'Ohun ìbànújẹ́ ló jẹ́ fún mi pé wọ́n dáná sun ìyá mi lójú mi láì rí nǹkankan ṣe si'

Oríṣun àwòrán, UK OGAH
Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni ìròyìn kan gba orí ayélujára nípa ìyá kan tí àwọn kan dáná sun ní ìlú Old Netim, ìjọba ìbílẹ̀ Akamkpa, ìpínlẹ̀ Cross River, ẹkùn ààrin gbùngùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹfà ọdún 2023 ni àwọn ènìyàn náà dáná sun abílẹ́kọ Martina Okey Itagbor, tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún, fẹ́sùn wí pé àjẹ́ ni.
Ọmọ ìyá olóògbé Martina Itagbor bá BBC Pidgin sọ̀rọ̀ tó sì ṣàlàyé bí ikú ṣe kú àti bí ọ̀bẹ ṣe bẹ́ àti bí ó ṣe rí lára rẹ̀ pé ọ̀nà yìí ni ìyá rẹ̀ gbà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.
Arábìnrin Ntoi Itagbor tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ mẹ́rin nínú àwọn ọmọ tí ìyá náà bí sún ẹkún kíkorò nígbà tó ń ṣàlàyé pé iwájú ṣọ́ọ̀ṣì àwọn ni wọ́n àwọn tó dáná sun ìyá òun pa á sí.
Ó ní òun rí bí wọ́n ṣe ń dáná sun ìyá òun àmọ́ òun kò lè ṣe nǹkankan láti ran ìyá òun lọ́wọ́ nítorí gbogbo rẹ̀ dàbí àlá lójú òun.
Ẹ̀sùn àjẹ́
Ntoi sọ́ fún BBC pé nínú oṣù Kẹrin ọdún 2023 ni àwọn ọ̀dọ́ kan lọ fi ẹjọ́ ìyá òun sun olórí ìlú àwọn pé àjẹ́ ni ìyá òun.
“Olórí ìlú wa, Ntufam Augustine Nyong Orok yọ ọwọ́ ara rẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ náà tó sì ní kí ìyá mi wẹ ara rẹ̀ mọ́ tí kìí bá ṣe àjẹ́.”
Nígbà tí BBC kàn sí olórí ìlú náà láti ṣàlàyé ohun tí ó mọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó kọ̀ láti sọ ohunkóhun.
“Ọ̀rọ̀ náà ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá nítorí náà mi ò ní sọ ohunkóhun nípa rẹ̀.”
Ntoi ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn ènìyàn náà kọ́kọ́ ṣe ìkọlù sí ìyá nígbà àkọ́kọ́, òun lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Old Netim, Akamkpa àmọ́ àwọn ọlọ́pàá kò ṣe nǹkankan sí ọ̀rọ̀ náà.
Ó ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kẹfà ọdún 2023 ni àwọn ọ̀dọ́ kan kó ara wọn sínú ọkọ̀ láti lọ kópa níbi ayẹyẹ ìbúrawọlée fún olóṣèlú kan ní Akamkpa àmọ́ tí wọ́n pàdé ìjàmbá ọkọ̀ lọ́nà.
Ó ṣàlàyé pé ó jẹ́ ohun tó ṣeni láàánú pé méjì nínú àwọn ọ̀dọ́ náà ló pàdánù ẹ̀mí wọn ní ojú ẹsẹ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ náà tí àwọn mìíràn sì farapa.
Ó fi kun bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ tò sí gbìyànjú láti má sunkún mọ́ pé ọjọ́ kejì tí ìjàmbá ọkọ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni àwọn ọ̀dọ́ náà wá sí ilé àwọn láti wá wọ́ ìyá òun sí títì wí pé òun lọ fi àjẹ́ rẹ̀ fa ìjàmbá ọkọ̀ àwọn tí àwọn méjì fi kú.
“Ní nǹkan bíi aago méje àárọ̀ ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹfà ni àwọn ọ̀dọ́ náà wá sí ilé wa, lu ìyá mi bíi kíkú bíi yíyè kí wọ́n tó dáná sun-ún tó sì jóná si eérú.
