Adé Olubadan nìkan ni mọ fẹ́ láti de láti bí ọdún 30 ṣẹ́yìn, mi ò fẹ́ dé adé míràn - Ladoja
Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Rashidi Ladoja ti ni lati ọgbọn ọdun ṣẹyin ti oun ti di ipo Otun Olubadan mu ni oun ti fẹ jẹ oye Olubadan ti ilu Ibadan.
Ladoja lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni lootọ ni oun gbọ awuyewuye nipa awọn oloye ti wọn fẹ maa de ade amọ oun ko ni nkan se nipa rẹ.
O ni ade ẹyọkan ṣoṣo to wu oun de lati igba pipẹ wa ni ade olubadan, ati pe oun ko nifẹ si ade miran.
Bakan naa lo fikun un pe ki ijọba gba awọn to nifẹ lati de ade gẹgẹ bi oloye ni aaye lati de ade wọn, kii ṣe ade ti ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo fun wọn.
Ladoja ni awọn to ba awọn oloye to ba oun sọrọ ni dide ade yoo bu iyi kun awọn ọloye naa.
Amọ o ni Ọba lo ma n de ade, awọn oloye agba kii de ade ni ilu Ibadan.
O wa gba awọn to fẹ de ade naa ni imọran lati ri pe wọn so ilu wọn mọ ilu Ibadan. Bii apẹrẹ Onido ti Ido Ibadan, onijaye ti Ijaiye-Ibadan ati bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, @Ladoja












