Onnoghen: Adájọ́ àgbà ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan òun

Oríṣun àwòrán, @todayng, @SERAPNigeria
Ile ẹjọ CCB ti fi gbé Adajọ́ Agba Walter Onnoghen lọ ilé ẹjọ́ CCT níbi tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn alábala mẹ́fa, eyí tó dá lórí pe kò jẹ́wọ́ awọn dukia rẹ̀ ati awọn owo kan to ni sile ifowopamọ.
Ọjọ́ Ẹti lo farahan niwaju ile ẹjọ naa, ti wọ́n si ka awọn ẹsun rẹ sii. Onnoghen ni oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.
Ile ẹjọ́ naa si gba oniduro, wọ́n ni nitori ilumọ̀ọ́ká ni, ko le sálọ.
Agbẹjọ́rò rẹ̀ Oloye Chris Uche (SAN) ní o bẹ̀bẹ̀ lọ́wọ́ ile ẹjọ́ lati sun igbẹjọ́ naa di ẹyin idibo.
Uche tun rọ ile ẹjọ́ latí fagile iwe 'farahàn tipátipá' tí ajọ naa fi gbé Onnoghen, nitori pe adajọ agba naa ti funra rẹ wa sile ẹjọ.
Alaga ile ẹjọ naa, Adajọ Danladi Umar gba si agbẹjọro Onnoghen lẹnu, o gba oniduro rẹ, o si fagi le iwe 'farahàn-tipátipá' ti wọn ti gbe jade tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Yomi Shogunle/Twitter
Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari ni ki Onnoghen lọ rọkun nile ti o si fi Adajọ Mohammed Tanko rọpo rẹ.
Awọn ọmọ Naijiria, ẹgbẹ awọn agbẹjọro fi ẹhonu wọn han wipe, igbesẹ̀ aarẹ naa ko tọ́na.













