Iya Gbonkan: Ògbóǹtagì ojú tó ń dẹ́rù ba gbogbo ẹni tó ń wo fíìmù Yorùbá?

Iya Gbonkan

Oríṣun àwòrán, others

    • Author, Yetunde Olugbenga
    • Role, Senior Broadcast Journalist

Ni ọpọlọpọ ọdun sẹ́yìn, ṣe o leè pàdé oju oṣere yii ni ọganjọ oru koo ma bẹru?

Abi ṣe ẹ le pade iya naa ninu mọto tòun ti bi oju rẹ ṣe ri yii kẹ́ẹ ni "mama ṣe mo le baa yin ya "selfie"? O n pa ni lẹrin bẹẹ ṣe n ka a yii amọ loju aye o le ma rẹrin rárá tori ọpọlọpọ ni yoo ti bẹru jina ki wọn to ranti pe oju aye la wa yii kii ṣe inu fiimu.

Ẹwẹ, lẹ́nu ọjọ mẹta yii, ẹ o ti maa ri oju Iya Gbonkan yii nita daadaa paapaa lori ayelujara, eyi si n túmọ̀ si pe aye ti n laju ti ọpọ oṣere si n fẹ́ ki awọn olólùfẹ́ wọn mọ pe eeyan ẹlẹ́ran ara bii tiwọn ni awọn naa n ṣe.

Ki ni ìbẹ̀rẹ̀ Iya Gbonkan?

Kii ṣe Iya Gbonkan ni baba ati iya to bi mama yii sọ ni kékeré, Margaret Mojoyinola Dele Olayinka gaan ni orúkọ oṣere yii amọ awọn eeyan o le gbagbọ ninu fiimu Yoruba pe ẹni ti wọn n kan saara si bi olori gbogbo awọn to le ko ipa ajẹ le maa jẹ Margaret amọ bi iṣẹ awọn onitiata ṣe ri niyi tori o yàtọ̀ si igbe aye wọn gangan loju aye.

Ọjọ kẹrìnlá oṣù Kẹsàn-án ọdun 1958 ni wọn bi Iya Gbonkan to sì jẹ ọmọ ilu Otu ni ijọba ìbílẹ̀ Itesiwaju, Ìpínlẹ̀ Oyo.

Gẹgẹ bi ìròyìn ṣe sọ ọ, Iya Gbonkan kò fi bẹẹ ni iriri igba ewe to dun yiin. Oníṣòwò ni baba rẹ bẹẹ si ni iroyin sọ pe oun nikan ni ọmọ ti iya rẹ bi fun baba rẹ.

Iroyin míì ni oju Iya Gbonkan ri to lọdọ awọn mọ̀lẹ́bí rẹ kan bi wọn ṣe n fiya jẹ ẹ to si mu ko sa kuro nílé amọ iroyin ti yipada lonii toripe Yoruba ni "igba ko lọ bi orere."

Iya Gbonkan

Oríṣun àwòrán, @EmotionsDoctor

Igba wo ni Iya Gbonkan "blow" gẹgẹ bi oṣere "ajẹ"?

Lati kekere gẹgẹ bi ọdọ ni Margaret ti fẹ́ràn lati maa kopa ninu ere torinaa o tẹle ipinu ọkan rẹ o si lọ dara pọ mọ awọn oṣere fiimu Yoruba.

Ó ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹlu kiko ipa kekeke ninu ere, igba to ya ó tun sunmọ kiko ipa ti eeyan lee dá mọ díẹ̀ díẹ̀.

Bó ṣe n baa lọ ree lagbo oṣere to si di ọjọ kan to woye wipe oun le ṣe bii iya to buru gan tabi ajẹ ninu sinima.

Iya Gbonkan ba bẹ̀rẹ̀ si ni ko ipa ribiribi ninu gbogbo fiimu to ba wa latigba naa to si di ki awọn eeyan maa tẹ orúkọ burúkú to ba jẹ ninu sinima mọ ọ lara loju aye.

Iya Gbonkan "blow", o di ilu mọọka daadaa pẹlu ipa to ko ninu fiimu to dá ẹrù ba ni gan kan amọ to jẹ òótọ́ iriri ayé, "Kòtò Ayé" àti "Koto Orun" ti oloogbe Alhaji Ajileye dari rẹ lọdun 2006 ko to jáde laye.

Iya Gbonkan ti ko ipa pupọ ninu oríṣiríṣi fiimu manigbagbe.

Bi oju rẹ ṣe ri lásán ati ara rẹ to jẹ pe ko fi bẹẹ ga, kódà o le ma nilo ki wọn kun nkankan si i loju lati ko ipa ajẹ tabi ṣe bii ẹbọra ninu fiimu.

Iya Gbonkan

Oríṣun àwòrán, NAIJA NEWS

Ninu "Koto Orun", o ko ipa Olori Emere.

Bi ẹ ba rántí, KOLEDOWO bi ọmọ méjọ, awọn iya ajẹ, lábẹ́ idari Iya Gbonkan si pa gbogbo wọn ti wọn yan wọn jẹ bí ẹran asun.

