Ohun márùn-ún rèé nípa lílo afẹ́fẹ́ gáàsì CNG fún ọkọ̀ rẹ̀ dípò bẹntiróò

Aworan awọn to n ta gaasi sinu ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igba ọtun ni lilo bẹntiroo lasiko yi jẹ fun ọpọ awakọ ati awọn araalu ni Naijiria.

Ko si ṣẹyin ikede aarẹ tuntun pe ẹkunwo lori epo bẹntiroo taa mọ si subsidy ti di ohun igbagbe ni Naijiria.

Lati igba ti ikede yi ti dori afẹfẹ ti alekun si ti ba iye owo bẹntiroo lawọn araalu ti n wo oriṣi ọna lati mu idẹkun ba lilọ bibọ ati awọn nkan mii ti wọn n fi bẹntiroo ṣe.

Nibi ti awa naa ti n fimu finlẹ lati ri iroyin nipa afẹfẹ gaasi taa mọ si Compressed Natural Gas, CNG, tawọn eeyan n lo fun ọkọ ayọkẹlẹ dipo bẹntiroo.

Eyi to daju ni pe imọ lilo gaasi yi wa nita ṣugbọn ki ni ẹyin mọ nipa rẹ ati pe ṣe o le mu idẹkun ba apo awakọ toba fẹ fi rọpo epo bẹntiroo lasiko taa wa yi?

A o gbiyanju lati mu alaye rẹ wa ninu apilẹkọ yii.

Iru gaasi wo ni CNG taa n wi yi jẹ?

Aworan awọn ọkọ to n lo gaasi CNG

Oríṣun àwòrán, InnosonVehicles

Gaasi taa n pe ni CNG yii wa latara gaasi taa n ri gẹgẹ bi alumọni ni.

Ni eyi to jẹ apeejuwe ti yoo ye wa, gaasi yi jẹ eleyi ti wọn ṣakojọpọ rẹ lọna ti yoo ṣe lo lati fi pese ina,ṣe iranwọ fun ọkọ taa n lo tabi ki a si fi mu ile tutu gboina tabi tutu nipa ẹrọ amuletutu wa ''air conditioner.''

Amọ eleyi tawọn eeyan mọ CNG fun ni lilo gaasi yii lati fi rọpo bẹntiroo tabi disuu ninu awọn ọkọ wa.

Jakejado agbaye o sunmọ miliọnu mẹtalelogun ọkọ ti wọn lo gaasi CNG yii fun loun nikan tabi nipa lilo gaasi yi pẹlu bẹntiroo papọ ninu ọkọ wa.

Bi eeyan ba ni to jala lita gaasi mẹfa tabi meje,o le fi ọkọ naa rin irinajo ọgọrun kilomita.

Irin yi bi eeyan ba lo bẹntiroo, yoo lo jala epo lita mẹwaa.

Lagbaye awọn ilu kan n ṣe amulo ọkọ yi ju ara wọn lọ.

Ni Latin America ati India, wọn gba ti ọkọ yii daada ju awọn to wa ni Yuroopu lọ.

Nilẹ adulawọ wa nibi yi, imọ nipa awọn ọkọ yii ko ti pọ daada.

Ni Naijiria, nkan ajoji lo jẹ ṣugbọn o ṣeeṣe ki o di atẹwọgba pẹlu bi bẹntiroo ti ṣe gbowo lori yi.

Ṣe ijọba fọwọ sii tabi ko fọwọ sii ni Naijiria?

Idahun si ibeere yii ko mu aroye pupọ wa.

Bi ẹ ba fi ọkan ba ipade ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba lori ẹkunwo owo epo ti ijọba yọ to fẹ mu ki ẹgbẹ oṣiṣẹ gunle iyanṣẹlodi, ẹ o ri pe ọrọ to nii ṣe nipa lilo ọkọ CNG wa ninu adehun ti wọn fẹnu ko si.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn fẹ ki ijọba ṣe agbende awọn aaye ikọṣẹ nipa yiyi ọkọ to n lo bẹntiroo pada si eleyi to n lo gaasi.

Eyi tunmọ si pe ijọba mọ riri iru awọn ọkọ yii wọn o si tako lilo rẹ lawujọ.