Ẹlòmíràn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lójú rẹ̀ ní lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn náà dáná sun ìyá ọ̀hún di eérú tán, wọ́n gbá eérú òkú rẹ̀ sínú gọ́tà, tí wọ́n sì tún fọ ilẹ̀ títì náà nù.
Wọn ò jẹ́ kí n lọ gba ìyá mi kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa á
Ntoi tẹ̀síwájú pé inú ṣọ́ọ̀ṣì ni òun wà nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ náà wá sí ilé àwọn àmọ́ ìgbà tí ìròyìn kàn dé ọ̀dọ́ òun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì kò jẹ́ kí òun jáde.
“Inú ṣọ́ọ̀ṣì ni mo wà, mò ń wo bí iná ṣe ń jó màmá mi àmọ́ wọn ò jẹ́ kí n bọ́ síta láti lọ ràn-án lọ́wọ́.”
“Èmi tètè lọ sí ilé ìjọsìn lọ́jọ́ náà nítorí òṣìṣẹ́ ìjọ ni mí àmọ́ kò pẹ́ púpọ̀ ni mo rí àwọn ọ̀dọ́ náà tí wọ́n ń wọ àdúgbò wa wá.”
“Mo gbìyànjú láti kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì àmọ́ wọn ò jẹ́ ki ń kúrò, nǹkan tó máa wà ní ọpọlọ mi títí tí mà á fi jáde láyé nìyí.”
“Ìyá mi ni gbogbo nǹkan sí wa nítorí àgbẹ̀ tó ń mójútó àwọn ọmọ rẹ̀ láti ìgbà tí bàbá mi ti kú láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni ìyá mi.”
“Òun ló ń ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ kí ọkọ mi máa ṣe fún mi, ṣé irú ìyá bẹ́ẹ̀ ló yẹ kí àwọn kan pa lọ́nà tí kò dára báyìí.”
Bákan náà ló fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń pe ìyá òun ní àjẹ́, òun mọ̀ wí pé onígbàgbọ́ òdodo ni ìyá òun nígbà tó wà láyé.
Grace Frank tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìjọ ṣọ́ọ̀ṣì Aguda tí Martina Itagbor ń lọ sọ wí pé ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún àwọn pé wọ́n pa ọmọ ìjọ àwọn sí iwájú ilé ìjọsìn àwọn.
Ó sọ fún BBC pé Martina àti àwọn ìyá ọmọ méjì tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ náà ló jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Catholic Women Association nínú ìjọ àwọn.
Ìpànìyàn lọ́wọ́ ara ẹni ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ̀ nìyí tí ìpanìyàn lọ́nà àìtọ́ ń wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ Akamkpa ní ìpínlẹ̀ Cross River gẹ́gẹ́ bí ìjábọ̀ ṣe fi hàn.
Ìròyìn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn alùfáà ìjọ Aguda méjì kan, Daniel Omonga àti ẹnìkan pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀.
Àwọn ọ̀dọ́ ìlú náà lọ pa àwọn olóyè mẹ́rin kan pé oṣó ni wọ́n àti pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú àwọn àlùfáà náà. Bákan náà ni wọ́n dáná sun ilé àtàwọn ohun ìní àwọn ènìyàn mìíràn.
Bákan náà nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2022, wọ́n pa àwọn márùn-ún kan fẹ́sùn wí pé àjẹ́ ni wọ́n.
Inú igbo ni wọ́n sun abílékọ Iquo Edet Iyo àtàwọn mẹ́rin yòókù rẹ̀ sí ní ìlú Ndon Nwong, Okurikang, ìjọba ìbílẹ̀ Odukpani ìpínlẹ̀ Cross River bákan náà.
Kíni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dọdẹ àwọn afurasí tó pa Martina Itagbor.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Cross River, Gyogon Grimah ti ní kí àwọn ọlọ́pàá fòfin gbé àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú ìyá náà kí wan sì fi ojú wọn winá òfin.
Grimah nínú àtẹ̀jáde kan ní ìpànìyàn lọ́nà jẹ́ ohun tí ọlọ́pàá kìí fọwa yẹpẹrẹ mú rárá.
Bákan náà ni gómìnà CrosS River, Bassey Otu ní kí àwọn ọlọ́pàá ri pé wọ́n nawọ́ gán àwọn ènìyàn tó wà nídìí ikú ìyá náà.