Lára àwọn ti ẹ ko le gbagbe pe ẹ ri pẹlu Iya Gbonkan ninu fiimu ni Olori Abioye, Oyiboyi, Ogunjimi ati Abeni Agbon ti oun ati Iya Gbonkan ṣi jẹ korikosun titi di oni. Gbogbo àwọn agba oṣere yii lee sọ imolẹ di okukun lọsan gangan nínú fíìmù - Abi bẹẹ kọ?

Koda wọn ti jẹ ki awọn eeyan gbagbọ pe eeyan kan ṣoṣo to maa n fi bẹẹ kapa awọn iya aye ni ABIJA, eyiun bi oun naa ba lo agabara kan to ju tiwọn lọ, AJAN, to maa n ri ohun gbogbo ko to sẹlẹ ti yoo si wa ṣe bii foonu to gbọn rìrì lati sọ ofofo fun ÁBÍJÀ WÀRÀ nigba ti ewu ba n sunmọ.

Nibo ni Iya Gbonkan ti ri orúkọ rẹ?

Gẹgẹ bẹẹ ṣe mọ pe odu ni iya yii kii ṣe àìmọ fun oloko ninu ko máa ko ipa ajẹ, o ṣe ajẹ ninu fiimu kan to jẹ ara ọ̀tọ̀ ninu eyi to ti jẹ olori awọn ẹgbẹ́ okunkun to tun wa pa a pọ mọ ipa iya buruku to n fi ẹ̀jẹ̀ awọn ọmọ bibi inu rẹ ṣe omi mu.

Tori ọna ara to gba ko ipa naa daadaa ni wọn ṣe fun un ni "Iya Gbonkan" eyi si ti wa di orúkọ to lẹ mọ ọ lara titi di oni ti ko ṣeé parẹ mọ.

Ẹwẹ, Iya Gbonkan tilẹ̀ ti pariwo sita lẹ́nu ọjọ mẹta yìí pe oun kii ṣe ajẹ amọ a o le sọ bóyá lóòótọ́, awọn eeyan ti gbagbọ abi wọn ṣi n bẹru rẹ.

Lati 1970s ni Iya Gbonkan ti n kopa ninu fiimu to si jẹ pe lara eyi to fi bẹ̀rẹ̀ si ni fara han lori sinima agbelewo Ileeṣẹ tẹlifisan kan, IFA OLOKUN eyi ti Oloye Ifayemi Elebuibon ṣe nigba naa.

Apá kan nínú sinima ọhun ti ko ṣeé gbagbe ni eyi to ti ko ipa Ọ̀RỌ̀ MODI-MODI to jẹ bii Òrìṣà kan to lọ bẹ baba alawo ìlú kan, Orumila wo to si tun jẹ pe oun lo n fi ikilọ ránṣẹ́ si ẹni to fẹ gba a lalejo pe ẹnikẹ́ni ko gbudọ gbe ina atupa lati wa gbe ina wo oju oun ti Orumila naa si sare la ofin silẹ fun iyawo rẹ.

Kódà, ẹnu ọna ni iyawo bàbà alawo naa gbudọ gbé oúnjẹ Iya Gbonkan si ko si yi ẹyin pada.

Ọjọ ti obinrin yii fẹ mọ àṣírí ta lo wa ninu yara ti ọkọ oun ni koun ṣáá máa gbe oúnjẹ si ẹnu ọna, ara rẹ ko ri bakan naa mọ pẹlu ohun bi ara to jade láti ẹnu Iya Gbonkan nigba to si ilẹkun. Ariwo yii le yọ oyun oṣù meje jabọ bo ṣe ta mọ iyawo Orumila bi Agbọn to n binu.

Iya Gbonkan

Oríṣun àwòrán, others

Ṣé ajẹ ni Iya Gbonkan lójú ayé?

Ko si aridaju kankan tó fi idi rẹ múlẹ̀ pe ajẹ ni Iya Gbonkan loju aye.

Agba oṣere yii ti ni ẹ̀bùn ere ṣíṣe àti fifun ipa rẹ ni ìtumọ̀ to dara lati kékeré.

Latari bo ṣe n ko ipa ribiribi ninu fiimu paapaa ipa ajẹ, awọn eeyan saba maa n fi oju rẹ we ti ajẹ to si jẹ pe ọpọ olólùfẹ́ rẹ ọmọdé ati agba tilẹ̀ maa n ni awọn ri i loju ala buruku lẹyin ti wọn ba wo fiimu rẹ tán.

Ipa ajẹ to n ko ko kan sọ ọ di ilumọka nikan, amọ o ti mu ki oun naa ni awọn iriri ti ko dára to si fi ẹnu ara rẹ sọ.

Ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, Iya Gbonkan pa ìtìjú ti to si kígbe sita fun iranlọwọ lati ni ọkọ tìrẹ, Eleduwa ṣe aamin si i ti eleyinju aanu kan si ra ọkọ bọgini fun un.

Lati bíi akoko yii ni Iya Gbonkan naa ti ja sórí ayélujára to bẹrẹ si ni fi onírúurú ọrọ ati fidio síta.

Lára rẹ ni Iya Gbonkan ti ṣe alaye fun awọn olólùfẹ́ rẹ pe oun kii ṣe ajẹ o, ki wọn gbe e kuro lọkan ki wọn si tẹle oju opo oun lori ayelujara lati le maa ri fidio nipa òun.