Lati kin ọrọ wa lẹhin, ileeṣẹ to n pese ọkọ labẹle iyẹn Inosson Motors ṣe ifilọlẹ awọn ọkọ ati bọọsi eyi to ṣe pe gaasi CNG yi ni wọn n lo.

Ileeṣẹ naa ni ọkọ tawọn gbe sita yoo mu idẹkun ba araalu paapa lasiko yii ti owo bẹntiroo lọ soke.

Aworan ọkọ kekere ati bọọsi Innoson to n ṣamulo CNG

Oríṣun àwòrán, InnosonVehicles

Lilo gaasi, disu tabi bẹntiroo ewo ni ko gunpa?

Aworan ayẹyẹ ibuwọle adehun tiijọba Naijiria ati Morocco ṣe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Cornel Osigwe to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ IVM sọ pe anfaani kan ti lilo ọkọ gaasi CNG ni lori awọn eyi to n lo bẹntiroo tabi disuu ni pe gaasi yi kii yara jo tan.

O ni ''gaasi kii ko ipalara ba ayika wa bi ti bẹntiroo. Ọkọ bẹntiroo mọ awọn ọmọ Naijiria lara lootọ ṣugbọn pẹlu bi a ṣe ni gaasi lọpọ yanturu iru ọkọ CNG yi yoo ṣe anfaani faraalu''

Gẹgẹ bi iwadii kan ti Price Water Cooper,PWC, gbe jade, Naijiria ni orileede ikẹsan to ni alumọni gaasi julọ lagbaye.

O ni Naijiria ni to 209.5 trillion cubic feet gaasi ti wọn ko si ribi ṣamulo ọpọ rẹ.

Lati le mọ bi gaasi Naijiria ṣe pọ to, Orileede Morocco lọdun 2022 buwọlu adehun kan lati ṣafikun ipese oju opo kun eleyi to wa nilẹ ti yoo gbe gaasi lati Naijiria lọ si orileede wọn.

Oju opo yi yoo ni ikapa lati gbe gaasi 30 billion cubic m/lọdun kan ti yoo si bẹrẹ lati Eko gba Cotonou Lome, Togo,Takoradi ni Ghana Abidjan ni Cote d''voire gba awọn orileede mii titi ti yoo fi kangun si Morocco.

Igbagbọ ni pe yoo ti ati ibẹ lọ si Yuroopu lati Spain.

US$25 billion ni wọn yoo fi pese oju opo yi ti wọn si lero pe yoo bẹrẹ lọdun 2046.

Aworan oṣiṣẹ ile opo to n ta gaasi CNG sinu ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lorileede India lilo gaasi CNG jẹ nkan ti o gbode laarin awakọ

Yiyi ọkọ rẹ pada si eyi to n lo CNG

A ti yi ọkọ pada lati eleyi to n lo epo bẹntiroo si gaasi CNG tabi LNG kii ṣe nkan to le .

Imọ nipa rẹ kan le ma ti kari bi ti yiyi ọkọ to n lo ọwọ ọtun si apa osi ni Naijiria, amọ awọn to n ṣe wa ni Naijiria.

Ileeṣẹ Innoson taa darukọ ṣaaju wa lara awọn to le ba eeyan yi ọkọ pada si ko maa lo gaasi dipo bẹntiroo.

Ileeṣẹ naa loju opo wọn ni awọnm si tun le ba araalu ṣe aaye ninu ọkọ rẹ ti yoo maa lo gaasi ati bẹntiroo papọ.

Eleyi yoo da bi awọn ọkọ ti wọn n pe ni Hybrid to n ṣe amulo oriṣi ọna lati jẹ ki ọkọ le rin lati ibi kan si omiran.

Pataki julọ awọn onimọ sọ pe bi eeyan ba fẹ ṣe ayipada tabi afikun yi, ko rii wi pe ọkọ rẹ jẹ eleyi ti yoo le gba iru ayipada yi.

Bakan naa ni wọn mu amọran wa wi pe ki eeyan ro daada boya yoo maa ri gaasi deede to ba yi ọkọ naa kuro lati bẹntiroo si gaasi ko ma di pe ati ri gaasi ra yoo di iṣoro.

