High Chiefs promote to Kings in Ibadan: Àwọn ọba mọ́kànlá tó gbadé ní Ibadan ní ọ̀rọ̀ òyè náà kó tó láti relé ẹjọ́
Awọn oloye olubadan ti ilẹ Ibadan ti wọn ṣẹṣẹ gba ade tuntun ti fi idunu wọn lede lẹyin ti wọn gba ade ọhun.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, wọn ni ohun to tọ ni igbesẹ naa jẹ, paapaa bi gomina Seyi Makinde ṣe fọwọ si igbesẹ ọhun.
Ti ẹ ko ba gbagbe, awọn awuyewuye kan ti kọkọ waye, eyii to mu ki awọn eeyan kan, ti Kabiesi Olubadan, iyẹn Ọba Lekan Balogun wa lara wọn, lọ sile ẹjọ ṣaaju asiko yii.
- Nítorí ìwọ̀sí tó ń kan àwọn olóyè àgbà ni mo fi gbà pé kí wọn máa dádé- Olubadan
- Ẹni tó bá lọ sílé ẹjọ́ lórí ìlànà ọba jíjẹ nílùú Ibadan ń tan ara rẹ̀ - Makinde
- Ladoja wọ́ Makinde, Olubadan lọ Ilé ẹjọ́ lórí dídé adé fáwọn olóyè Ibadan
- Ta ni "Iya Gbonkan", ògbóǹtagì ojú tó ń dẹ́rù ba gbogbo ẹni tó ń wo fíìmù Yorùbá?
- Ìṣẹ̀ṣe Day- Emir Ilorin àti Wole Soyinka tahùn síra wọn
"Ẹni ti ko ba fẹ jọba, ko joko sile rẹ"
Bo tilẹ jẹ pe iwuye awọn ori ade naa lọ wọrọwọ, awọn oloye kan bii gomina tẹlẹ, Rashidi Ladoja ko fọwọ si.
Lara awọn ori ade tuntun naa to ba BBC Yoruba sọrọ, Ọba Adebayo Akande, to jẹ ẹkarun un Olubadan sọ pe ọrọ naa ko le to ki awọn kan maa binu tabi gba ile ẹjọ lọ.
O ni "Ẹni ti ko ba fẹ jọba, ko joko sile rẹ, a ko ni fi tipatipa ni ki eeyan jọba."
"Mọkanmọkan loye Ibadan, igbesẹ kan si omiran ni oye Ibadan, a kii ja soye Ibadan, a ko mọ ọjọ ti yoo kan ẹnikọọkan."
Nigba ti ẹkẹrin Olubadan, Ọba Hamidu Ajibade n sọrọ, o ni ohun to dara bi wọn ṣe fun wọn ni ade.
O ni "Oye lọbalọba ti a gba yii... ibikibi ti a ba lọ ki wọn ma maa pe wa ni ọmọ iranṣẹ nibẹ mọ."
Gẹgẹ bii ohunn to sọ, ẹgbin maa n ba awọn lawọn ipade to ṣe pataki ti wọn ba lọ tẹlẹ nitori wọn ko ni ade lori.
O fi kun pe lara iṣẹ awọn ni lati maa da seria fun awọn kọlọrọsi to n ta ilẹ ni itakuta nigboro Ibadan.
- Àwọn èèyàn bú mi pé mi ò kàwé mo dẹ̀ fẹ́ ṣe gómìnà ló jẹ́ kí ń kàwé yọrí – Adeleke
- Ìlú yóò le, ọmọ le kú, àìsàn yóò pọ̀ bí eégún kò bá jáde nílùú Ibadan - Olóòlù
- A ó ṣiṣẹ́ láti ripé àwọn lọ́balọ́ba ní àṣẹ́ lábẹ́ òfin Naijiria- Abenugan Ilé Aṣòfin
- Àṣìta ìbọn NDLEA pa ọmọ ọdún méjì, mọ̀lẹ́bí bẹ̀bẹ̀ fún ìdájọ́ òdodo
- Ẹ̀sùn gbígbé ìbọn láì gbàṣẹ tí DSS fí kan Emefiele, ohun tí òfin sọ nípa rẹ̀ réè
Emi kọ ni mo fun awọn oloye ni ade, Olubadan lo fun wọn - Makinde
Ẹwẹ, gomina Seyi Makinde ti sọ pe oun kọ loun fun awọn oloye naa ni ade.
O ni "Awọn eeyan n sọ pe gomina ipinlẹ Oyo fẹ gbe ade fun awọn agba oye ti wọn sọ di ọba."
"Kabiesi Olubadan ti ilẹ Ibadan, awọn ni wọn gbe ade fun awọn oloye wọn, ti wọn sọ wọn di ọba."
"Ti awọn ori ade wa ba fọwọsi pe awọn n fẹ atunto laarin ara wọn, emi gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo maa ṣe atilẹyin fun wọn."
"Awọn ti wọn ba lọ sile ẹjọ kan n fi akoko ara wọn ṣofo ni, nitori pe ohun ti gbogbo awọn oloye Ibadan ati ọmọ bibi Ibadan n fẹ ka ṣe, ati ṣe fun wọn."