Ẹni tó bá lọ sílé ẹjọ́ lórí ìlànà ọba jíjẹ nílùú Ibadan ń tan ara rẹ̀ - Makinde

Gomina Makinde ń gbé ọ̀pá àṣẹ lé ọ̀kan lára àwọn olóyè náà lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, OYO GOVT

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti gbe ọpa aṣẹ le awọn oloye agba ti ilẹ Ibadan mẹwaa, ti wọn si gba igbega sipo Ọba nilẹ Ibadan.

Bi o tilẹ jẹ pe mọkanla ni awọn oloye agba fun Olubadan, mẹwaa ninu wọn ni o tẹri gbade nitori Otun Olubadan, ẹni ti o ti figba kan ri jẹ Gomina ipinlẹ Oyo, oloye Adewolu Rasheed Ladoja ni ko si nibi ayẹyẹ ọhun.

Ṣaaju ki Gomina Makinde to gbe Ọpa aṣẹ fun awọn Ọba ọhun ni Olubadan ti gbe ade lewọn lori ti o si rọ wọn lati lo ipo wọn daradara fun idagbasoke agbegbe wọn.

Awọn oloye agba to gba igbega sipo Ọba ni, Balogun ti ilu Ibadan Owolabi Olakulehin; Otun Balogun, Tajudeen Ajibola; Osi Olubadan, Eddy Oyewole; Osi Balogun, Lateef Adebimpe; Ashipa Olubadan, Biodun Kola-Daisi; Ashipa Balogun, Kola Adegbola; Ekerin Olubadan, Hamidu Ajibade; Ekerin Balogun, Olubunmi Isioye; Ekarun Olubadan; Bayo Akande and Ekarun Balogun, Abiodun Azeez.

Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ni jijẹ Ọba yii ko ni mu akude ba ilana ti wọn fi n jẹ Ọba ni ilu Ibadan ko to di asiko yii.

Tajudeen Aremu, ẹni ti o gbẹnu sọ fun Olubadan ni bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ awuyewuye lo ti waye ṣaaju ayẹyẹ naa, gbigba Ade ọhun yoo tun mu ẹyẹ ba awọn oloye agba naa ni

O fi kun pe yoo tun mu opin ba itiju ati ẹtẹ ti awọn oloye agba naa maa n koju lọwọ awọn eniyan ti wọn ba lọ sibi ayẹyẹ tabi lọ sode.

Nigba to n sọrọ, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni ayẹyẹ naa fi idi ofin to n ri si ọrọ oye jijẹ nipinlẹ naa mulẹ, eyi to fun Gomina laṣẹ lati fi ọwọ si yiyan Ọba.

Makinde ni niwọn igba ti mẹwaa ninu awọn mọkanla to yẹ kí wọn gba Ade ti wa nibi ayẹyẹ ọhun, ó fihan wi pe gbogbo ilu lo fọwọsi ayẹyẹ naa.

Makinde ni ẹnikẹni ti o ba tun lọ si ile ẹjọ nitori ilana jijẹ oye yii n tan ara rẹ jẹ ni.

Olubadan nìkan kọ́ ni ọba mọ́ ní Ibadan, ọba ti pọ̀ báyìí - Olugbon ti Orile-Igbon

Aworan

Olugbon ti Orile-Igbon, Oba Francis Olushola Alao ti gba awọn Ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ jẹ ni ilu Ibadan ni imọran lati jẹ ki imọ wọn ṣọkan fun ilọsiwaju ilu Ibadan.

Ọba naa sọ eyi lasiko ti wọn n fi ade de ori awọn ọba tuntun naa nibẹ.

Awọn ọba tuntun naa ni wọn jẹ oloye agba tẹlẹ ni ilu Ibadan amọ ti wọn ti wa di ọba ni awọn agbegbe wọn.

Ninu ọrọ rẹ, o ni bayii ti kii ṣe Olubadan nikan kọ ni ọba mọ ni ilu Ibadan awọn lọbalọba to ku gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu awọn Ọba kaakiri ipinlẹ Oyo.

