Bí Iya Gbonkan ṣe kẹnu bọ àyájọ́ èdè Yorùbá láti fi ìdùnú hàn lorí ẹ̀bùn ọkọ̀ bọ̀gìnì tó gbà rèé

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gbajugbaja agba oṣere fiimu Yoruba, Tobola Olayinka ti ọpọlọpọ mọ si Iya Gbonkan ti ri amuṣẹ ero ọkan rẹ o - Ọkọ bọgini ti wa lagbala Iya Gbonkan bayii lẹyin to bẹbẹ fun iranwọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe laipẹ yii ni Iya Gbonkan fi ipe sita lati tọrọ iranwọ lọdọ awọn ẹlẹyinju aanu ni Naijiria lati boju aanu wo o ki wọn ra ọkọ to le maa fi ṣe ẹṣẹ rin.

Iya Gbonkan ni oun ko fẹ maa gun ọkada alupupu tabi ta mọ mọto lati lọ si ibi to ba ti fẹ kopa ninu sinima eyi to ni o ti su oun.

Ẹni to fi ọkọ naa ta agba oṣere yii lọrẹ, Arabinrin Omobolanle Olatise ni idi ti oun fi ṣe eyi ni pe tori oun fẹ ṣe moriya fun Iya Gbonkan ni gẹgẹ bi akinkanju oṣere tiata.

'Ohun Iyalẹnu lo jẹ fun Iya Gbonkan'

Iroyin ni kete ti awọn ti alaanu naa ran pe ki wọn lọ wa ọkọ to dara fun Iya Gbonkan ri ọkọ naa, laarin iṣẹju ọgbọn ni o san owo ọkọ ọhun.

“O jẹ iyalẹnu fun Iya Gbonkan tori pe wọn o tilẹ mọ pe a fẹ gbe ẹbun ọkọ fun wọn nibi ni ilu Ibadan, nitori naa, inu wọn dun gidi gan nigba ti wọn ri ọkọ naa.”

Kete ti Iya Gbonkan foju kan ọkọ naa ni oun ati akẹgbẹ rẹ oṣerebinrin mii, Alirat Adunni ti ọpọ mọ si “Tamotiye” ki orin bọ ẹnu ati adura ti wọn si n yọ ṣẹṣẹ tori wọn ko le pa idunu wọn mọra mọ.

“Emi gangan loriire kan! Alaanu mi ẹ ṣe o, ẹ o ni ku lailai, ẹ o ni ṣubu ẹmi, ẹ o ni ṣubu ara. Lagbara Ọlọrun, ore yoo maa gori ore fẹyin naa ni tọmọ tọmọ.”

Ẹẹ ni rarin ra, ẹ o ni rare lailai, o ti n daa ko daa mọ ko ni jẹ tiyin, bata ọfọ, bata ibanujẹ wọn o ni da a sile yin lagbara Ọlọrun...”

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ki lo selẹ tẹlẹ?

Ṣaaju akoko yii ni iroyin kan naa ti jade wipe Iya Gbonkan ti gba ẹbun owo nla lati fi pari ile rẹ to n kọ lọwọ amọ ti ko tii kọ pari.

Ni nnkan bii ọsẹ diẹ sẹyin ni agba oṣere naa bọ si ori ayelujara to si rawọ ẹbẹ si gbogbo eniyan lati ran an lọwọ lati pari ile rẹ to n kọ ati ko ri ọkọ fi ṣe ẹsẹ rin.

Ninu fidio ọhub to n lọ kaakiri lori ayelujara ni agba oṣere yii ti rawọ ẹbẹ yii.

Iya Gbonkan ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun pe o ṣeeṣe ki awọn ti ko ran oun lọwọ nigba ti oun wa laye lee jade maa fi maluu ranṣẹ fun ayẹyẹ isinku oun nigba ti oun ba papoda tan.