Ọkùnrin kan gbé ọọ̀ni ní ìyàwó nítorí ètùtù ọrọ̀

Oọ̀ni to ṣe ìgbéyàwó

Oríṣun àwòrán, Reuters

Olori ìlú kekere kan ni orile-ede Mexico, ti gbe ọọ̀ni kan níyàwó, gẹgẹ bi etutu fun ọrọ̀ rẹpẹtẹ.

Iroyin sọ pe ọọ̀ni naa to jẹ ọdun meje, ti wọn sọ orúkọ rẹ ni 'Little Princess' (ọmọọbabìnrin kekere') jẹ́ asoju òrìṣà kan to nii ṣe pẹlu ilẹ̀.

Igbeyawo rẹ pẹlu olori ìlú naa , Victor Hugo Sosa, jẹ àpẹẹrẹ idapọ eniyan ati ara ọrun.

Àṣà naa ti wa fun aimọye ọdun - o si wọpọ laarin awọn eeyan Chontal ati Huave nipinlẹ Oaxaca.

Victor Hugo Sosa sọ fun awọn akọroyin pe igbeyawo naa jẹ idapọ àṣà ilu mejeeji.

Ninu fidio igbeyawo naa, ọọ̀ni naa wọ aṣọ igbeyawo funfun, ti wọn si fà á le ọkọ rẹ lọwọ.

Wọ́n fi nnkan di oọ̀ni naa lẹnu, lasiko ti ọkọ rẹ n fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

Èrò pọ̀ nibi ayẹyẹ igbeyawo naa, gbogbo wọn n jó, wọn n yọ̀.

Olivia Perez to ṣe amojuto imura oọ̀ni naa sọ pe "oọ̀ni naa jẹ ayaba, ọmọọbabìnrin to n pese omi, òjò, ati ìkórè irúgbìn to dara".

Fidio naa tun ṣe afihan bi wọn ṣe tun pàárọ̀ aṣọ ọrùn oọ̀ni naa, pẹlu orisirisi awọn nnkan iṣaraloge ti wọn to si ara rẹ.

Ninu aṣọ tuntun yii ni ọkọ rẹ ti gbe e dání, to si n jó pẹlu rẹ.