Imaamu agba ni Uso,ni ijọba ibilẹ Ọwọ,nipinlẹ Ondo sọ ohun ti oju rẹ ri lọwọ awọn ajinigbe

Àkọlé fídíò, Imaamu agba ni Uso,ni ijọba ibilẹ Ọwọ,nipinlẹ Ondo sọ ohun ti oju rẹ ri lọwọ awọn ajinigbe

Imaamu agba ni ilu Uso ni ijọba ibilẹ Ọwọ ni ipinlẹ Ondo, Alhaji Ali Ibrahim Bodunde ni oun wa ninu oko ni awọn ajinigbe naa mu oun.

Imaamu ọhun lo sọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ.

O ni awọn ajinigbe naa sọ wi pe ọwọ ni awọn n fẹ ni awọn ṣe se ikọlu si imaamu naa.

''Mo gbagbọ pe inu igbo to wa ni ibi oko wa ni agbegbe Uso ni wọn wa ti wọn si n gbe.''

''Wọn sọ fun mi iye ọmọ ti mo ni, iye iyawo ti mo ni to fi mọ iye ọkọ ti mo ni.''

''irin wakati mẹfa larin ninu igbo ki ilẹ to su ba wa ti wọn si fi okun de mi ni ọwọ ati ẹṣẹ mi mọlẹ.''

O ni fun wakati mejila ni oun fi wa ninu igbo naa ninu ilara lai si iranwọ kankan.

Amọ o ni awọn ajinigbe ti wọn fi lede pe owo ni wọn n wa naa jọ Fulani, ti wọn si gba miliọnu meji ni ọwọ wọn.

Imaamu agba naa wa rọ ijọba lati ba wọn dasi eto aabo to dẹnubolẹ ni agbegbe naa.

Ninu ọrọ ti wọn, ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe wọn ti fi panpẹ mu awọn ajinigbe naa, ti iwadii si tẹsiwaju.