Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ gan láti di Mínísítà tí Tinubu fẹ́ yàn?

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ahmed Tinubu

    • Author, Yetunde Olugbenga & Mukhtar Adamu Bawa
    • Role, BBC Yoruba & BBC Hausa

Gẹgẹ bi awọn ọmọ Nàìjíríà ṣe n reti akoko naa pato ti aarẹ Bola Ahmed tinubu yoo gbe orukọ awọn minisita ti yoo ba a ṣiṣẹ jade, igboro ori ayelujara ti kun fọfọ fun oniruuru ero.

Bi awọn kan ṣe n gbero pe awọn oloṣelu kan to ṣatilẹyin fun aarẹ Tinubu lasiko eto idibo yoo rọwọ mu lara awọn ti yoo di minisita bo tilẹ jẹ pe inu ẹgbẹ oṣelu miran ni wọn wa yatọ si ti Tinubu.

Bakan naa ni alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Iyiola Omisore tun sọ ninu iroyin kan pe o ṣeeṣe ki aarẹ Tinubu pa awọn ọfiisi kan pọ si ẹyọkan amọ ko sẹni to lee fi aridaju eleyi han.

Ibeere to wa n pọ lọkan awọn eeyan ni wipe kii gan ni ohun amuyẹ ti eeyan kan ni lati ni ko to le di minisita lorilẹede Naijiria.

BBC Yoruba kan si onimọ nipa ọrọ ofin paapaa julọ nipa iwe ofin Naijiria, Agbẹjọro Jiti Ogunye kẹnu bọ ọrọ ilẹ kun to si ni alakalẹ wa ninu ofin nipa iru eeyan to yẹ ki aarẹ fi jẹ minisita.

Ki ni iwe ofin sọ?

“Gẹgẹ bo ṣe wa ninu abala 147 iwe ofin Naijiria, aarẹ orilẹede Naijiria ni alaṣẹ to ga julọ to si ni agbara ofin lati yan awọn minisita”.

Amọ Ogunye tẹsiwaju pe ẹka kan labẹ abala ofin 147 yii kan naa lo tun ka agbara naa lọwọ ko pẹlu awọn ohun amuyẹ to ka silẹ fun ẹni ti yoo le di minisita.

“Abala 147 iwe ofin Naijiria ẹsẹ karun sọ pe: “Wọn ko le yan ẹnikẹni gẹgẹ bii minisita ayafi bi ẹni naa ba koju osuwọn gẹgẹ bi aṣofin paapaa ile igbimọ aṣoju-ṣofin Naijiria.”

Awn nnkan amuyẹ ti ẹni ti yoo jẹ minisita gbọdọ ni?

  • Ẹni naa gbudọ jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.
  • Ẹni naa gbudọ ti to ẹni ọgbọn ọdun.
  • Dede iye sabuke iwe to gbudọ ni ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ gẹgẹ bẹẹ naa ni ti ipo aarẹ.
  • Ẹni naa gbudọ jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan pato, ẹgbẹ oṣelu rẹ si lo gbudọ ṣe onigbọwọ fun un lati di minisita.

Ẹwẹ, agbẹjọro Ogunye mẹnu ba ohun to lee mu ki eeyan ma koju osuwọn lati di minisita. Lara rẹ ni pe:

“Ẹni ti yoo di minisita ko gbudọ jẹ ẹni to n jẹ gbese ni banki, ko gbudọ jẹ ẹni to n ṣe ẹwọn lọwọ (to ba siti ṣẹwọn ri, o gbudọ ti le ni ọdun mẹwaa), ko gbudọ jẹ alaarun ọpọlọ, bẹẹ si ni ko gbudọ jẹ oṣiṣẹ ijọba (ayafi to ba ti fi ipo naa silẹ fun oṣu mẹta ṣaaju akoko iyansipo rẹ).

Bakan naa lo ni ofin pa aarẹ laṣẹ lati yan o kere tan, minisita kan lati ipinlẹ kọọkan wọn si gbudọ jẹ ọmọ̀ ipinlẹ naa gẹgẹ bi ẹsẹ kẹta abala 147 iwe ofin Naijiria ṣe sọ ọ.

Kí ló ń dá Ààrẹ Tinubu dúró lórí yíyan àwọn mínísítà?

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad/twitter

Lẹyin ogoji ọjọ tiBola Ahmed Tinubu gba ipo gẹgẹ bi aarẹ orilẹede to pọ julọ ni Afrika, ijọba adaṣe lo ṣi n gbe dani pẹlu bi ko tii ṣe yan minisita si igbimọ iṣejọba rẹ.

