Ṣé ẹ lè ló páàdì aláṣọ tí arábìnrin yìí ń rán láti ran àwọn obìnrin tí kò lówó páàdì òyìnbó?
Ṣé ẹ lè ló páàdì aláṣọ tí arábìnrin yìí ń rán láti ran àwọn obìnrin tí kò lówó páàdì òyìnbó?
Ọpọlọpọ obinrin ati ọdọbinrin nilẹ Afirika ni o ku diẹ kaato fun lati maa ri owo fi ra awọn nnkan to wa fun itọju oju abẹ wọn.
Eyi lo mu ki oniṣẹ ọwọ yii to tun jẹ ajafẹtọ, Elsa M’bena Ba gbe igbesẹ akin lati maa lo awọn aṣọ to si n ge wọn lati ran an ko le yipada si paadi alaṣọ eyi ti awọn obinrin le maa lo lasiko ti wọn ba n ṣe nnkan oṣu, wọn si tun le tun awọn paadi alaṣọ naa lo lọpọ igba.

“Lati ọdun 2020, a ti ta paadi alaṣọ to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọta. Lilo ati atunlo paadi n daabo bo aika wa lai fi ogunlọgọ paadi da panti ti ko ṣe ara loore silẹ”.
Elsa jẹ ajafẹtọ obinrin to si ti n ṣe eto iranwọ yii fun awọn obinrin ni adugbo rẹ fun ọdun pipẹ.





