Èmi kò nílé níbikíbí àfi Nàìjíríà, bẹ́ẹ̀, mí ò kọ́ ilé tuntun lórí òye- Buhari

Kini o ṣokunfa bi àwọn ọmọ Nàìjiría ṣe tun lọ hu ọrọ Aarẹ ana, Muhammadu Buhari sita lori ayelujara?
Nigba ti Buhari ṣi wa lori aleefa lo lọ si Umited Kingdom to si ṣabẹwo si Oba Charles nigba naa.
Lasiko abẹwo yii ni oun ati Oba Charles jọ sọrọ ti Buhari si ṣalaye pe oun ko ni ile Adani kankan ni orilẹ-ede miran ju Naijiria lọ nitori pe oun kọ lati ko ọrọ jọ funra oun.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin lẹyin ipade ọhun, ni Buhari sọ pe Ọba Charles beere lọwọ oun boya oun ni ile silẹ Gẹẹsi, oun si fesi pe rara.
O ni “O beere lọwọ mi boya mo ni ile nibi (UK), mo ni rara.”
“Naijiria nikan ni mo n gbe, awọn ile ti mo si ni sibẹ gan ko kọja awọn ile ti mo ti kọ ṣaaju ki n to di Aarẹ.”
“Mi o nifẹ si ki n maa kọ ile kiri, mo ni itẹlọrun lasiko ti mi o ni nnkankan.”
Ààrẹ Buhari ṣàlàyé ohun tó gbe lọ rí Ọba Charles Kẹta ní ààfin Buckingham
Ọba Charles beere lọwọ mi boya o ni ile ni UK – Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ipade pẹlu Ọba ilẹ Gẹẹsi, King Charles III, ninu aafin Buckingham to wa niluu London.
Igba akọkọ ree ti Buhari ati Ọba Charles yoo pade lati igba ti Charles ti gori itẹ iya rẹ to di oloogbe ninu oṣu Kẹsan an, ọdun yii.
Lẹyin ipade wọn, Buhari sọ fun awọn akọroyin pe pupọ ninu ọrọ ti wọn jiroro le lo da lori eto ọrọ aje laarin orilẹ-ede mejeji.
Kini koko ipade Buhari ati Oba Chalres nigba naa?
O ni oun ni ireti pe to ọrọ aje laarin Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi yoo maa tẹsiwaju lai si idiwọ kankan.
Aarẹ Buhari fi kun pe Ọba Charles ni inu didun si Naijiria, o si sọrọ rere nipa Naijiria.
Awọn mejeji tun sọrọ nipa bi ibaṣepọ to wa laarin orilẹ-ede mejeji yoo ṣe gun rege si.
Buhari sọ pe ilu Kigaki, ni Rwanda lo yẹ ki ipade naa ti waye lasiko ipade ajọ Commonwealth to waye nibẹ ninu oṣu Keje ọdun yii, amọ wọn sun siwaju.












