Ìjọba Ekó fẹ́ ti afárá Eko Bridge fún wákàtí 24

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe awọn yoo ti afara to wọ Eko bridge lati Apongbon Bridge fun wakati mẹrinlelogun ni Ọjọ Aiku.
Ijọba ni awọn n gbe igbeṣẹ naa lati ṣe atunṣe awọn ibi to bajẹ ni ori afara naa.
Awọn ti yoo ma sakoso atunṣẹ naa ni ileeṣẹ to n risi iṣẹ akanse nipinlẹ Eko, ni ajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ ijọba apapọ to n risi ọrọ iṣẹ ati ileegbe.
Akọwe agba ni ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko, Abdulhafiz Toriola ni titi ori afara naa fuin wakati mẹrinlelogun yoo fun awọn ni anfaani lati tete ṣe awọn ibi to ti n bajẹ nibẹ.
Bakan naa ni ijọba ni awọn ẹṣọ oju popo yoo wa ni ikalẹ lati ripe eyi ko fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ni oju popo naa.
Agbegbe to ṣeeṣe ki titi afara naa sakoba fun ni awọn to n bọ lati agbegbe CMS, Marina, Ijora, ati awọn ọna miran to wọ Lagos Island ati Lagos Mainland bakan naa.
O ni atunse naa pọn dandan fun afara Apongbon ti wọn ṣẹṣẹ ṣi.
Awọn ọna miran ti awọn eniyan le gba ni asiko ti wọn ba n sẹ atunṣe naa ni;

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ti wọn ba n bọ lati Mainland si Surulere lọ si Lagos Island ni wọn gba ni iyanju lati gba Ijora-olopa/causeway si carter Bridge(Idunmota) lati le de ibi ti wọn ba n lọ.
Tabi ki wọn gba Costain jasi Igannu lati Ijora-Oloye si Ijora Causeway si Carter Bridge (Idumota) lọ si ibi ti wọn ba n lọ.
Bakan naa ni wọn ni awọn onimọto le gba Carter Bridge(Idumota) lọ si Ijora ọlọpa, gba LAWMA si Eko Bridge lọ si Costain/Alaka lọ si ibi ti wọn ba n lọ.
Ijọba gba awọn ara ilu ni imọra lati tun lọ afara Third Mainland Bridge lati jasi Adekunle ki wọn si gba ibẹ de Herbert Macauly lati lọ si ibi ti o ba wu wọn
Wọn gba awọn eniyan nimọran lati ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹṣọ oju popo ki wọn le rin lai si ewu.

















