Àwọn ọmọ Nàìjíría ń kọminú lórí 70 bilìọ̀nù táwọn aṣòfin àpapọ̀ yà sọ́tọ̀ fún ara wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ẹka ile aṣofin apapọ mejeeji ṣe buwọlu aadọrin biliọnu Naira (N70billion) gẹgẹ bi owo iranwọ fun ara wọn ti n da họwuhọwu silẹ laarin awọn ọmọ Naijiria.
Awọn ọmọ Naijiria kan ti n fapa janu loju opo Twitter lori akoko ti awọn aṣofin apapọ n gbe igbesẹ yii.
O le oṣu kan sẹyin ni ijọba yọ owo iranwọ ori epo ti o si ti n mu ọpọ inira ba awọn ọmọ Naijiria.
Yiyọ owo iranwọ epo ti mu ki owo ọkọ ati ounjẹ goke ni gọbọi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
“Awọn aṣoju lati ẹgbẹ oṣelu meje li wa ni ule aṣofin apapọ Naijiria, LP, PDP ati NNPP wa lara wọn, ko si si eyikeyi ninu wọn ti kọ aadọrin biliọnu yii. Ẹ rii bayii oe bi ọrọ ba ti di ọrọ owo, awọn oloṣelu Naijiria kii fẹ sọrọ.”
Awọn ọmọ Naijiria kan n fapa janu pe owo yii pọ ju iwo iranwọ biliọnu mọkandinlogun ti wọn fun awon agbẹ ti agbara ojo gba nnkan oko wọn lọdun to kọja.
ẹgbẹta eeyan ni agbara ojo baa ran lọ sọrun ti ẹgbẹlẹgbẹ miran si di alainilelori
owo ti awọn aṣofin pin mọ ara wọn lọwọ gẹgẹ bi ara owo iranwọ wa ninu owo alekun iṣuna ti wọn buwọlu pẹlu ẹdẹgbẹta biliọnu naira ti aarẹ Tinubu beere fun lati san owo itura fun irora araalu lori owo iranpọ epo.
Ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọnìyàn kan, SERAP ti lerileka oe awọn yio gbe ọrọ naa lọ si ile ẹjọ bi awon aṣofin apapọ naa ko ba tete yi ohun pada lori owo naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ileeṣẹ akoroyin jọ NAN salaye pe awọn aṣofin apapọ n wi awijare lori owo naa gẹgẹ bi owo ẹtọ to tọ si wọn fun atunṣe ile ati ohun gbogbo ti wọn nilo lati si ẹru won lọ silu Abuja.
Ida aadọrin awọn aṣofin saa kẹwaa ile aṣofin apapọ Naijiria ni wọn jẹ ṣẹṣẹ de to jẹ pe igba akọkọ wọn niyi gẹgẹ bi aṣofin.
ọpọ igba lawọn ọmọ Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu awọn aṣofin apapọ nitori owo gọbọi to ju iṣẹ ọwọ wọn lọ ti wọn ro pa awọn aṣofin naa n gba.
Lati ọdun 2017 lawọn aṣofin apapọ si ti kọ lati sọ ni pato iye ti wọn n gba faraalu.












