'Ifá ló mú èmi o! Ẹnu iṣẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Fásitì ni mo wà tí wọ́n ní kí n wá jẹ Olota ti ìlú Ota'
"Kò dẹrùn fún mi láti kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ mọ́ lọ gbájúmọ́ iṣẹ́ Àafin níwọ̀n ìgbà tí mo ti di Ọ̀jọ̀gbọ́n".
Aafin ilu Ọta gba alejo ikọ iroyin BBC Yoruba bẹẹ si ni kilaasi Ọba Ọlọta ti ilu Ọta gẹgẹ bi Ọjọgbọn Fasiti naa gbalejo BBC.
"Awọn to n kọ ẹkọ onipele ti oye PhD ni mo n kọ ni ẹkọ. Ara iṣẹ wa gẹgẹ bi Ọba naa ni ka maa gba awọn ọmọ ni imọran".
Ọba Lanlege ni ẹni iṣẹ yii ni oun wa ti wọn fi ni Ifa mu oun to si ni gbogbo iṣẹ ti oun ti kọ ni Naijiria ati ni ilu Ọba ko yẹ ko danu bẹyẹn tori naa loun ṣe tẹsiwaju ninu iṣẹ olukọ Fasiti titi to fi de ipo Ọjọgbọn.

Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti n jade lori pe ṣaaju ifinijoye ni awọn Ọba ilẹ Yoruba ti n daa bi ọgbọn lati di ọrẹ awọn gomina ipinlẹ tori ki wọn le fi wọn jẹ Ọba ati pe kii ṣe Ifa lo n mu ọmọ oye mọ bayii.
Ẹwẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo yii, Ọba Adeyemi Lanlege ti ilu Ọta ṣalaye pe kii ṣe pe jijẹ Ọba mu oun loju tori oun ni iṣẹ ti oun n ṣe tẹlẹ koda o ti kawe ni oke okun to si wo o pe o yẹ ki oun mu imọ ti o kọ lọhun wa sile ki awọn ọmọ Naijiria jẹ anfani rẹ.
Ẹnu iṣẹ yii lo wa to ni wọn wa pe oun wipe Ifa ti mu oun lati jẹ Ọba ilu Ọta ni ipinlẹ Ogun.