Lọwọ yii ọpọ ọmọ Naijiria lo n ga’run bayii lati mọ iru awọn eeyan ti yoo yan lati baa tukọ iṣakoso iṣejọba rẹ.

Bi ọrọ yii ṣe n pẹ ti di eyi to n mu ki oniruuru ofege iwe orukọ awọn minisita maa farahan lori ayelujara kiri

Osu mẹfa gbako lo gba Muhammadu Buhari to ṣejọba ṣaaju Tinubu, lati yan minisita nigba tirẹ.

Agbẹnusọ fun Aarẹ, Dele Alake ti kigbe sita oe arumọjẹ ni iwe orukọ to n lọ kaakiri naa ati pe, “aarẹ nikan lo lẹtọ ati yan minisita ti yoo ba a ṣiṣẹ́ẹ.”

Ile asofin apapọ wulẹ ti ṣe ayipada si iwe ofin Naijiria nipa sisọ ọ di ọranyan fun aarẹ lati yan awọn ọmọ igbimọ rẹ laarin ọgọta ọjọ to ba de ori oye ki o si fi orukọ wọn ṣọwọ si ile asofin apapọ fun ayẹwo.

Nibayii awọn omo Naijiria ti n sọrọ lori irufẹ amuyẹ ti wọn fẹ lara awọn ti aarẹ yoo ba yan

Lọpọ igba, eto mo moore ni awọn aarẹ naa n fi Yan awọn eeyan kan sipo minisita, yoo si tun wo idurodeede wọn, ẹsin, ẹya pẹlu maa n wa kara amuyẹ ti aarẹ maa n lo

Aarẹ Buhari ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Tinubu/Twitter

Eyi si jẹ ara ohun to n mu ki igbesẹ ati yan minisita o gbẹnu tan nigba mii.

Aarẹ Tinubu ti gbe awọn igbesẹ kan to mu kí ọpọ wo o gẹgẹ bi eyi to ṣeeṣe ko yan awọn ọmọ ẹgbẹ alatako kan sinu igbimọ rẹ gẹgẹ bi igbimọ binukonu.

Bakan naa ni itankalẹ ka gbogbo ipinlẹ mereerindinlogoji to wa ni Naijiria pẹlu jẹ ara ohun ti yoo gbe yẹwo.

Ọjọgbọn kan ninu imọ oṣelu ni fasiti ilu Abuja, Omowe Abubakar Kari ṣalaye ninu ifọrọwọrọ pẹlu BBC pe orukọ ti yoo fa kalẹ ṣeeṣe ko jẹ ọkan lara awọn idanwo akọkọ fun oun ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, iyen APC.

Iyatọ Tinubu at’awọn aarẹ to ti jẹ kọja

Aarẹ Tinubu ati Jonathan

Oríṣun àwòrán, Bola ahmed tinubu

Agbeyẹwo ati akọsilẹ ọpọ onwoye ni pe Aarẹ Olusẹgun Obasanjọ lo yawọ gbe orukọ awọn minisita rẹ jade julọ lara awọn aarẹ to ti n jẹ lorilẹede Naijiria.

Muhammadu Buhari 2015 -2023

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad/twitter

Osu mẹfa gbako lo gba Aarẹ ana Muhammadu Buhari lati to igbimọ iṣejọba rẹ lọdun 2015 to wọle. Amọṣa o yaa diẹ ju eyi lọ nigba ti wọle fun saa keji lọdun 2019 nitori o kan yan opo ninu awọn ti yan fun saa kini pada ni.

ọpọ lo sọ ọ lorukọ inagijẹ “baba go slow” nitori bi ẹmi faagun ṣe maa n ba ọrọ iyannisipo ni abẹ iṣejọba rẹ.

Goodluck Jonathan 2010-2015

Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, goodluck e jonathan

Lẹyin ọgbọn ọjọ ni Jonathan gbe orukọ awọn ọmọ igbimọ iṣejọba rẹ jade lẹyin ti wọn bura fun lọdun 2011.

Umar Musa Yar’adua 2007-2010

Aarẹ Musa YarÁdua

Asiko ti yaradua lo lati yan minisita pọ ju ti asaaju rẹ, Obasanjọ lọ.

Akọsilẹ fihan pe ọjọ mọkandinlọgọta lo gba a lẹyin to de ori oye ki o to yan minisita.

Olusẹgun Obasanjọ 1999-2007

Obasanjo n gba akoso ijọba lọwọ Ọgagun Abdusalam

Oríṣun àwòrán, others

Aarin ọjọ mẹfa lẹyin ti de ipo lọdun 1999 ni Aarẹ Olusẹgun Obasanjọ gbe orukọ awọn minisita jade.

Amọṣa ọjọ mọkandinlogun lo gba a ni saa jeji rẹ.