Bí mo ṣe pàdánù ọwọ́ mí lásìkò tí mo ń dáàbò bo ìlú mi-Sani

Aworan

Oríṣun àwòrán, OFFICER BABANGIDA

"N ko kabamọ pe mo padanu ọwọ mi nítorí nnkan ti Ọlọrun ti ni yoo waye sì mi nìyẹn ati loni awọn eeyan ilu mi n kan sara sì mi."

"Nǹkan to dun mi ju ni pe mo padanu iyawo sọwọ iku òjìji lẹyin ti mo padanu ọwọ mi nitori o oun ronu lori iṣẹlẹ to sẹlẹ si mi

Bayii ni Sani Inusa tí ọpọ mọ si ọfisa Babangida ni agbegbe Tudun Fulani niluu Kano se padanu ọwọ rẹ.

O ba ileeṣẹ BBC News sọrọ lori bi o ṣe padanu ọkan lara apa rẹ, to si ku diẹ ko padanu ẹmi rẹ sọwọ awọn adigunjale.

Lọdọ awọn eeyan to n gbe ni Tudun Fulani, Babangida jẹ ẹni ti Ọlọrun ran si wọn nítorí o n gbinyanju lati fi opin si gbogbo iwa adigunjale ni agbegbe naa.

"Ko si ileeṣẹ Ọlọpaa kan kan ni gbogbo agbegbe yii, eyi lo jẹ ki n darapọ mọ awọn fijilante ni bi ọdun marun un sẹyin lati le ni anfani gbena woju awọn eeyan buruku ni agbegbe mi.

"A ni ọpọlọpọ awọn ọdọ ni mu ogun oloro ni ọkunkundun pelu idigunjale to fi jẹ pe ẹni to ba darapọ mọ Ọlọpaa tabi fijilante tí di ọta wọn.

"A ko ni ile wosan tabi ina mọnamọna ni adugbo yii to fi jẹ pe lasiko ojo ọpọ lo ma n sa fun agbegbe wa nítorí ọna ti ko da.

Bi mo ṣe padanu ọwọ mi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọjọ kọkandinlogun, ọdun 2023, Babangida ni oun wa ni ile nigba oun gba ipe pe ẹnikan lilo iranlọwọ

"Mo n ran asọ fun aga nitori mo ní isẹ miiran ti mo n se yatọ si isẹ fijilante.

"Ní ago mẹta ooru ni mo gba ipe pe àwọn adigunjale ti kọlu ile eeyan mi kan tí mo si suure lọ si ibẹ "

Ṣugbọn Babangida ko mọ pe awọn adigunjale yii pọ ju agbara rẹ ati akẹgbẹ rẹ lọ.

"O se ni laanu pe awa mejeeji ni a jade lasiko naa ti awọn adigunjale yìí si to aadọta, ti wọn si bẹrẹ lọ awọn ohun ija fi koju wa

"Wọn fi ada saa mi gan pẹlu ọbẹ. Bi wọn ṣe n saa mi ni mo n fi owo da duro.

"Akẹgbẹ mi keji naa ko gbẹyin, wọn jọ saa wa ni ada ni ti wọn si fi wa silẹ nínú agbara ẹjẹ pẹlu igbagbọ pe a ti kú

Babangida ni oun tiraka lati fi aya rin de ibi ti awọn eeyan ti ri oun, ti wọn si gbe oun lọ ile wosan.

"Mo faya rin gan ki awọn eeyan to wa gbe mi lọ ile wosan Murtala

"Awọn dokita wa fi idi rẹ mulẹ pe mo ti padanu ọwọ mi ati pe wọn gbọdọ ge owo naa. Ọwọ kejì naa ko sisẹ dara bí ti tẹlẹ mọ.

"N ko le dẹkun ki-kọju si awọn eeyan buruku"

Babangida ni pẹlu ipo ti oun wa, o wa wu oun lori ti oun ba ranti awọn nnkan ti oun ti fi owo ohun mejeeji ṣe ki iṣẹlẹ naa to waye

"Awọn iranti yii ma mu inu mi dun pupọ nitori a fi aye ni awọn adigunjale lara pupọ ni Tudun Fulani.

"A ti mu ọpọlọpọ awọn to n gbe ogun oloro ati awọn adigunjale tí a yoo si gbe wọn ileeṣẹ Ọlọpaa ni Bachirawa ati Gwala.

"Laipẹ yii, a mu awọn kan ti wọn fẹ jí awọn ọmọ kekere gbe ni agbegbe wa.

"Pẹlu bí apa ṣe tí ge, ti ìkejì ko sisẹ mọ, Babangida ni oun si maa lọ ọfisi fijilante lojojumọ lati se iwọn tiẹ̀

"Ojojumọ ni mo n lọ sibẹ nitori ibẹ ni a n sọrọ lori ọna ti a fi mu awọn adigunjale.

"N ko setan lati fẹyin tí lẹnu isẹ yii nítorí nnkan ti mo nifẹ ni lati ma ran awọn eeyan ati agbegbe mi lọwọ."