Ìjọ̀ba Tinubu yóò ma gba owó orí lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò ní àwọn ọjà káàkiri Naijiria

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba orilẹede Naijiria ti kede pe awọn yoo bẹrẹ si ni gba owo ori lọwọ awọn ọlọja kaakiri orilẹede Naijiria.
Ijọba ni eleyii yoo fun wọn ni anfaani lati mọ iye owo ori to n wọle ni abẹle.
Wọn ni eleyii yoo mu adinkun ba orisirisi owo ori ti wọn n gba ni abẹnu.
Ninu atẹjade ti Ileeṣẹ to n risi ọrọ owo ori labẹle, FIR lo ni awọn n ṣiṣẹ pẹlu ẹgbẹ awọn ọlọja ni Naijiria, MATAN

Oríṣun àwòrán, Others
FIRS ni ajumọṣe yoo wa laarin ileeṣẹ naa ati ẹgbẹ awọn ọlọja ni Naijiria.
‘’Eyi yoo mu rọrun fun awọn araalu lati maa san owo ori wọn si apo iṣuna kan, lai si pe ọpọlọpọ awọn eniyan lo n gba owo ori ni Naijiria.
‘’Ajọṣepọ naa yoo mu ki awọn araalu mọ nipa owo ori ati bi wọn ṣe maa san lai niran fun wọn.
FIRS ni eyi yoo mu opin deba awọn to n gba owo ori lọwọ awọn ọlọja lọna aitọ, ti yoo si fi opin si igbeṣẹ awọn ọmọ igboro to n gba owo ori ita lọwọ awọn eniyan.

Oríṣun àwòrán, Others
Ninu ọrọ rẹ, MATAN ni awọn ni ọlọja to le ni miliọnu ogoji ọlọja ninu ẹgbẹ wọn, eleyii ti wọn ni ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ti mu owo wọle.
Ileeṣẹ to n risi ọrọ owo ori labẹnu fikun un pe awọn ọlọja naa yoo ni ami idanimọ pẹlu nọmba idanimọ.
Bakan naa ni oju opo naa yoo ma ṣafihan awọn to n sanwo ori wọn deede, awọn ti ko san ati bi wọn yoo ṣe maa wo iye ti wọn san lati asiko de asiko.

















