Ẹ bá mi rọ Ọba Ghandi kó má tún ìtàn Ògbórí Ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ yà- Ẹda Onile Ola

Àkọlé fídíò, Ogbori Elemoso
Ẹ bá mi rọ Ọba Ghandi kó má tún ìtàn Ògbórí Ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ yà- Ẹda Onile Ola

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awuyewuye kan gbilẹ lori ayelujara, lori itan ilu Ogbomoso ti agba oṣere nni, Lere Paimo tawọn eeyan mọ si Eda Onile Ola, ya lọdun 1990.

Soun ilu Ogbomoso, Oba Olaoye Ghandi, ni Eda Onile Ola fesun kan, pe oun ati ileeṣẹ kan fẹ tun iṣẹ naa ya, eyi ti oun tako, nitori ko si bi atunya ko ṣe ni i ṣe awọn ayipada kan si itan naa.

Alagba Lere Paimo sọ pe:

" Emi ti mọ pe ti wọn ba ni lati tun un ya, wọn maa yọ awọn nnkan kan kuro, ti ko si ni ba bi itan ṣe lọ mu mọ. Itan ibilẹ ni, ko ṣee yi pada.

"A ya a ni odun 1990, a sọ ọ di fiimu. Ko too di igba yẹn ni mo ti n ṣe e ni tẹlifiṣan ati lori itage kaakiri agbaye, ki n too sọ ọ di fiimu.

"Ki i wa ṣe pe nisinyi ni ẹnikan maa ni awọn fẹẹ yi i pada.

"Milionu meje aabọ ni wọn fi ranṣẹ si mi, awọn ọmọ si ni iya owo kọ lo n jẹ mi, ni mo fi da a pada fun wọn.

"Ẹ ba mi rọ Kabiyesi Ọba Ghandi o, ki wọn ma tun Ogbori Ẹlẹmọṣọ ya o."

Alagba Lere Paimo ni bi wọn ba fẹe ya itan Ogbomoso, o kunlẹ, dandan kọ ni ko jẹ Ogbori Elemọṣọ.

Ati pe ohunkohun ti wọn ba ya, ki wọn ma pe e ni Ogbori Ẹlẹmọṣọ.

Ṣugbọn Oludamọran fun Ọba Ghandi, Peter Olaleye, ninu ọrọ tirẹ, sọ pe :

"Itan Ogbori Ẹlẹmọṣo, itan ilu Ogbomoso ni, o yatọ ninu gbogbo itan ti awon eeyan maa n ṣe, nitori otitọ ni, ki i ṣe agbelẹrọ.

"Itan bi Soun Ogunlola ṣe gba awọn ara Oyo lowo Ẹlẹmọsọ, to pada di ọba ti orukọ rẹ ko tan ninu itan ogbomoso. Itan naa ki i ṣe eyi ti ẹnikan le sọ pe ti oun ni. "

Bakan naa ni Amofin Orioye Oluwasanmi, ṣalaye ohun ti ofin sọ lori atunya iṣẹ naa. O ni bo ti wu ki iṣẹ naa jẹ ti ibilẹ to, ẹnikẹni kọ lo le ya a.

Ati pe awọn eeyan Ọba Ghandi tilẹ tun ṣe akọsilẹ funra wọn fun agba oṣere naa.

O ni o kọni lominu bi wọn ko ṣe fẹ gba aṣẹ.