“Ọkùnrin mẹ́wàá ni mò ń bá lòpọ̀ lójúmọ́”

Oríṣun àwòrán, @Others
Ọmọdebinrin kan, to jẹ ọkan lara awọn aadọta obinrin ti wọn fi n ṣowo nọbi ti sọ ohun toju rẹ nidi iṣẹ naa.
Ajọsẹpeọ ileeṣẹ ọmọ ogun, ileẹṣẹ Civil Defense ati ajọ to n gbnogun fifi eeyan ṣowo ẹru, NAPTIP lo doola rẹ atawọn mii nile itura kan ni ipinlẹ Rivers.
Gẹgẹ bii ohun ti ọmọdebirin naa ti a pe orukọ rẹ ni Nancy (lati bo orukọ abisọ rẹ laṣiri) sọ, ibatan rẹ kan lo mu kuro ni abule wọn lọ si igboro fun iṣẹ amọ ko mo pe wọn fẹ lọ ta oun fun iṣe nọbi ni.
Ọwọ ijọba tẹ awọn to n fi Nancy ṣe iṣẹ aṣẹwo lẹyin ti ileeṣẹ ọmọ ogun ati ajọ NAPTIP gbọ nipa awọn eeyan naa, eyii to mu ki wọn doola ọmọbirin ọhun, ti wọn si wo ile ti wọn n lo fun iṣẹ nọbi naa palẹ.
Ni ṣe ni wọn tan mi jẹ
Ọkan lara awọn ọmọdebirin ti wọn doola nile nọbi naa sọ pe sẹ ni ẹni to ko wọn lọ ṣiṣẹ nọbi ọhun tan awọn jẹ pe iṣẹ karakata ni awọn yoo maa ṣe amọ ohun miran ni wọn fi awọn ṣe.
O ni “Obinrin kan wa si abule wa pe oun yoo ba wa wa iṣẹ si ile itura kan.”
“Ko pẹ si asiko ti a bẹrẹ iṣẹ naa ti obinrin ọhun ko wa sinu yara kan pe iṣẹ nọbi ni a o maa ṣe.”
“Amọ a kọ jalẹ pe a ko ni le ṣe iṣẹ naa, o si sọ fun wa pe oun yoo fi ebi pa wa ti a ba kọ lati ṣiṣẹ ọhun.”
“Ọkunrin bii mẹwaa ni mo maa n ba lopọ lojojumọ, ọga wa si ni a maa n ko gbogbo owo ti a ba pa fun.”
O fi kun pe bo tilẹ jẹ ọga awọn lo maa n gba owo ti wọn ba pa, o maa n fun awọn lara owo naa.”
Ọmọde ni ọpọ ninu awọn ti wọn n fi ṣiṣẹ nọbi – NAPTIP
Adari ajọ NAPTIP ni ipinlẹ Rivers, Nwa-Amaka Ikediashi ni ajọ naa yoo bẹrẹ iṣẹ lori awọn naa lati le mu ki wọn gbagbe iṣẹ nọbi ti wọn ti ṣe sẹyin atawọn ohun ti wọn ti la kọja.
O ni “Ọmọde ni ọpọ ninu wọn, o si ṣeeṣe ki wọn pada sinu iṣẹ nọbi naa, amọ a o ṣiṣẹ lori wọn lati yi irori wọn pada.”
“Bẹẹ naa ni a o ṣe gbogbo iwadii to yẹ lori bi wọn ṣe bẹrẹ iṣẹ yii ki awọn to n fi wọn ṣowo le foju wina ofin laipẹ.”
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, okunrin kan ati obrinin meji lo n dari ile itura ti wọn ti n fi awọn ọmọde naa ṣowo nọbi.












