Ṣé lóòtọ́ ní ìjínígbé, ìpàníyàn, ètò ààbò tó dẹnukọlẹ̀ tí rọlẹ̀ síi ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Twitter/D.Olusegun
Olubadamọran pataki si aarẹ orilẹede Naijiria lori eto aabo, Mallam Nuhu Ribadu ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe awọn ohun to fa a ti eto aabo fi dẹnukọlẹ ti n rọlẹ si ni Naijiria.
O ni adinku ba eto aabo lati bi ọṣẹ meji ti wọn ti yan awọn adari ileeṣẹ ikọ ọmọogun ati awọn eleto aabo tuntun.
Ribadu lo fi eyi lede lasiko ti awọn adari ẹka eto aabo ṣe abẹwo si aarẹ Tinubu ni ile aarẹ ni Abuja.
O ni awọn onimọ nipa eto aabo ni wọn fi idi ọrọ yii mulẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/D.Olusegun
Ribadu ni awọn ṣe abẹwo si aarẹ lati dupẹ lọwọ rẹ fun igbagbọ to ni ninu awọn, to si fun wọn ni aaye lati ṣiṣẹ ni ijọba rẹ.
O ni inu awọn dun lati sa ipa wọn fun itẹsiwaju orilẹede Naijiria, ti eto aabo yoo si gbọọrọ si.
Awọn ikọlu to waye laarin opin oṣu kẹfa si ibeere Osu Keje ni Naijiria...

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ikọlu, ijinigbe to ti waye laarin ọṣẹ kan fihan pe ijinigbe, ipaniyan ati ikọlu laarin awọn darandaran ati agbẹ ṣi n waye ni Naijiria.
Laipẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn ajinigbe yabo ile ijọsin kan ni ipinlẹ Ogun ti wọn si pa pasitọ ijọ Redeem kan lẹyin ti wọn ko ọgọọrọ awọn ọmọ ijọ lọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn figillante ti doola ẹmi awọn ọmọ ijọ kọọkan, amọ wọn ṣi n wa awọn miran ti wọn wa ni panpẹ awọn ajinigbe naa.
O kere tan eniyan ẹgbẹrun lọna mẹta ni ko ni ile lori nipinlẹ Taraba lẹyin ti ikọlu tun waye ni agbegbe naa ni Ọjọ Satide, ti o kere tan eniyan mẹta tun gbẹmi mi.
Saaju opin oṣẹ naa, ni awọn eniyan ti gbẹmi mi ni agbegbe naa lasiko ti eto aabo dẹnukọlẹ nibẹ.
Nibayii, ijọba ti kede ilu o fararọ ati ki onile-gbele fun wakati mẹrinlelogun ni agbegbe ilu Karim ati agbegbe rẹ lati Ọjọ Keji, Osu Keje, ọdun 2023.
Ikọ Boko Haram to n gbẹmi awọn eniyan naa ko dẹkun ipaniyan wọn ni ariwa orilẹede Naijiria.












