Emefiele tún fi ẹ̀yìn DSS janlẹ̀, iléẹjọ́ míràn ní kí wọ́n tú u sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, central bank of nigeria
Ileẹjọ giga miiran to niluu Abuja tun ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ agbofinro DSS tu gomina banki apapọ NAijiria tẹlẹ, Godwin Emefiele silẹ kiakia.
Ile ẹjọ giga apapọ naa ti bu ẹnu atẹlu bi ajọ DSS se gbe Emefiele si ahamọlainaani awọn aṣẹ ti ile ẹjọ kan ti pa ṣaaju lori igbesẹ wọn.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Bello Kawu to gbọ ẹjọ mo fẹ ja fun ẹtọ mi ti Emefiele pe tako DSS, ni bi DSS ṣe fi agidi ha a mọ ahamọ rẹ labẹ awawi ati fi ọrọ wa a lẹnu wo lodi si idajọ ati asẹ ti ile ẹjọ miran labẹ Onidajọ M.A Hassan ti kọkọ pa.
Agbẹjọrọ fun Emefiele, Peter Abang rọ ileẹjọ naa pe ko wogile igbesẹ DSS nitori ko ba ofin mu ati pe o lodi si idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila ọdun 2022.
Adajọ Kawu tun wa pasẹ pe wọn ko gbọdọ fi ofin mu Emefiele fun ẹsun kan tabi omiran lai gba asẹ .
Bakan naa ni Adajọ fi ofin de ajọ DSS lori dida si ọrọ to ba jẹ mọ ọrọ Emefiele, wọn ko si gbọdọ fi si ahamọ tabi fi ọrọ wa lẹnu.
DSS ti gbé Emefiele, gómìnà báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ lọ sílé ẹjọ́
Ileeṣẹ Agbofinro DSS lorilẹede Naijiria ti gbe gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ, Godwin Obaseki lọ si ile ẹjọ.
Igbesẹ yi n waye lẹyin ti ile ẹjọ giga kan nilu Abuja paṣẹ lọjọbọ pe ninu ki wọn gbe e lọ si ile ẹjọ tabi ki wọn da a silẹ, DSS gbọdọ fi ọwọ mu ọkan laarin ọsẹ kan.
Agbẹnusọ fun DSS, ọmọwe Peter Afunaya fi idi rẹ mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lalẹ Ọjọbọ pe wọn ti pe e lẹjọ nile ẹjọ ni ibamu oẹlu aṣẹ ti ile ẹjọ pa.
O ni lati ọdun 2022 ni awọn ti n kan si ile ẹjọ lori ọrọ Enefiele lati le fi panpẹ ofin gbe enitori awọn ẹsun iwa ọdaran kan to n ra baba lori rẹ
“Lootọ , Emefiele gba idajọ kan lati ile ẹjọ eti to ka wa lapa ko lati ma lee gbe e loṣu kẹfa ọdun 2022, amoṣa ẹru ẹsun to tun ṣẹṣẹ n ṣẹyọ, kun ara idi to fi n jẹjọ bayii “

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ile ẹjọ giga to wa ni ilu Abuja ti paṣẹ pe ki wọn fi gomina ile ifowopamọ to ga julọ ti ijọba ni ko lọ rọọkun nile, Godwin Emefiele silẹ ko maa lọ ni alafia.
Eyi waye ni ile ẹjọ lonii gẹgẹ bi agbẹjọro fun Emefiele ati agbẹjọro ti ijọba 'se jọ n takurọsọ.
Agbejoro ti ìjọba ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Godwin Emefele jẹ́ àwọn ẹ̀sùn ọ̀daràn.
Ni ti Agbẹjọro fun Godwin Emefele, ó tako bí wọn ṣe mú Godwin Emefele to jẹ́ gómìnà àná fún ilé ìfowópamọ lorileèdè Nàìjíríà lòdì sí òfin ẹ̀tọ́ ọmọniyan.
"Bí wọ́n ṣe fi páńpẹ́ òfin mú oníbarà mi, Emefele gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn kò bójú mú àti pé ó lọ́wọ́ òsèlú nínú."
Torí náà, agbẹjọro fún Godwin Emefele tún ní gbogbo ẹjọ́ ti wón fi kan Godwin Emefele kò lẹsẹ nílẹ̀.
Ki ni adajọ sọ nipa bi DSS ṣe mu Emefiele?

Adájọ́ àgbà Hamza Muazu ti ilé ẹjọ́ tó wà nílùú Abuja , Federal Capital Territory FCT ló pàsẹ yìí lásìkò tó ń se ìgbẹ́jọ́ tó wà láàrin ìjọba àpapọ̀ àti gómìnà àná fún ilé -ìfowópamọ́ tÍ ìjọba àpàpọ̀, ìyẹn ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gba isẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kẹwàá osù kejìlá, ọdún 2023 tí àjọ DSS sì gbé e sí àtìmọ́lé.
Adájọ Muazu ni àjọ DSS ní agbára láti se ojúṣe wọn àti láti dènà ìwà ìbàjé, àmọ́sá wọn gbọ́dọ̀ ṣe ojúse yìí lábẹ́ òfin.
Nítórí náà, àjọ DSS kò kọjá ààyè wọn lati fọwọ́ òfin mú ẹnìkankan, níwọ̀n ìgba tó jẹ́ pé, ó níye ìgbà tí onítọ̀hún leè lò ní àtìmọ́lé.
Godwin Emefiele ló wá gbé ajọ DSS àti ìjọba àpapọ̀ lọ sílé ẹjọ́ látàrí pé wọn tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn rẹ̀ mọ́lẹ̀.
Nínú ẹjọ́ tí agbẹjọ́rò rẹ̀ pé, Joseph Daudu (SAN) rọ ilé -ẹjọ́ pé kí wọ́n dá àjọ DSS lẹ́bi nípa ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé láti mú gómìnà banki apapọ àná Godwin Emefele.
Bákan náà ni ó ní kí ilé-ẹjọ́ pa á lásẹ fún àjọ DSS láti san owó ìtanràn mílíọ̀nù márùn ún naira, 5m fún olúbárà rẹ̀, ìyẹn Godwin Emefele.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Àwọn ẹ̀sùn wo ni ìjọba fi kan Emefiele?
Akọ̀ròyìn wa fi tó wa létí pé àjọ DSS kò gbé Godwin Emefele wá sílè ẹjọ́.
Sibẹ, agbẹjọro ìjọba ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Godwin Emefele jẹ́ àwọn ẹ̀sùn ọ̀daràn.
Lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni wọ́n ní bó ṣe ń ṣe agbódegbà fún àwọn ikọ ọlọtẹ láti máa ṣe ìrànwó owó fún wọn.
Agbẹjọro, Joseph Bodunde Daodu ( SAN) ni agbẹjọro fún Godwin Emefele.O tako gbogbo ohun ti agbẹjọro ijọba sọ to si ni kí wọn fi Godwin Emefele sílẹ̀ nítorí pé gbogbo ẹsùn ìwà ìbàjé ti won fi kan án, irọ́ lásán-làsàn ni.
Ẹwẹ, ilé ẹjọ́ ti ní kí wọ́n gbé Godwin Emefele wá sí ilé ejọ́ pẹlu àwọn ẹ̀rí to fẹsẹ múlẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ kan tábì kí wón fi sílẹ̀.














