'Ẹ yé lo ikú ọmọọmọ mi láti fi da ìlú rú'

Àwọn tó ń ṣe ìfẹ̀hónóhàn lórí ikú Nahel

Oríṣun àwòrán, EPA

Nadal, ìyáìyá ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún Nahel, tí àwọn ọlọ́pàá ti rọ àwọn tó ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn ní orílẹ̀ èdè France láti dáwọ́ ìwọ́de tí wọ́n ń ṣe dúró.

Ìyá náà ní òun kò fẹ́ bí àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ṣe ń ba àwọn sọ́ọ̀bù, ilé ẹ̀kọ́ àti àwọn ọkọ̀ jẹ́ káàkiri gbogbo ìgboro nítorí ikú ọmọọmọ òun.

Ó ní gbogbo àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ kàn ń lo ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé sí ọmọọmọ òun láti fi máa hu ìwà tí kò tọ́ ni.

Nadal ní ó dá òun lójú pé ọlọ́pàá tó ṣekúpa ọmọọmọ òun máa fojú winá òfin àti pé kí gbogbo àwọn tó ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn dáwọ́ gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe dúró.

Ó fi kun pé gbogbo ìwọ́de tí wọ́n ń ṣe náà kò dá ẹ̀mí Nahel padà nítorí náà òun ń fẹ́ kí àláfíà jọba nínú ìlú.

Ní Nanterre ni Nadal ti bá àwọn akọ̀ròyìn ilé iṣẹ́ BFM TV sọ̀rọ̀ lórí rògbòdìyàn tó ti gba orílẹ̀ èdè France kan láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun tí ọlọ́pàá ti yìnbọn pa Nahel.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀ka ìdájọ́ wí pé wọ́n máa ṣe ìdájọ́ ọlọ́pàá náà bó ṣe tó àti bó ṣe yẹ.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun ilé Mayor Paris

Ilé Mayor tí wọ́n dáná sun

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àwọn tó ń ṣe ìwọ́de ní France ti ṣe ìkọlù sí ilé Mayor Paris bí wọ́n ṣe gbèrò láti dáná sun ilé rẹ̀, tí wọ́n sì tún yìbọn ba ìyàwó àti àtàwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń sálọ.

Ìwà yìí ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ń bu ẹnu àtẹ́ lù tí wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan àwọn tó ṣe iṣẹ́ náà.

Olóòtú ìjọba France, Elisabeth Borne júwe ìgbésẹ̀ náà bí èyí tìkò tọ̀nà àmọ́ wọn kò rí ẹnìkankan mú láti fẹ̀sùn pé ó ṣe iṣẹ́ láabi yìí.

Mayor Vincent Jeanburn kò sí nílé nígbà tí ìkọlù náà wáyé àmọ́ ìyàwò rẹ̀ tó wà nílé nígbà ìkọlù náà ṣèṣe lẹ́sẹ̀ tí ọmọ wọn kan náà sì farapa.

Àwọn tó lọ ṣe ìkọlù náà gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ wa ọkọ̀ kan wọ inú ọgbà Mayor ọ̀hún tí wọ́n sì sọ iná sí i pẹ̀lú èrò wí pé iná náà máa mú ilé rẹ̀.

Nígbà tí ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì ń gbìyànjú láti sá kúrò nílé ni wọ́n yin ìbọn bà á tí òun àti ọmọ kan sì farapa.

Ìwádìí lórí ìkọlù náà ti bẹ̀rẹ̀ báyìí fẹ́sùn ìpànìyàn.

Ìjọba France dá ọlọ́pàá 40,000 síta nítorí ìwọ́de lórí bí ọlọ́pàa se pa omọ ọdún 17

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ijọba orilẹ-ede France ti kede pe oun yoo da ẹgbẹrun lọna ogoji ọlọpaa si gbogbo orilẹ-ede naa ni alẹ Ọjọbọ.

Eyi ko sẹ yi ifẹhọnuhan to n waye nibẹ lẹyin ti ọlọpaa sekupa ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan.

Minisita fun ọrọ abẹnu lo sọ bẹẹ lẹyin ipade pẹlu Aarẹ Emmanuel Macron.

Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn ni wọn da awọn ọlọpaa ẹgbẹrun mẹsan an sita amọ ijọba ko tii kede ilu ko fararọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Kilo fa ifẹhọnuhan ni orilẹede Faranse?

Ifẹhọnuhan naa lo bẹrẹ kaakiri orilẹede France lẹyin ti ọlọpaa kan yinbọn pa awakọ to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogun.

Ọdọkunrin awakọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Nahel M, ni ọlọpaa yinbọn pa nitori o kọ lati duro nigba ti ọlọpaa da duro to si wa ọkọ lọ.

O kere tan ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu ẹniyan ọgọsan ni ọjọ keji ti wọn bẹrẹ ifẹhọnuhan naa.

Bakan naa ni ọlọpaa to le ni aadọsan ti farapa ninu iṣẹlẹ naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ni agbegbe Nanterre ti wọn ti yinbọn pa Nahel, awọn afẹhọnuhan da ina sun awọn ọkọ ti ọlọpaa si fin afẹfẹ tajutaju, ti awọn kan si yabo gbagede ilu naa ti wọn si n yinbọn ni agbegbe Lille.

Nibayii, wọn ti fi panpẹ mu ọlọpaa to yinbọn pa ọdọkunrin naa, ti iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ẹwẹ, Aarẹ Emmanuel Macron ti se ipade pajawiri pẹlu awọn minisita rẹ to si ni rogbodiyan to bẹ silẹ naa ko tọ, bẹẹ lo si kesi awọn eniyan ki wọn fi ọwọ wọnu.