Nígbà wò ni ààrẹ Tinubu yóò kéde àwọn dúkìá rẹ̀? Aráàlú ń bèèrè

Ibeere yi lawọn ọmọ Naijira kan ti n sọ nipa rẹ ni kulẹkulẹ ko to di pe o ta si eti igbọ wa.
Ninu ohun ti wọn n beere ni pe njẹ ofin sọ ọ di dandan ki aarẹ kede dukia rẹ ati pe ki lo de ti ko fi tii. kede rẹ sita faraalu lati gbọ.
Awọn miran tilẹ sọ pe aarẹ ko jẹ ẹnikankan ni gbese lati sọ dukia rẹ faraalu.
Ki gaan ni iwe ofin Naijiria sọ nipa kikede dukia fawọn to ba di ipo mu nijọba ati pe ipa wo ni kikede dukia yi ni fun idagbasoke ijọba awarawa?
Wọnyi lawọn idahun taa gbiyanju lati wa ki ọrọ baa le niyanju.
Ẹ ma gbagbe pe ibi taa ti bẹrẹ ọrọ si ni pe igba wo ni aarẹ yoo kede dukia rẹ faraalu.
CCB, SERAP atwọn mii ti n ke si aarẹ tipẹ
Ka to rin jina, ẹ jẹ ki a fi to ara wa leti pe a o le sọ pato boya aarẹ ti kede dukia rẹ ni gbangba tabi ni ikọkọ.
Idi ni pe ikede lori ọrọ yi ko tii waye lati ọdọ awọn agbẹnusọ aarẹ.
Eleeyi to han si wa gbangba ni pe ajọ Code of Conduct Bureau to n mojuto iṣesi awọn to dipo mu ni ijọba ti ṣaaju kede ọrọ lori kikede dukia yi.
Ninu nkan ti wọn sọ CCB kesi aarẹ, igbakeji rẹ ati awọn gomina mejidinlọgbọn ti wọn ṣẹṣẹ yan pe ki wọn kede dukia wọn saaju ki wọn to burawọle si ipo fun wọn ni ọjọ Kọkandinlọgbọn.
Yatọ si ajọ yi to kesi aarẹ, awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan mii lorileede Naijiria bi SERAP tikesi aarẹ pe ko jẹ ki araalu mọ iyi to ni ko to bura sipo gẹgẹ bi aarẹ.
Ọrọ tiwọn atiaṣẹ ti ajọ CCb fi sita yi la gbọ kẹyin lori ọrọ ikede dukia aarẹ ati igbakeji rẹ.
Loju opo ayelujara bi eeyan ba gbiyanju lati wa iroyin nipa boya aarẹ ti kede dukia rẹ tabi ko yi ti kede rẹ, ko si nkankan to tọka si igbesẹ yi rara.
Ki ni ohun ti ofin sọ nipa kikede dukia?
Agbẹnusọ fun ajọ CCB, Abilekọ Veronica Kato sọ fun BBC pe jijẹwọ ohun ini awọn ti araalu dio yan wa lara eto iburawọle sipo fun wọn.
O ni ọpọlọpọ awọn ti wọn dibo yan naa lo ti wa gba fọọmu ikede ohun ini wọn ni awọn olu ile iṣẹ wọn ni awọn ipinlẹ Naijiria.
O tẹsiwaju pe ikede yi wa ni ibamu pẹlu ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.
Bẹẹ lo sọ pe iwe ofin Naijiria fi lede pe gbogbo oṣiṣẹ ijọba ni yoo kede awọn ohun ini rẹ kete ti wọn ba ti bẹrẹ iṣẹ ijọba wọn ati lẹyin saa wọn ni ipo.
''Labẹ ofin naa, ẹnikẹni to ba kọ lati kede ohun ini rẹ lo ṣeesẹ ki wọn yọọ ni ipo, ki o si ma lee di ipo miran mu lorilẹede Naijiria.''
Bakan naa ni ajọ ọhun fikun un pe ẹnikẹni to ba kọ lati kede ohun ini rẹ ni wọn ko ni bura wọle fun.
Wọn fikun un pe ofin Naijiria paṣẹ pe ọkan lara eto iburawọle ni ki awọn ti wọn ba dibo yan kede awọn ohun ini wọn.
Yar'Adua, Buhari, Osinbajo kede dukia wọn lasiko ti wọn wa lori oye
Lẹyi taa le yara tọka si gẹgẹ bi apẹrẹ awọn aarẹ atiigbakeji wọn ti wọn kede dukia wọn nigba ti wọn wọle sipo ati lẹyin ti wọn fipo silẹ ni aarẹ to jẹ tẹlẹ ri Umaru Musa Yar Adua.
Ninu apẹrẹ to fi lelẹ nigba naa lọhun oun ati igbakeji rẹ Goodluck Jonathan kede faraye gbọ iye dukia ti wọn ni.
Nigba ti aarẹ Buhari naa kọkọ de ori ipo, awọn araalu beere ki o to pada kede dukia rẹ.
Koda nigba naa lọhun agbẹnusọ aarẹ Femi Adesina sọ pe ko ṣe dandan ki aarẹ jẹwọ dukia rẹ nita gbangba faraalu.
O ni bi o ba wu aarẹ o le sọ ni ikọkọ bo baa si wu o le sọ ni gbangba.
Alaye to ṣe ni pe sisọ tabi kikọ lati sọ ku si ọwọ aarẹ.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Tinubu ati awọn eekan mii ti ṣaaju jẹjọ ọrọ dukia lọdọ CCT
Aarẹ lonii Bola Tinubu kii ṣe ajoji si awuyewuye ọrọ kikede dukia lọdọ CCT.
Nigba naa lọhun lọdun 2007 lẹyin to pari saa rẹ gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Eko, ajọ yi pe lẹjọ lati wa sọ idi ti ko fi kede gbogbo dukia rẹ labẹ ofin.
Ninu ẹsun ti wọnfikan Tinubu ni pe o lawọn akoto owo ilẹ okere kan ti ko jẹwọ rẹ gẹgẹ bi tiẹ lasiko to wa lori oye gẹgẹ bi Gomina.
Ẹjọ yi fori sanpọn ti adajọ si ni ki Tinubu maa lọ sile layọ ati alaafia tori pe ko si ẹri wipe oun lo ni akoto owo mẹwaa ti awọn to pe e lẹjọ s pe o kọ lati jẹwọ rẹ.
Yatọ si Tinubu awọn eekan miran ree tawọn naa jẹjọ niwaju ajọ CCT lori ọrọ aikede dukia wọn.
- Bukola Saraki aarẹ ile aṣofin agba Naijiria tẹlẹ
- Ike Ekweremadu- Sẹnẹtọ ati igbakeji aarẹ ile aṣofin agba nigba kan ri
- Sylvester Ngwuta- Adajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria
- Godsday Orubebe-Minisita fọrọ agbegbe Niger Delta tẹlẹ ri
- Walter Onoghen- Adajọ agba lorileede Naijiria tẹlẹ ri












