Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ̀
Ilu lilu maa n mu inu mi dun ni- Promise Akinlade
Omọ ọdun mọkanla ni Promise Akinlade to n fi ilu da ara to wu u.
Ayantunde Aluyo Jesu ni ọga to tun kọ Promise ni iṣẹ ilu lilu sii to fi di aluluogo bayii.
O ni lati ọmọ ọdun mẹta ni oun ti maa n lu ike ati agolo kaakiri ni eyi ti awọn obi oun ro pe ariwo lasan ni oun fi n pa.
O gba awọn obi nimọran lati ṣe atilẹyin to yẹ fun awọn ọmọ wọn to ba ni talẹnti to dara.
Ayantunde naa rọ wọn pe ki ọmọde kankan ma ṣe ri talẹnti wọn mọlẹ nitori pe Oluwa lo mọ ọjọ ọla ẹda.