Bakan naa lo ṣapejuwe Olubadan gẹgẹ bi ẹni ti ipo rẹ ti kuro ni Ọba nikan, amọ ti o ti di ọba to n fi ọba jẹ bayii, eleyii to pe ni’’imperial majesty’’.

O ṣapejuwe ipo awọn ọba tuntun naa gẹgẹ bi eleyii to bu iyi kun ilu Ibadan, to si yẹ ki inu gbogbo eniyan dun si.

Aworan

Oloye agba mọkanla niluu Ibadan lo tun ade Ọba gba lonii.

Ayẹyẹ ifunni lade ọhun ni o waye ninu gbagede Mapo.

Amọ gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ to tun jẹ Otun Olubadan, Rashidi Ladoja ni ko yọju sibi ayẹyẹ naa nitori ṣaaju lo ti sọ pe ipo Ọba kan ṣoṣo ti oun fẹ ni ipo Olubadan.

Lara awọn oloye agba ti ilẹ Ibadan ti wọn gba ade loni ni...

Aworan
  • Balogun ti ilu Ibadan Owolabi Olakulehin;
  • Otun Olubadan ti Ibadan,Rasheed Ladoja;
  • Otun Balogun, Tajudeen Ajibola;
  • Osi Olubadan, Eddy Oyewole;
  • Osi Balogun, Lateef Adebimpe;
  • Ashipa Olubadan, Biodun Kola-Daisi;
  • Ashipa Balogun, Kola Adegbola;
  • Ekerin Olubadan, Hamidu Ajibade;
  • Ekerin Balogun, Olubunmi Isioye;
  • Ekarun Olubadan; Bayo Akande
  • Ekarun Balogun, Abiodun Azeez.

Sísọ àwọn Olóyè di Ọba kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ipò Olubadan - Ọba Balogun

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Awọn agbaoye Olubadan ni wọn ko wa gẹgẹ bi oloye agba mọ, ti wọn yoo si di Ọba alade.

Awọn igbimọ mọkanla ọhun ni Olubadan tí ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun yoo gbe ade Ọba fun loni niluu Ibadan

Olubadan kede ọrọ naa ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ rẹ, Oladele Ogunsola buwọlu fun awọn akọroyin.

Awọn agbaoye ti yoo gba Ade Ọba ọhun ni Agbaoye Owolabi Olakulehin, Rashidi Ladoja, Tajudeen Ajibola ati Eddy Oyewole, Balogun of Ibadanland, Otun Olubadan, Otun Balogun ati Osi Olubadan.

Awọn mii ni Agbaoye Lateef Gbadamosi Adebimpe (Osi Balogun); Abiodun Kola-Daisi (Ashipa Olubadan); ati Kolawole Adegbola (Ashipa Balogun).

Bakan naa ni, Agbaoye Hamidu Ajibade (Ekerin Olubadan); Dada Isioye (Ekerin Balogun); Adebayo Akande (Ekarun Olubadan); ati Abiodun Dauda Azeez (Ekarun Balogun)

Ayẹyẹ ọhun ni yoo waye ni gbọngan Mapo niluu Ibadan.

Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni igbagbọ wa pe yoo darapọ mọ ayẹyẹ ọhun tí yoo si gbe ọpa asẹ fun awọn ori ade tuntun naa

Nínu atẹjade naa Olubadan ni igbesẹ yii ko ni nnkan ṣe pẹlu ilana to wa ni ilẹ fun Olubadan ati pe yoo tun ṣe ọpọlọpọ anfaani fun sì ni

"Bi awọn kan ṣe n bẹru pe igbesẹ le se akoba fun ilana to ti wa nilẹ fun jijẹ Olubadan ni ko ni ẹsẹ ni ilẹ rara ati pe ko ni ibasepọ kan pẹlu ilana Olubadan