Ẹ̀sùn gbígbé ìbọn láì gbàṣẹ tí DSS fí kan Emefiele, ohun tí òfin sọ nípa rẹ̀ réè

Aworan Gomina CBN tẹlẹ Godwin Emefiele ati oṣiṣẹ DSS to gbe ibọn lọwọ

Ko jẹ iroyin tuntun mọ pe ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS n ba Gomina tẹlẹ ni banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele fa wahala lẹyin to kuro lori ipo.

Laipẹ yi ni ile ẹjọ sọ pe ki wọn tu Emefiele silẹ ko maa lọ lalaafia bi wọn ko ba ri ẹsun kankan fi kan an.

Ni idahun si aṣẹ ileẹjọ, DSS ti wa gbe Emefiele lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe o ni ibọn lọwọ lai gbaṣẹ lọwọ awọn alaṣẹ ki o to ṣe bẹẹ.

Ninu iwe ipẹjọ ti o tẹ BBC lọwọ lati ri ẹsun ti wọn fi kan an yi ti wọn si ni ohun to ṣe tapa si ofin orileede Naijiria.

Ẹsun onigun meji ni a ri ninu iwe ipẹjọ yi ti alakọkọ si da lori pe o ni ibọn jagamu ti ko gba aṣẹ, fun ti eleyi si tako abala kẹrin ofin lilo nkan ija oloro ti wọn gbe kalẹ ọdun 2004.

Ẹlẹkeeji igun ẹsun yi nipe o ni ọta ibọn mẹtalelọgọfa ti ko ni aṣẹ lati ni lọwọ.

Emefiele

Oríṣun àwòrán, @General_Oluchi

Ohun ti ofin sọ nipa ẹni to ni ibọn lọwọ lai gbaṣẹ

Ni Naijiria ofin de rira tita tabi lilo nkan ija oloro gẹgẹ bo ṣe wa lawọn orileede mii.

Ofin to de ẹsun ti wọn fi kan Emefiele yi wa ninu ofin ti wọn pe orukọ rẹ ni 'Firearms Act of 2004.'

Ninu ofin yi, ijọba apapọ sọ pe Emefiele tapa si abala kẹrin ofin Firearms Act, Cap. F28, ti ijiya si wa fun ẹṣẹ yi labẹ abala kẹtadinlọgbọn(1)b(i) ofin yi kan naa.

Bẹẹ naa ni wọn lo ko ọta ibọn sọwọ lai gba aṣẹ.Ijiya eleyi naa wa labẹ abala ofin yi taa ka siwaju.

Abala ofin yi sọ nipa nini ibọn ti araẹni pe ''Ko si ẹnikankan ti yoo ni ibọn ni isọri taa ka silẹ labẹ ofin yi ayafi to ba gba iwe iyọnda, 'licence' ti o ṣe pe ọga agba ọlọpaa lo le yọnda eyi fun tabi ko kọ fifun ni iyọnda yi pẹlu aṣẹ Aarẹ orileede''

Ni abala kẹtadinlọgbọn ofin yi to mẹnu ba ijiya to wa fẹni ba tapa si ofin yi, o ni ''ẹwọn ọdun marun un ni ijiya fẹni to ba tapa si abala kẹrin ati ikẹjọ ofin yi''

Emefiele, lilọ rọọkun nile rẹ ati awuyewuye Naira tuntun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Atẹjade to wa lati ọfisi akọwe agba fun ijọba apapọ sọ pe aṣẹ lọ rọọ́kun nile ti wọn fun Emefiele waye nitori iwadii ọfisi Emefiele ati awọn eto to fẹ gbe kalẹ fatunto ẹka ọrọ aje Naijriia.

Wahala ti Emefiele n koju ti bẹrẹ lati igba to kede ilana iyipada owo Naira ṣaaju ki idibo ọdun 2023 to waye.

Igbesẹ yi mu ọpọ inira ba araalu ti eto ọrọ aje si dẹnukọlẹ latari rẹ.

Awijare ti Emefiele sọ nigba naa ni pe ida ọgọrin owo tawọn tẹ ni ko si lakoto banki ti eyi si tunmọ si pe owo to wa nita pọ ju iye to wa ni banki lọ.

O ni ipenija yi lo mu kawọn ni kawọn araalu ko owo wa si banki ki wọn si tẹ omiran jade.

Igbesẹ yi bu lọwọ to si jasi pe awọn eeyan ko ri owo gba jade ni banki tabi lẹnu ẹrọ to n pọ owo jade, iyẹn ATM.

Gbogbo inira ti eleyi ko ba araalu wa lara nkan tawọn eeyan fi dunnu nigba ti wọn gbọ pe Aarẹ tuntun Bola Tinubu paṣẹ ki o lọ rọọkun nile.

Lati igba ti aṣẹ yi ti jade si ni o ti n koju wahala kan tabi omiran ni paapa lati ọdọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS to fi igba kan fi si ahamọ ki ile ẹjọ to wa sọ pe ki wọn pe lẹjọ bi bẹẹ kọ ki wọn tui silẹ ko maa lọ lalaafia.