Mayowa Odetola coconut: Nǹkan tí mo lè fi eyín dá lárà pọ̀ ju ti àgbọn lọ -Mayowa tó ń fi eyín gé àgbọn

Àkọlé fídíò, Mayowa Afeyin ge agbọn

Awọn agba to ni eyin mu ju abẹ lọ mọ ohun ti wọn n sọ , paapaa julọ pẹlu ọrọ arakunrin Mayọwa Ọdẹtọla.

Mayọwa Ọdẹtọla jẹ eeyan kan to jẹ pe o lee fi eyin lasan ya gbogbo epo ẹyin agbọn kuro lailo ada tabi ọbẹ.

BBC News Yoruba ṣe abẹwo sii ni ilu Abẹokuta ni ipinlẹ Ogun nibi ti o ti ṣe afihan iṣẹ aramanda yii.

Mayọwa ṣalaye pe lati igba ewe, nigba ti oun wa ni nnkan bii ọmọ ọdun mẹwaa ni oun ti bẹrẹ si ni fi eyi ya agbọn, to si ti di irọrun fun oun bayii.

O ni iṣẹ atun ohun elo ina manamana ṣe ni oun kọ oun si tun maa n ṣe iṣẹ alawada ori ayelujara, ti ọpọ n pe ni 'skit' bayii lọpọ igba.

'Aṣeyọri Hilda Baci tun fun mi ni iwuri'

Arakunrin Mayọwa Ọdẹtọla ti ọpọ mọ si 'Mayor of Abk' ni aṣeyọri Hilda Baci, ọmọ Naijiria to kogoja ni ami ẹyẹ Guiness World Records pẹlu ounjẹ sise lo fun oun ni iwuri pe oun naa lee gbe agbọn ti oun n fi eyi ya naa de ibi giga sii.

Ni aipẹ yii ni aworan Mayọwa gbilẹ lor ayelujara lẹyin to fi eyin ya aadọta agbọn.

Ọpọlọpọ leyi ya lẹnu nigba ti wọn ri fidio naa, eleyi ti .sọ pe o jẹ iwuri nla fun oun.

Ọgbẹni Ọdẹtọla ni ọpọ ipenija loun ti ri lẹnu.