'Ẹ yé lo àwọn ọlọ́pàá bí ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́'

Oríṣun àwòrán, POLICENG
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn pàtàkì ní àwùjọ tí wọ́n máa ń fi ọlọ́pàá tì láti yé lo àwọn ọlọ́pàá náà bí ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Osun, Yemisi Opalola Olawoyin nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹta oṣù Keje ní ó jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin kí ọlọ́pàá máa bá àwọn ènìyàn tí wọ́n fi wọ́n tì gbé báàgì, họ̀mbúrẹ́là tàbí ṣí géétì.
Opalola ní ó jẹ́ ohun àbùkù fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ń lo àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n kó tì wọ́n.
Ó ṣàlàyé pé iṣẹ́ tí àwọn ọlọ́pàá náà gbà tí wọ́n fi wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn yìí ni láti dá ààbò bò ẹ̀mí àti dúkìá wọ́n lọ́wọ́ ewu kìí ṣe láti ṣiṣẹ́ sìn wọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀.
Bákan náà ló ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn pàtàkì láwújọ yìí láti yé jẹ́ kí wọ́n lo àwọn nílò tí kò bá òfin mu.

Oríṣun àwòrán, TWITTER
“Gbígbé báàgì, ṣíṣí géètì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ fún àwọn ènìyàn pàtàkì tí àwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ lòdì sí òfin kò sì bá iṣẹ́ tí wọ́n gbé lé àwọn ọlọ́pàá yìí lọ́wọ́ mu.”
“Ọlọ́pàá tí a bá rí tó bá ń ṣe iṣẹ́ tó wà fún ọmọ ọ̀dọ̀ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tó wà máa fojú winá òfin.”
Opalola tún pàrọwà sáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn ọ̀tọ̀kùlú ìlú tí wọ́n máa ń gba ọlọ́pàá fún ààbò láti yé lo àwọn ọlọ́pàá náà bí ọmọ ọ̀dọ̀ àti pé tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n gba àwọn ènìyàn tó lè máa ràn wọ́n lọ́wọ́ dípò lílo àwọn ọlọ́pàá yìí.

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n máa ń kó sí ẹ̀yìn àwọn ènìyàn pàtàkì nínú ìlú ló máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ bíi ká gbé báàgì dání, ṣí ilẹ̀kùn ọkọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún àwọn tí wọ́n máa ń yàn wọ́n tì.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni fídíò àti àwòrán àwọn ènìyàn yìí máa ń jẹ jáde lórí ayélujára tí àwọn ọmọ Nàìjìríà sì máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu irú àwọn ìwà yìí.
Nínú oṣù Karùn-ún ọdún yìí ni àwòrán gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sypro gba orí ayélujára níbi tí ọlọ́pàá kan ti ń ṣi ilẹ̀kùn ọkọ̀ fun.

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Àwòrán yìí fa onírúurú awuyewuye lórí ayélujára pé iṣẹ́ tí àwọn ọlọ́pàá yìí ń ṣe lòdì sí ohun tí ìjọba torí rẹ̀ máa fi owó ìlú san owó oṣù fún-un.
Yàtọ̀ sí èyí àwòrán ibi tí àwọn ọlọ́pàá, pàápàá àwọn obìnrin ti ń gbé báàgì dání fún àwọn ènìyàn ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ fa awuyewuye lórí ayélujára.
Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà, Kayode Egbetokun nígbà tó gba ipò nínú oṣù Kẹfà ọdún 2023 kéde pé àwọn máa kó àwọn ọlọ́pàá kúrò lẹ́yìn àwọn ènìyàn pàtàkì yìí àmọ́ BBC kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá àṣẹ yìí ti wá sí ìmúṣẹ.