Ni ti tiẹ, ijọba orileede Naijiria ti ṣe ipinu lati mu alekun ba iye ọkọ ti yoo ma lo gaasi gẹgẹ bi ọkan lara eto mimu ayedẹrun lẹyin ti wọn ba yọ subsidy epo.

Nigba to n ṣe alaye ọrọ yi nigba naa lọhun, Minisita keji fọrọ alumọni epo Timipre Sylvia ṣalaye pe ijọba gbero lati yi nkan bi miliọnu marun ọkọ si eyi to n lo gaasi nigba ti wọn yoo fi pari eto naa.

Oṣu mẹrindinlogoji,36, ni wọn la kalẹ pe ijọba yoo fi ba awọn to n pese irinṣẹ,Original Equipment Manufacturers (OEM) ati awọn oniṣowo epo ati gaasi,ṣiṣẹ ti wọn yoo fi sọ ọkọ miliọnu kan di eyi to n lo gaasi.

Bẹẹ lo ni awọn yoo pese aaye ti wọn yoo ti maa ta gaasi si ọkọ ẹgbẹrun kan.

Njẹ ewu kankan wa nibi lilo ọkọ oni gaasi CNG?

Aworan ọkọ to n lo gaasi ti Innoson ṣe agbekalẹ

Ọkọ lilo yala eyi to n lo gaasi tabi epo bẹntiroo lo lewu.

Lọpọ igba, ewu yi gẹgẹ bi awọn onimọ ti ṣe sọ, ko ṣẹ lẹyin pe awọn eeyan to n lo ọkọ kii fẹ tẹle imọran ti awọn to ṣe ọkọ naa la kalẹ.

Ọkọ oni gaasi CNG yi le jẹ eleyi ti wọn ṣe wa lati ileeṣẹ ọlọkọ tabi ko si jẹ pe wọn yi pada si lilo gaasi tabi ko ṣi ṣe pe o n lo gaasi ati epo bẹntiroo pọ.

Bo ba jẹ elleyi ti wọn ṣe wa pẹlu ile epo gaasi ati irinṣẹ rẹ, ọrọ buṣe.

Ẹnu ki awakọ maa tẹle gbogbo imọran ko si ri pe oun n ra gaasi nibi ti wọn ti n ta eleyi ti ọkọ rẹ n lo.

Gboogbo atunṣe to ku o ku si ọwọ ẹni to n lo irufẹ ọkọ naa.

Amọ bo ba ṣe pe onitọhun yi ọkọ elepo pada si gaasi ni, o ni lati ri wi pe ọkọ naa jẹ eleyi ti yoo gba iyipada bẹẹ loun lo.

Awọn eeyan a maa ra nkan eelo iyipada ọkọ taa mọ si Conversion Kit.

Bi o ba fẹ ra nkan eelo yi, ri wi pe eleyi ti yoo ṣiṣẹ pẹlu ọkọ rẹ lo ra.

Ti ko ba ri bẹẹ, wahala bẹrẹ ni yẹn

.

Bakan naa ni wọn gba lamọran pe kieeyan gbe ọkọ naa lọ ba awọn akọṣẹmọṣẹ ti yoo le ṣe iyipada yi lai si wahala kankan.

Ninu nkan mi to yẹ ni mimọ ni pe aaye ikẹru si ko ni pọ mọ ninu ọkọ ti eeyan ba tin lo gaasi dipo epo bẹntiroo.

Idi ni pe inu booti ni wọn yoo gbe kondoro ti yoo gba gaasi yi si.

Bi ẹru rẹ ko ba ti pọ, ko si iṣoro nipa eleyi.

Lakotan ni pe ko to le pinu lati maa lo ọkọ oni gaasi o di dandan ko ṣagbeyẹwo bi waa ṣe maa ri gaasi ra deede.

Lọwọlọwọ awọn aaye to n ta gaasi yi sinu ọkọ ko pọ bii ti bẹntiroo.

Idi ree to le fẹ ṣoro diẹ fawọn to ba kọkọ yi ọkọ pada si lilo gaasi.

Bi nkan ba ṣe n lọ si ti ijọba ati awọn ọlọdani naa si pese ile epo oni gaasi, lilo ọkọ gaasi yoo di amuyangan laarin awọn ọmọ Naijiria.