NECO kéde èsì ìdánwò Common Entrance, akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà gba máákì 1 nínú 100

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook/NECO

Ajọ̀ idanwo Naijiria, NECO ti kede esi idanwọ aṣewọle sile ẹkọ girama (Common Entrance Examination).

Amọṣa, kayefi to ṣe ọpọ̀ lori esi naa ni pe mẹfa ninu akẹkọọ to joko ṣe idanwo naa lo jẹ pe maaki kan pere ni wọn gba ninu gbogbo idanwo naa.

Akọwe agba nileeṣẹ eto ẹkọ nijọba apapọ NAijiria, Andrew Adejo lo fi ọrọ yii to awọn akọroyin leti niluu Abuja.

O ni, " O le lẹgbẹrun mejilelaadọrun akẹkọọ to forukọ silẹ fun idanwo naa, ipinlẹ Eko ni ẹgbẹrun mejidinlogun akẹkọọ; ipinlẹ Taraba lo ni iye akẹkọọ to kere julọ pẹlu mejilelọgọruun.

"Awọn akẹkọọ ọkunrin to ṣe idanwo naa jẹ ẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn, awọn obinrin jẹ ẹgbẹrun mejidinlogoji"

Akọwe agba naa ko ṣalaye lẹkunrẹrẹ lori awọn ipinlẹ ti awọn akẹkọọ naa ti wa.

O ni awọn mẹfa lo gba maaki kan pere ninu idanwo naa jakejado nAijiria.

Bakan naa lo fi kun un pe maaki kan ti wọn gba lo kere julọ ninu idanwo naa.