Wo àwọn òṣèré tíátà tó tọrọ ọkọ̀ tó sì ti rí gbà lọ́dún 2023

Oríṣun àwòrán, Others/BBC/Agbala Gabriel
Yoruba ní, ẹni to ba dakẹ, tara rẹ yoo ba a dakẹ.
Bẹẹ gan ni ọ̀rọ̀ rí fun àwọn òṣèré títa Yoruba kan, to ke jade lori ayelujara fun awọn ololufẹ wọn lati fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ta wọn lọrẹ.
Ninu oṣu Kẹfà, ọdun 2023, ni ìpè yii jade julọ.
Ohun to jẹ ìyàlẹ́nu ni pe, bi awọn agba òṣèré naa ṣe ń pariwo síta, ni awọn ọmọ Naijiria n dide fun iranlọwọ wọn.
Ẹ jẹ ka wo díẹ̀ lara àwọn òṣèré náà.
Iya Gbonkan

Bi ẹ ko ba gbagbe laipẹ yii ni Iya Gbonkan fi ipe sita lati tọrọ iranwọ lọdọ awọn ẹlẹyinju aanu ni Naijiria lati boju aanu wo o ki wọn ra ọkọ to le maa fi ṣe ẹṣẹ rin.
Iya Gbonkan ni oun ko fẹ maa gun ọkada alupupu tabi ta mọ mọto lati lọ si ibi to ba ti fẹ kopa ninu sinima eyi to ni o ti su oun.
Ẹni to fi ọkọ naa ta agba oṣere yii lọrẹ, Arabinrin Omobolanle Olatise ni idi ti oun fi ṣe eyi ni pe tori oun fẹ ṣe moriya fun Iya Gbonkan ni gẹgẹ bi akinkanju oṣere tiata.
Kete ti Iya Gbonkan foju kan ọkọ naa ni oun ati akẹgbẹ rẹ oṣerebinrin mii, Alirat Adunni ti ọpọ mọ si “Tamotiye” ki orin bọ ẹnu ati adura ti wọn si n yọ ṣẹṣẹ tori wọn ko le pa idunu wọn mọra mọ.
Lalude

Oríṣun àwòrán, Others
Ko pẹ ti awọn alaanu dide fun iya Gbonkan, ni oserekunrin mii, Adekunle Adetayo, ti ọpọ mọ si Lalude, naa ke gbàjarè lori ayelujara pe oun nilo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́.
Bi ìpè rẹ ṣe jade sori ayelujara, paapaa pẹlu iranlọwọ apanilẹ́ẹ̀rín, Kamo Comedy, to ba a gbe lárugẹ.
Nílé-lóko ni awọn ololufẹ àgbà osere naa ti dá owo jọ lati fi mu inu rẹ dun.
Ẹni kan ti ko dárúkọ rẹ fun ni miliọnu mẹta Naira lati fi ra ọkọ̀ tuntun. Awọn míì tun da miliọnu kan Naira mọ owo naa, ati awọn ẹ̀bùn miran.
Ninu fidio to safihan asiko ti wọn gbe ọkọ naa fun Lalude, ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Camry pupa ni.
Osere naa fi ayọ̀ ọkan rẹ hàn fun ifẹ àti atilẹyin to rí gbà.
Alapini
Òṣeré miran tó tun ke gbajare fun ẹ̀bùn ọkọ̀ lori ayelujara ni Ganiu Nofiu, ti ọpọ mọ si Alapini Osa.
Lẹ́yìn ọjọ díẹ̀ ti ọrẹ rẹ, Lalude, ri ẹ̀bùn ọkọ̀ gba, ni Alapini naa bẹrẹ si ni bẹbẹ.
Agba òṣèré naa ninu ikede to fi sita sọ pe ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ meji ni oun ni tẹlẹ, sugbọn oun ta mejeeji lati fi ṣe itọju ọmọ rẹ kan to ṣe aisan.
O ni gbogbo dukia olowo iyebiye ni oun ta, àmọ́ ọmọkùnrin rẹ ọ̀hún to jẹ ẹni ogoji ọdun, pada kú.
Alapini sọ pe igbeaye kò rọrùn lati igba ti ọmọ naa ti kú.
Eyi lo mu ki oun naa rawọ ẹ̀bẹ̀ si àwọn ololufẹ rẹ lati dide iranlọwọ fun un, gẹ́gẹ́ bi wọn ṣe ṣe fun akẹẹgbẹ́ rẹ, Lalude.
Owo bii miliọnu kan lé díẹ̀ Naira ni ẹni to ṣe agbatẹru ikowojọ naa kede pe wọn ri, sugbọn a ko tii le sọ boya owo naa ti pe bayii nitori pe Alapini ko tii kede pe oun ti ra ọkọ̀ naa.
Pariolodo

Oríṣun àwòrán, Agbala Gabriel
Ninu oṣu Kẹfà, ọdun 2023 yii kan naa, òṣèrékùnrin mii, Pariolodo naa fi fidio kan sita, ninu eyi ti oun ati awọn ọmọ rẹ meji ti sọ̀rọ̀ lori igbeaye ìnira ti wọn n gbé.
Ninu fidio naa ni wọn ti ṣàlàyé pe ilé akọpati ni àwọn n gbe, ati pe Pariolodo naa nilo ọkọ̀.
Nílé-lóko si ni awọn ọmọ Naijiria ti dìde iranlọwọ fun un.
Pasitọ kan, Gabriel, to ṣe agbatẹru bi Iya Gbonkan ṣe ri ọkọ ati owo to fi pari ile rẹ gbà, ṣe àbẹ̀wò si Pariolodo.
Oun lo ṣi ba a pariwo igbe fun iranlọwọ jade. Akitiyan wọn so eso rere, nitori pe bi miliọnu mẹfa Naira ni awọn eeyan dá jọ fun Pariolodo lati fi rán lọ́wọ́.
Yatọ si pe o gba ẹbun ọkọ̀ Toyota Camry kan, wọn tun fun ni oúnjẹ ati awọn nnkan èlò inú ile.












