayelujara, ileeṣẹ BBC News ba onkọle Abraham MacHills to gbe ọrọ naa sórí ayelujara sọrọ lori pe njẹ o ṣeeṣe lati fi milọnu marun-un kọ ile oni yara meji.
MacHills ni o ṣeeṣe nítorí oun ko nilo ilẹ to tobi ati pe o ṣeeṣe tí ilẹ ko ba ti n se ilẹ omi.
O tẹsiwaju pe oun ko ni eroja aja gẹgẹ bii awọn eeyan ṣe n sọ ati pe oun ko gba oṣisẹ pupọ.
"Eroja Inferior tí a ma lo jẹ bi owo rẹ ba ṣe mọ, granite wa, iyẹpẹ wa, simẹnti wa."
MacHills ni o ṣeeṣe fun oun lati fi milọnu marun-un kọ ile oni yara meji nitori oun ko nilo lati pe onimọẹrọ.
"Wa a ya machine, ra simẹnti, iyepẹ lati mọ bilọki fun ara rẹ.
"Bilọki to to ẹgbẹrun meji ti to, gbogbo owo ti a maa sori ferese ni ko kọja N175,000.
MacHills ni oun kọkọ ma n se iwadii ti oun yoo si wa ibi tí won tí n ta awọn yii to sunmọ ibi ti ile wa, tí oun yoo si ra gbogbo rẹ ni ẹẹkan naaa.
Ọpọ eeyan lo ni ile ọhun ni ko ni dabi eyi to wa ninu aworan ṣugbọn MacHills ni gẹlẹ bí o ṣe wa ninu aworan ni oun yoo kọ ile naa.
"Ile naa yoo ni gbogbo nnkan to yẹ ko ni ayafi aga."
O ni awọn ọdọ ni oun ni lérò, paapa awọn ti wọn lowo lọwọ ti wọn fi n ra awọn nnkan ti ko yẹ.
Ileeṣẹ BBC News ko fi idi rẹ mulẹ boya akọsẹmọsẹ ni onkọle yii.
Gẹgẹ bii o se wa lori ayelujara rẹ Abraham MacHills sapejuwe gẹgẹ bii onkọle pẹlu ileeṣẹ Valley Hill Construction.
Adelaja ninu ọrọ tìẹ ni owo ile kikun da le lori ibi tí eeyan fẹ kọ ile ọhun sì
O ni nitori pe owo eroja ile yatọ ni awọn agbegbe kan
O tẹsiwaju wipe ni awọn agbegbe bí Mowe, Ibafo, Ijebu-Ode, Sagamu, Epe, eeyan le fi milọnu meje kole oni yara meji ti igbalode sugbọn ni awọn agbegbe kan nipinlẹ Eko eeyan yoo nilo milọnu mẹwaa.
O ni awọn ile oni yara mẹta ati awọn ile nla miiran le na eeyan ni milọnu mẹẹdogun si mẹẹdọgbon naira
Elo ni awọn eroja ile ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, others
Oludasilẹ ileeṣẹ Jarus Homes, Suraj Oyewale to n se isẹ ile kilọ ṣe agbekalẹ iye tí awọn n ta eroja kọọkan lati kọ ile oniyara meji.
Ẹlomiiran lori ayelujara @mistervosa ṣe afihan iye tí abanikọle fẹ gba lati fi kọ ile oni yara meji fun un.
Iron rod: 12m - 1 ton - N500k
10mm Iron rod fun : 250k
Granite– fun N300k
Iyepẹ - N120k for 5 trips
Iyepẹ fun rirẹ ile- N69k fun irinajo meji
Awon arẹle – N300k
Irin ferese - N56k fin eyo kan
Lilẹ Tiles – N1.25m
Tiling ati awon osise - N400k
Omi borehole – N250k
GP tanki Omi – N56k
Ceiling - N700k
Ile idana - N550k
Fi fa ina wole - N1.850m
Fifa omi wole – N450k
Sanitary wares – N320k
Carpenter, ki kan ile – N100k
Owo akanle - N120k
Bricklayer 2500 bilọki x 80 naira
bilọki 2500 pieces x N500
Simẹnti fun gbogbo isẹ: bagi 300 x N5000 = N1.5m
Ceiling ita- N350k
Igi ferese – N420K
Ilẹkun ita – N180k fun eyokan
ileẹkun ninu ile – N67k per one
Foundation digging, foundation laterite filling labour - N550k












