A ti mú Emefiele, ó sì ti wà lákàtà wa – DSS

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ Nigeria, DSS, ti fi ṣikun ofin mu gomina CBN, Godwin Emfiele, o si ti wa ni ahamọ wọn.
DSS lo fidi iroyin naa mulẹ loju opo Twittre rẹ lọjọ Abamẹta.
Ti ẹ ko ba gbagbe, DSS ti kọkọ sọ pe Emefele ko si lakata oun, eyii to mu ki ọpọ araalu maa bere pe nibo lo wa.
Amọ awọn eeyan kan to sunmọ gomina CBN tẹlẹ naa ni DSS ti fi ṣikun ofin mu, o si ti wa ni ahamọ wọn to wa niluu Eko.
Wayi o, DSS ti wa kede pe nitootọ awọn ti mu ọkunrin ọhun
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Atẹjade keji ti DSS fi lede yii sọ pe “A fẹ fidi rẹ mulẹ bayii pe Ọgbẹni Godwin Emefiele ti wọn ni ko lọ rọkun nile ti wa lakata wa fun awọn iwadii kan.”
Godwin Emefiele kò sí ní àhámọ́ wa – DSS

Oríṣun àwòrán, Social Media
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti ni gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ, Godwin Emefiele ko si ni ahamọ awọn.
DSS lo fi ọrọ naa lede loju opo Twitter tẹ lọjọ Abamẹta, eyii ti agbẹnusọ rẹ, Peter Afunnaya buwọlu.
Atẹjade naa ni “Lọwọ yii, Emefiele ko si ni akata DSS.”
Eyi ko ṣẹyin iroyin to n ja ranyin pe ikọ ọtẹlẹmuyẹ naa ti fi Emefiele si ahamọ lẹyin ti Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu yọ ni ipo.

Oríṣun àwòrán, DSS
Eyi kii ṣẹ igba akọkọ ti iroyin yoo jade pe ajọ DSS fẹ mu Emefiele, awuyewuye naa bẹrẹ lati igba to ti ṣe atunṣe owo naira, eyi to fa hilahilo fun ọpọ eniyan ni Naijiria.
Ẹwẹ, ibeere ti ọpọ ọmọ Naijiria n bere bayii ni pe “nibo ni emefiele wa?”
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Ẹti ni agbẹnusọ akọwe ijọba Naijiria, Willie Bassey kede aṣẹ Aarẹ pe ki Emefiele maa lọ sile na.
Atẹjade Bassey sọ pe “Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti pasẹ ki gomina CBN, Godwin emefiele lọ rọkun nile lẹsẹkẹsẹ.”
“Aṣẹ yii ko ṣẹyin iwadii kan to n lọwọ ni ọọfisi rẹ lori atunṣe eto ọrọ aje Naijria.”
“Wọn ti ni ki ọgbẹni Emefiele tare gbogbo iṣẹ to wa lọwọ rẹ si akata Folashodun Adebisi Shonubi, ti yoo maa dele de e titi ti iwadii ẹsun ti wọn fi kan an yoo fi pari.”
Ohun tí àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ rèé lẹ́yìn tí Aàrẹ Tinubu pàṣẹ kí Emefiele lọ rọọ́kún nílé

Oríṣun àwòrán, Others
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo ti gboriyin fun aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori bi o ṣe yọ Gomina Banki apapọ Niajiria, Godwin Emefiele nipo bẹẹ si ni awọn mii n fi ero wọn han.
Aṣẹ aarẹ Tinubu farahan ninu atẹjade kan ti ọfiisi akọwe ijọba apapọ Naijiria fi sita lalẹ ọjọ Ẹti.
Atẹjade naa tẹsiwaju lati ṣalaye wi pe, aarẹ gbe igbesẹ naa nitori iwadi to n lọ lọwọ lori ọfiisi gomina banki apapọ naa ati awọn atunto to fẹ waye lori ẹka iṣuna lorilẹede Naijiria.
Ni idahun awọn araalu si igbesẹ aarẹ yii, ni ọpọ fi idunnu wọn han ti wọn si ni o yẹ ki igbeṣẹ yii ti waye ni kiakia ko to di asiko yii.
‘’Ọpẹ o! Emefiele ti lọ!’’
Loju ọpọ Facebook BBC News Yoruba, ọpọlọpọ awọn to sọrọ ni wọn fi idunnu wọn han si igbesẹ aarẹ naa, ti wọn si ni o dun mọ awọn ninu.
Awọn miran to sọrọ ni igbeṣẹ Emefiele lati ṣe atunṣe owo Naira fi iya jẹ awọn araalu ti ọpọ si sọ ẹmi rẹ nu lasiko ọwọngogo owo Naira naa.

Oríṣun àwòrán, Screengrab

Oríṣun àwòrán, Others
Loju ọpọ Twitter awọn miran to sọ ero wọn ni igbesẹ to dara ni aarẹ Tinubu gbe, eleyii ti yoo yi igbe aye awọn eniyan pada.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Amọ ninu ọrọ tirẹ, Reno Omokri ni ki ijọbs Tinubu ma ti Godwin Emefiele mọ le lati gbẹsan lara rẹ, o ni eyi yoo jasi ohun ti ijọba Buhari se ni ọdun 2015, to n fi panpẹ ọba gbe awọn to ba Jonathan ṣiṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ààrẹ Bola Tinubu yọ ṣọ́ọ̀kì lẹ́sẹ̀ Gómìnà Báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele, Ó ní kó lọ rọọ́kún nílé

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu ti paṣẹ fun Gomina banki apapọ Naijiria (CBN), Godwin Emefiele pe ko lọ rọọkun nile naa.
Aṣẹ aarẹ Tinubu farahan ninu atẹjade kan ti ọfiisi akọwe ijọba apapọ Naijiria fi sita lalẹ ọjọ Ẹti.
Atẹjade naa tẹsiwaju lati ṣalaye wi pe, aarẹ gbe igbesẹ naa lati nitori iwadi to n lọ lọwọ lori ọfisi gomina banki apapọ naa ati awọn atunto to fẹ waye lori ẹkan iṣuna lorilẹede Naijiria.
“Aarẹ Bọla Tinubu ti paṣẹ fun gomina Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele CFR pe ko lọ rọọkun nile lẹyẹ o ṣọka.
“Eyi n waye nitori iwadii to n lọ lowo lori ọfiisi rẹ ati atunto ẹka iṣuna ti ijọba n gbero lati ṣe.”












