NLC lẹ̀tọ́ láti bèèrè àfikún owó oṣù ìdá 300% àmọ́ ewu wà nibẹ̀-onímọ̀ ọrọ̀ ajé

Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Nigeria Labour Congress HQ

Ọrọ awuyewuye to n tẹyin igbesẹ aarẹ lati na ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira gẹgẹ bi Palliative fun araalu tun ti gbọna mii yọ.

Yatọ si pe ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn tapa si owo yi ti wọn si ni ki aarẹ fi owo kun owo oṣu to kere julọ dipo eyi, awọn onimọ eto ọrọ aje naa ti sọ ero wọn.

Ọkan ninu awọn onimọ yi to ba BBC sọrọ ṣalaye pe ẹgbẹ oṣiṣẹ lẹtọ lati beere alekun owo osu ida 300% ṣugbọn ewu wa ninu rẹ.

Bisi Iyaniwura to jẹ agbẹjọro to si tun nimọ nipa eto ọrọ aje ni ijọba ni owo yi lati san gẹgẹ bi awọn oṣiṣẹ ti ṣe beere nitori awọn naa ko fi ọrọ naa lọ araalu ki wọn to fi aduru alekun ti wọn fi le owo bẹntiroo.

''Ko si ohun to buru ninu ibeere wọn. Mo gbagbọ pe ow yi wa ni ikapa ijọba lati san nitori nkan ti araalu n farada lẹyin ti wọn yọ subsidy ko rẹrin rara''

Iyaniwura sọ pe bi eeyan ba n kaakiri lọja to si n ri nkan ti awọn to n tiraka ijẹ imu n foju ri, ko ni sọ pe alekun owo oṣu fun oṣiṣẹ ati awọn mii naa ti ko ba ijọba ṣiṣẹ ko yi ti pọju.

Ekunwo yoo mu ki nkan gbowo lori

Agbẹjọro Iyaniwura sọ pe ti ijọba ba fun awọn oṣiṣẹ ni owo yi, yoo tan iṣoro diẹ ninu inira ti yiyọ subsidy mu wa ṣugbọn ida keji rẹ ni pe nkan yoo wọn lọja.

O ni kii ṣe gbogbo eeyan naa ni oṣiṣẹ ijọba ati pe awọn ti ko ba ri owo yi gba yoo gbe owo lori ọja fawọn to ba jẹ nafaani alekun owo oṣu yi.

''Ọpọ yoo ni owo lọwọ ṣugbọn owo pupọ yoo maa le ja kekere kaakiri ni. Itunmọ eleyi ni pe awọn to n ta ja tabi nkan miran bi owo ile tabi owo ọkọ yoo fi wo le ọja wọn.''

O ni ''Lootọ ni pe awọn araalu nilo idẹkun ṣugbọn owo ti ijọba lawọn fẹ pin ni Palliative ko le kari awọn ọmọ Naijiria to wa ninu ewu iṣẹ ohun oṣi.''

Iyaniwura ṣalaye pe kii ṣe pinpin owo iranwọ nikan lo yẹ ko wa loke aya ijọba bi kii ṣe pe ki wọn pese awọn nkan amayedẹrun ti ko ni jẹ ki araalu nilo lati maa na owo pupọ.

''Ipese ọkọ ti yoo maa gbe awọn eeyan naa lanfaani. Bakan naa lo yẹ ki ijọba wa ọna lati mu adinku ba inakuna ti awọn to wa nipo n na lori ara wọn.''

''Bawo leeyan ti araalu dibo yan yoo ṣe maa na obitibiti owo ti awọn to dibo yan yoo si maa farada inira?Ko bojumu rara''

Di "Palliative" N500bn rẹ mú, àlékún owó oṣù ìdá 300% la fẹ́ - NLC sọ fún Tinubu

Aworan aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @officialABAT

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorileede Naijiria ti tapa si aba Aarẹ Tinubu lati na ẹẹdẹgbẹta biliọnu Naira gẹgẹ bi owo iranwọ ti yoo mu adinku ba inira ti yiyọ ẹkunwo epo mu ba araalu.

Esi yi n waye lẹyin ti aarẹ fi iwe ranṣẹ si ile aṣojuṣofin ni Ọjọru lati gba iyọnda nina owo N500bn gẹgẹ biimayedẹrun faraalu.

