Ẹ̀gbẹ́ PoS kò ní àṣẹ láti fí gbèndéke iye owó ti wọn yóò maà gbà lọ́wọ́ àwọn oníbárà wọn– Ìjọba Naijiria

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba orilẹede Naijiria ti fesi si igbeṣẹ ẹgbẹ awọn oni PoS ni Naijiria, AMMBAN, ẹka ti ipinlẹ Eko lati ṣe afikun iye ti wọn yoo ma gba lọwọ awọn onibara wọn.
Bakan naa ni wọn fẹ fi gbedeke le ori iye ti awọn eniyan to ba fẹ gba owo tabi fi owo ranṣẹ yoo maa ṣan ni gbogbo igba.
Saaju ni ẹgbẹ naa ti fi lede pe iye ti wọn yoo ma gba lori ẹgbẹrun kan naira ni ọgọrun Naira, ti awọn to ba fẹ gba lati bi ẹgbẹrun lọna mejidinlogun si ẹgbẹrun lọna ogun yoo maa san bii ẹgbẹrin naira.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin Channels TV sọrọ fi idi igbeṣẹ wọn mulẹ.
O ni igbeṣẹ wọn yoo mu idọgba de ba iye ti wọn yoo maa gba lọwọ awọn olubara wọn, ti eyi yoo si ri pe awọn eniyan ko gba ju iye owo to yẹ ni ọwọ awọn araalu.
Amọ ẹka ijọba apapọ to n risi ọrọ karakata ni Naijiri, FCCPC ti kede igbeṣẹ ati ofin ijọba apapọ to tako igbesẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
‘’Ẹ̀gbẹ́ PoS kò ní àṣẹ láti fí gbèdéke iye owó t’’i wọn yóò maà lọ́wọ́ àwọn oníbárà wọn’’
Ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ ana, Tolu Ogunlesi fi lede loju opo Twitter rẹ lo ti sọ nipa awọn ofin to de ẹgbẹ awọn oni PoS naa.
Ninu atẹjade naa ni ajọ FCCPC ti o lodi si ofin ki ẹgbẹ kan gbe igbeṣẹ lati fi gbedeke lori oye ti wọn yoo ma ta ọja.
Ajọ naa ni iṣẹ ẹgbẹ awọn onibara abi ọlọja kankan ko rọ mọ sisọ iye ti awọn eniyan yoo maa ta ọja.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
‘’Ko ba ofin mu ti a si bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa nitori o tako ofin kara -kata.’’
''Adun ọja ni pe awọn eniyan le ra nibi to ba ti tẹ wọn lọrun, lai ṣe pe gbogbo wọn n ta ni iye kan naa.’’
Ajọ naa wa gba wọn ni imọran lati jawọ ninu igbeṣẹ naa nitori ijiya ni yoo tẹlẹ.
Bakan naa ni wọn ni awọn yoo ṣewadii ibi ti ẹgbẹ naa ti wa, ki awọn le ni aridaju nipa igbeṣẹ ti wọn fẹ gbe naa.
