Olori ile aṣofin Tajudeen Abass lo ka iwe ti aarẹ fi ranṣẹ ti ijiroro yoo si bẹrẹ lori rẹ ni Ọjọbọ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Naijiria nii Punch ṣalaye pe awọn ko lero pe owo iranwọ yi yoo debi kankan lati mu adinku ba inira taraalu n ri latari yiyọ subsidy lori epo bẹntiroo.

Nigba ti akọroyin ileeṣẹ naa beere lọwọ akapo ẹgbẹ naa Hakeem Ambali boya N500bn yi yoo ran nkan to wa nilẹ, niṣe lo sọ pe ''ko le ran nkankan.Ọmọ Naijiria to le ni 125m lo wa ninu iṣẹ ohun iya bayii.Bawo ni owo yi ṣe le tan tabi mu adinku ba iṣoro ti wọn n koju?''

Alekun owo oṣu 300% ni NLC daba

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu alaye rẹ to ṣe fun ileeṣẹ iroyin Punch, Hakeem Ambali sọ pe awọn fẹki ijọba gbe awọn igbesẹ kan dipo nina owo N500bn to n gbero lati na.

Lara awọn aba ti ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ ni pe ki ijọba mu alekun ida 300% ba owo oṣu awọn oṣiṣẹ gbogbo,ki wọn fun awọn aladani ni iwe aṣẹ lati bẹrẹ si ni da ileeṣẹ ifọpọ alabọde silẹ ki wọn si tun fun awọn olokoowo kekeeke ni owo ẹya ti wọn yoo san pada pẹlu alekun ida 15%.

O fi kun pe ki ijọba mu atunṣe ba awọn ileeṣẹ ifọpo to wa nilẹ ki wọn si pese ẹyawo fawọn agbe ati ọdọ nipasẹ ile ifowopamọ to n ri si ọrọ iṣẹ agbẹ.

Ẹgbẹ yi tun sọ pe awọn fẹ ki ijọba pese eto ti yoo mu ki idokoowo lẹka ina mọnamọna gbe pẹẹli ju ti tẹlẹ lọ ati ṣiṣe eto lilo gaasi dipo epo bẹntiroo fawọn ọlọkọ.

''Ijọba ni lati da ileeṣẹ mọnamọna pada sọwọ ara wọn nitori bi awọn ti wọn ta ileeṣẹ wọnyi fun ti ṣ eda gbogbo nkan ru. Ẹ ri wi pe ẹ ṣeto reluwee ni gbogbo olu ilu ipinlẹ jakejado Naijiria ki ẹ si mu adinku ba owo tawọn akẹkọọ n san lawọn fasiti Naijiria''

Bawo ni Aarẹ ṣe ba ọrọ debi pe Palliative lo fẹ pese

Saaju ni Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti paṣẹ fun igbimọ ijọba to n ri si ọrọ aje wipe ki wọn bẹrẹ igbesẹ lati ṣiṣẹ lori awọn nnkan irọrun faraalu lati lee mu ki idẹrun ba wọn lasiko ti wọn yọ owo iranwọ epo (subsidy) .

Aarẹ tinubu ni ki igbakeji rẹ, Kashim Shettima dari igbimọ naa to si fun wọn ni ọgbọn ọjọ lati gbe igbesẹ naa.

Ababọ ijiroro igbimọ naa la ri ti Aarẹ kọ iwe si ile aṣojuṣofin lati beere iyọnda ko le na N500bn gẹgẹ bi owo iranwọ faraalu.

Ninu iwe ti aarẹ kọ si ile aṣojuṣofin, o ni ''Mo kọ iwe yi lati fi beere ibuwọlu ile lori mimu ayipada ba owo afikun si iṣuna ọdun 2022 to wa nilẹ.''

O ni iyọnda yi ṣe pataki ki awọn baa le yọ N500bn kuro ninu N819,536,937,815 afikun owo isuna to wa nilẹ lati le fi pese owo idẹrun tori subsidy epo ti ijọba yọ kuro.

Ireti wa wi pe ile yoo joko ni Ọjọbọ lati ṣe agbeyẹwo ibeere Aarẹ yi.

Lọdun to kọja loṣu Kejila ni ile aṣofin Naijria buwọlu afikun N819BN si owo iṣuna 2022 ti wọn si fi igbalaye silẹ ki wọn na owo yi titi di ọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu kẹta ọdun 2023.